Ta ni Olayide Adelami igbákejì gómìnà tuntun ní ìpínlẹ̀ Ondo?

Oríṣun àwòrán, Olayide Adelami/Facebook
Oloye Olayide Adelami jẹ ọmọbibi ilu Owo ni ipinlẹ Ondo.
A bi Oloye Adelami si idile Pa ati Iyaafin Amos AdelamI ni ọjọ kẹta oṣu Kẹrin ọdun 1958, eyi to tumọ si pe ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin ni i ṣe.
Adelami lọ si gbajugbaja ile ẹkọ Imade College niluu Owo.
Lẹyin naa ni o ṣe idanwo girama GCE nile ẹkọ gbogbonṣe ti ilu Ibadan ki o to kẹkọọ gboye ni fasiti UNILAG nibi ti o ti kẹkọọ nipa owo ṣiṣe.
Adelami tun tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ nigba to gba oye fasiti keji MBA ni ile ẹkọ fasiti ipinlẹ Ogun.
Lẹyin ti o kopa tan ninu eto agunbanirọ ọlọdun kan loṣu kẹfa ọdun 1983, Adelami bẹrẹ iṣẹ ijọba gẹgẹ bi oluṣiro owo ni ọgagba oluṣiro owo lorilẹede Naijiria.
Ni ọdun 1988 ni wọn gbe lọ si ọfiisi ile igbimọ aṣofin agba nilu Abuja.
O si wa lara awọn to kọkọ ṣiṣẹ ni ọfiisi ile igbimọ aṣofin l'Abuja ti o di eyi tawọn sẹnẹtọ ati aṣoju-ṣofin n lo lonii.
Adelami lo ṣe idasilẹ ẹka eto inawo ati apo ikowosi nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja.
Bayii ni wọn ranṣẹ pe Adelami pe ki o wa ṣe idasilẹ ẹka eto inawo ati apo ikowosi fun ajọ to n ri si ere ori owo epo.
Lẹyin ti o ṣe iyẹn tan ni o tun lọ ṣe idasilẹ ẹka eto inawo fun ajọ to n ri si iranwọ fun idile.
Adelami ṣe olori oniruuru ẹka laarin ọdun 1996 si 2000.
Lasiko ti o n ṣiṣẹ yii gan an ni ijọba da ile iwosan ijọba apapọ ilu Abuja silẹ.

