Èèyàn mẹ́fà dèrò ọ̀run níbi tí wọ́n ti ń ṣe àjọyọ̀ bọ́ọ̀lù ní Guinea

Ayo aseyori

Oríṣun àwòrán, getty

Ko din ni eeyan mẹfa to padanu ẹmi wọn lorilẹ-ede Guinea, lẹyin ti orilẹ-ede naa fẹyin Gambia gbolẹ pẹlu ami ayo kan si odo ninu idije AFCON 2023 to n lọ lọwọ.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye lọjọ Ẹti to kọja yii ni Guinea ti na Gambia pẹlu ami ayo kan si odo, eyi to mu kawọn ọmọ Guinea kan gun ori mọto, ti awọn mi-in si n gun alupupu lọna to l'ewu, ni olu orileede naa, Conakry.

Ajọyọ to lewu naa lo fa a ti ijamba fi ṣẹlẹ, ti eeyan mẹfa si di oku gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

‘’Eeyan mẹta lo kọkọ ku nigba ti ọkọ meji fori sọra wọn nibi ajọyọ ọhun, ọpọlọpọ lo si fara pa yannanyanna, gẹgẹ bi ọlọpaa kan ṣe fdi eyi mulẹ fun ẹka iroyin Agence France Presse.

Orilẹ-ede to nifẹẹ nla si ere bọọlu alafẹsẹgba ni Guinea gẹgẹ bi akọsilẹ nipa rẹ se sọ. Wọn fẹran ere bọọlu to bẹẹ ti pupọ wọn rin irinajo ti ko din ni ẹgbẹrun kan maili lati ti lọọ wo ere bọọlu AFCON 2023 yii ni Ivory Coast to ti n waye.

Bi wọn ṣe bori ifẹsẹwọnsẹ naa ni wọn fọn sigboro ti wọn n fo f’ayọ.

Ifẹsẹwọnsẹ Guinea pẹlu Cameroon lọjọ Aje ko mu iduunu bẹẹ wa, ọmi ni wọn jọ ta.

‘A o ni kawọn eeyan wa ma yọ, ki wọn ṣọra la n sọ’

Ajọ to n ri si ere bọolu alafẹsẹgba ni Guinea (Feguifoot) pẹlu agbabọọlu tẹlẹ, Pascal Feindouno, ti rọ awọn eeyan lati ma fi idunnu han lọna to mu ewy dani.

Pascal Feindouno, ọkan ninu awọn olokiki agbabọọlu ni Guinea, sọ pe 'mo ni iṣẹ kan ti mo fẹẹ ran sawọn ọmọ Guinea lọkunrin ati lobinrin, a gbọ pe awọn eeyan ku lẹyin ta a bori Gambia. A fẹ kiru nnkan bayii dopin.

" Gbogbo nnkan n lọ deede fun wa lasiko yii lorilẹ-ede wa, a si nireti ninu idije yii, ṣugbọn ẹ ma ṣe ohun ti yoo pa yin. Ẹ ṣe jẹjẹ, ẹ jọọ.’’

Idije bọọlu awọn orilẹ-ede Afrika to n waye naa lo bẹrẹ lọjọ kẹtala, oṣu kinni, ọdun 2024, yoo si pari lọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun 2024.