Èèyàn tó lé ní 90 ni ìjì líle inú yìnyín ti ṣekúpa ní America

Aworan yinyin l'Amẹrika

Oríṣun àwòrán, EPA

O le ni aadọrun eeyan ti iji lile inu yinyin ti ṣekupa bayii laarin ọsẹ kaakiri orilẹede America.

Mẹẹdọgbọn ninu awọn eeyan naa ni wọn ku ni Tennessee nigba ti mẹrindinlogun jẹ Ọlọrun ni pe ni Oregon nibi ti ofin konle o gbele si wa nita latari iji lile inu yinyin to n fẹ nibé.

Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan ni wọn ti wa ninu okunkun birimu bayii kaakiri orilẹede America latari oju ọjọ ti ko dara.

Bo tilẹ jẹ pe ni Tennessee ati Oregon lawọn eeyan ti ku ju, iji lile naa tun ṣọṣẹ ni Mississippi, Illinois, Pennsylvania, Washington, Kentucky, Wisconsin, New York, New Jersey atawọn ilu mii naa.

Niluu Portland ni Oregon l'Ọjọbọ to kọja, eeyan mẹta ni ina gbe ti wọn si ti ibẹ ku lẹyin ti iji lile wo opo ina le ọkọ ti wọn wa ninu rẹ lori.

Amọ, ọmọ ikoko kan to wa ninu ọkọ naa moribọ ni tiẹ.

Eeyan marun un mii ku laarin ọjọ mẹrin niluu Seattle gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Associated Press ṣe sọ.

Ni Mississippi, wọn ti rọ awọn awakọ lati dẹkun ọkọ wiwa ayafi to ba nilo.

Bakan naa ni wọn kilọ fun wọn pe ki wọn maa ṣe akiyesi yinyin dudu loju titi.

Koda, awọn ile ẹkọ giga fasiti ti sun iwọle awọn akẹkọọ siwaju nitori oju ọjọ ti ko dara.

Aworan ile ti yinyin bo mọlẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot?BBC

Awọn to ti ku ni ipinlẹ naa ti di mọkanla bayii lẹyin tawọn mẹta mii tun jẹ Ọlọrun nipe lọjọ Aiku to kọja.

Iṣoro omi ṣi n koju awọn eeyan Tennessee nibi ti ẹgbẹrun lọna irinwo eeyan ko ti ri omi lo latari egboro omi to bẹ ni Memphis.

Omi inu igo lawọn eeyan n mu, oun naa ni wọn n fi fọ eyin ti wọn si tun n fi fọ abọ pẹlu.

Koda, omi inu igo yii naa ni wọn fi n dana ounjẹ.

Omi yii naa ni ọpọ ile ounjẹ n fun awọn onibara wọn lọjọ Aiku to kọja.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ agbegbe ti iji lile inu yinyin sọ si okunkun lo ti pada ni ina bayii, awọn agbegbe kan si wa ti wọn ko tii ni ina di akoko yii.