Oríṣun àwòrán, others
Adelami pada sile igbimọ aṣofin agba l'Abuja
Ifakọyọ Adelami nigba ti o fi ṣiṣẹ nile aṣofin agba niluu Abuja lo jẹ ki wọn pe e pada lọdun 2000 lati ṣe iranwọ fun ẹka eto inawo ati apo ikowosi.
Adelami di adari ẹka eto inawo lẹyin ọdun mẹta to pada si ile igbimọ aṣofin l'Abuja.
O wa ni ipo yii titi di ọdun 2007 nigba ti ni igbega si ipo ọgagba .
Ọdun to tẹ le ni wọn fi orukọ ranṣẹ lati lọ kẹkọọ ni gbajugbaja ile ẹkọ giga ti wọn ti n kọ ipa iṣeto ilu ati ọgbọn inu, NIPSS ni Kuru, mipinlẹ Plateau.
Lẹyin to pari ẹkọ rẹ nibẹ ni ijọba tun gbe iṣẹ nla mii le e lọwọ ni ileeṣẹ ti ijọba ṣẹṣẹ da silẹ to n ri si rira ati pinpin nkan.
Adelami ṣe akitiyan lati ṣe idanilẹkọọ fawọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ to n ṣiṣẹ labẹ rẹ ni ẹka ijọba ọhun.
Adelami gba igbega si ipo akọwe agba ni ẹka ijọba to n ri si rira ati pinpin, ileegbe ati akanṣe iṣẹ.
Ipo yii lo wa titi ti wọn fi yan sipo igbakeji akọwe ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja.
Adelami di ipo yii mu titi ti o fi fẹyinti lẹnu iṣẹ ọba lọdun 2018.
Adelami wọ agbo oṣelu lẹyin to fẹyinti lẹni iṣẹ ọba
Kete ti o fẹyinti lẹnu iṣẹ ọba ni Adelami kanlu agbami oṣelu.
Ileeṣẹ yan an gẹgẹ bi oludari igbimọ to n ṣatilẹyin fun aarẹ nipinlẹ Ondo.
Iṣẹ ti wọn gbe le e lọwọ ni lati pẹtu si aawọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn n ba ara wọn ja.
Lara iṣẹ ti wọn tun gbe fun un ni pe ki sẹ agbatẹru bi oniruuru ajọ yoo ṣe ṣatilẹyin fun aarẹ Muhammadu Buhari ki o le wọle ibo fun saa keji.
Adelami 'siṣẹ takuntakun fun ẹgbẹ oṣelu APC, o ṣi rii pe sẹnẹtọ kan ṣoṣo ti APC ni nipinlẹ to wa lati ẹkun oṣelu rẹ.
Adelami jẹ ọjulowo ọmọ ẹgbẹ oriṣiiriṣii ẹgbẹ akọmọṣẹmọṣẹ bii FCNA, FNIM, FCTI ati FCMA
Gómìnà Aiyedatiwa kéde igbákejì rẹ̀ lẹ́yìn tó tú ìgbìmọ̀ ìṣèjọba ìpínlẹ̀ Ondo ká
Gomina ipinlẹ Ondo, ti kede orukọ Ọlayide Owolabi Adelami gẹgẹ bi igbakeji rẹ.
Ikede yii n waye ni ọjọru lẹyin wakati diẹ to tu igbimọ iṣejọba ipinlẹ naa ka.
Adelami, jẹ ọmọ ilu Ọwọ, iyẹn ilu gomina ana ni ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu.
Bakan naa, igbakeji akọwe agba ile igbimọ aṣofin apapọ Naijiria ni Adelami tẹlẹ ki o to fipo silẹ.
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa fi idi rẹ mulẹ pe awọn ti ri iwe orukọ Ọlayide Owolabi Adelaide ti Gomina Lucky Ayedatiwa fi ranṣẹ gẹgẹbi ẹni to yan ni igbakeji rẹ.
Lọla ni ireti wa pe yoo fi ara han niwaju ile aṣofin naa fun ayẹwo ni ibamu pẹlu ilakalẹ iwe ofin Naijiria.
Gómìnà Aiyedatiwa tú ìgbìmọ̀ ìṣèjọba ìpínlẹ̀ Ondo ká

Oríṣun àwòrán, luckyaiyedatiwa/x
Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa ti tu igbimọ iṣejba ipinlẹ naa ka.
Ni Ọjọru ni igbesẹ naa waye ninu atẹjade kan eyi ti amugbalẹgbẹ fun gomina Aiyedatiwa lori ọrọ iroyin, Ebenezer Adeniyan fi sita.
Gbogbo awọn kọmiṣọna ati amugbalẹgbẹ ti gomina ipinlẹ naa to di oloogbe, Rotimi Akeredolu yan sipo lo ṣi wa ninu igbimọ iṣakoso ijọba ipinlẹ naa, yatọ si awọn marun un kan to kọwe fi ipo silẹ ni kete ti iṣẹlẹ iku Akeredolu waye ni ooṣu kejila ọdun 2023.
Atẹjade naa ṣalaye pe gbogbo awọn ọmọ igbimọ iṣejọba ipinlẹ naa ni ki wọn wa iṣakoso iṣẹ ajọ ati ileeṣẹ ijọba ti wọn n mojuto le awọn akọwe agba gbogbo nibẹ lọwọ
“Gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba ti ọrọ yii kan gbọdọ jọwọ gbogbo awọn dukia ijọba to wa ni ikawọ wọn.
Ni ọjọ kẹtadinlogun ni wọn bura fun Lucky Aiyedatiwa gẹgẹ bi i gomina tuntun ni ipinlẹ Ondo lẹyin iku ọga rẹ, Gomina Rotimi Akeredolu ni ọjọ yii kan naa.
Ọpọ lo ti n reti igbesẹ yii lati waye ṣaaju asiko yii paapaajulọ pẹlu dukuu to wa laarin awọn to gbe sẹyin gomina Akeredolu atawọn to gbe si ẹyin Aiyedatiwa nigba to wa nipo gẹgẹ bii igbakeji gomina Akeredolu.

