Wo ajá ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́fà tó nílò N17m fún iṣẹ́ abẹ

Oríṣun àwòrán, GREENACRES RESCUE
Ai rin jina lai ri abuke ọkẹrẹ, ti a ba rin jina , a o ri ẹja to yọ ike lalẹ omi.
Bayii ni ọrọ ṣe ri pẹlu aja ti orukọ rẹ n jẹ Ariel to ni ẹsẹ mẹfa dipo mẹrin.
Aja naa nilo iṣẹ abẹ lati le sọ ẹsẹ rẹ di mẹrin, iṣẹ abẹ naa yoo nilo £15,000 eyi to jẹ N17,376,525.
Iroyin Ariel lu ori ayelujara pa lẹyin ti wọn gbe e ju si ibi ti wọn maa n paaki ọkọ si ni ẹka ile itaja B&M ni Pembrokeshire lorilẹede Wales.
Owo to le ni miliọnu mẹtadinlogun owo naira lawọn ẹlẹyinju aanu kaakiri agbaye dajọ fun iṣe abẹ eṣẹ aja naa.
Dokita akọṣẹmọṣẹ nipa iṣẹ abẹ, Aaron Lutchman gbiyanju lati daabo bo ẹsẹ mẹrin aja naa nigba ti o n ṣe iṣẹ abẹ ọhun.
‘’Aja naa n ṣe daadaa lẹyin iṣẹ abẹ to ṣe, inu aja naa to jẹ abo ti dun pada bayii.
A n wo wi pe yoo gbe igbe aye to dara,’’ Dokita Lutchman lo sọ bẹẹ.
Awọn to gbe aja Ariel lọ fun itọju
Mikey Lawlor ni oludasilẹ ati ọgagba ileeṣẹ Greenacres Rescue to wa lẹgbẹ Haverfordwest.
Awọn ni wọn ri Ariel nibi to ti wa ninu irora.
Dokita olutọju ẹranko to kọkọ ṣe ayẹwo Ariel ṣalaye pe yatọ fun ẹsẹ mẹfa ti aja naa ni, idi ré naa tun pe meji.
Ayẹwo mii to fihan pe kindinrin kan ni aja ọhun tun ni eyi to jẹ ki o nilo itọju to pọ gan an.
''Nitori pe oke itan meji ni Ariel ni, ko le jẹ ki idi rẹ ri bi o ti yẹ ki o ri.
Idi niyi ti ẹsẹ ẹsẹ ẹyin rẹ ko ṣe ni iṣan to yẹ ko wa nibẹ.
Amọ, aja yii ti n ta kebe kebe lẹyin oṣu mẹta ti o ṣe iṣẹ abẹ tan.
Ni ile iwosan Langford Vets ni Somerset ni wọn ti ṣe iṣẹ abẹ fun Ariel.
Oriṣi meji iṣẹ abẹ ni wọn ṣe fun Ariel, mejeeji lo si yọri si rere.
Koda, lati ọjọ keji naa ni Ariel ti bẹrẹ si ni fi ẹsẹ rin kaakiri to si n jẹun, o tun n mu omi bakan naa.
Amọ, Ariel ṣi nilo amojuto ki kokoro maa wọ oju iṣẹ abẹ rẹ.
Ṣugbọn ko le ni iyọnu kankan tori awọn akọsẹmọṣẹ lo n ṣe itọju rẹ,'' dokita to ṣiṣẹ abẹ fun Ariel lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, GREENACRES RESCUE
Ọgbẹni Lawlor sọ pe oun lero pe o yẹ ki Ariel le jade nile iwosan titi opin ọsẹ yii.
Lawlor ni ''o ti sinmi daadaa nile iwosan lati igba ti wọn ti ṣe iṣẹ abẹ fun un tan.
A maa rii wi pe a wa ile ti yoo maa gbe fun un.
Iwuri nla lo jẹ fun wa bi ọgọọrọ eeyan ti n pe tawọn mii ṣi n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ lori ọrọ ilera Ariel.
Awọn eeyan kan si wa lori ọrọ Ariel lati ilu New York l'Amerika ati lati orilẹede Australia.
Mi o le ki gbogbo eeyan tan fun ifẹ ti wọn ti han si aja yii.''
Vicki Black to jẹ ọgagba ile iwosan Langford Vets naa sọ pe ''ohun to ṣe aja Ariel lagbara debi pe oniruuru awọn dokita akọsẹmọṣẹ ni wọn jọ ṣiṣẹ pọ lori rẹ.
Inu wa dun wi pe a fun Ariel ninitọju to peye, ara rẹ si ti ya lẹyin to ṣe iṣẹ abẹ tan.