Oríṣun àwòrán, Olabode Richard Olatunde
Ẹbi gomina ipinlẹ Ondo nigba kan to di oloogbe, Rotimi Akeredolu, ti kede bi eto isinku ati idagbere ikẹyin yoo ṣe ṣe lọ.
Ninu ikede kan ti akọwe fun Gomina Akeredolu nigba to fi wa nipo, Olabode Richard fi sita, ni ẹbi Akeredolu ti dupẹ lọwọ gbogbo eeyan to duro ti wọn, ati awọn to ba wọn kẹdun lasiko ti ajalu iku Aketi ja lu wọn.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni Rotimi Akeredolu jade laye lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.
Iku rẹw aye lẹyin ti aisan jẹjẹrẹ ba a finra ninu nnkan ọmọkunrin rẹ.
Orilẹ-ede Germany lo ku si nileewosan to ti n gba itọju.
Ọgbẹni Olabode sọ pe awọn pe gbogbo ọrẹ, alajọṣe, ati awọn afẹnifẹre, lati larapọ mọ wọn lati fun akọni wọn ni idagbere to yẹ ẹ.
Bi eto isinku ati idagbere naa yoo ṣe waye:
Ọjọbọ, February 15, 2024:
Isọji ijere ọkan ni gbagede MKO Abiola Democracy Park, Akure
Ọjọ Ẹti, February 16, 2024:
Irun Jimọ yoo waye ni Akure Central Mosque
Ọjọ Abamẹta, February 17, 2024:
Isin idagbere ti ile ẹkọ girama Layola, ti yoo waye ni gbọngan Loyola College Old Ife Rd, Agodi, niluu Ibadan
Ọjọ Aiku, February 18, 2024:
Isin alẹ idagbere ni Fasiti Obafemi Awolowo. Eyi yoo waye ni ile ẹgbẹ OAU, Old Ife Road, Agodi, Ibadan.
Ọjọ Ẹti, February 19, 2024:
Ijoko ile ẹjọ pataki yoo waye ni ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Oyo to wa ni ile ẹjọ giga, Ring Road, Ibadan, nipinlẹ Oyo.
Lẹyin ti ijoko naa ba waye ni ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria yoo ṣe isin idagbere fun Akereolu, ni ile ẹgbẹ wọn, Aare Afe Babalola Bar Centre, Iyagakun, Ibadan.
Isin orin onigbagbọ ati idagbere yoo waye ni gbọngan Jorgor Centre, Liberty Road, niluu Ibadan.
Ọjọ Iṣẹgun, February 20, 2024:
Isin ikẹyin yoo waye ni owurọ ni ile ijọsin All Saints Church, Jericho, Ibadan. Lẹyin eyi ni wọn o tẹ oloogbe si ile rẹ, nibi ti awọn eeyan ti wọn ba fi iwe pe, yoo ti ni anfaani lati wo oku rẹ.
Ọjọru, February 21, 2024:
Ajabue (Oro ile) yoo waye fun oloogbe niluu Owo, nipinlẹ Ondo.
Lọjọ yii kan naa ni ijoko pataki yoo waye fun un ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo, to wa ni ilu Akure.
Bakan naa ni wọn o tẹ oku rẹ ni itẹ ẹyẹ, ni papa iṣere ilu Akure fun gbogbo araalu lati wo.
Aṣalẹ idaro ati idagbere ni yoo kẹyin rẹ ni irọlẹ ọjọ naa, niluu Owo.

Oríṣun àwòrán, Olabode Richard Olatunde
Ọjọbọ, February 22, 2024:
Eto isin orin onigbagbọ yoo waye nile ijọsin St Andrews Cathedral, Imola, niluu Owo, ipinlẹ Ondo.
Alẹ aisun onigbagbọ yoo waye ni irọlẹ ọjọ naa bakan naa ni ile rẹ, Maranatha Villa, Owo.
Iwọde pẹlu ti tan abẹla ati ikorajọpọ awọn ẹgbẹ ẹlẹmu, Kegites Club, yoo waye ni alẹ ọjọ naa mọju ọjọ keji.
Ọjọ ẹti, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, ọdun 2024, ni wọn o sin oku Gomina Rotimi Akeredolu, ni ilẹ isinku kan to wa niluu Owo. Amọ, ẹbi nikan ni yoo kopa nibi eto naa.
Ọjọ Abamẹta ni wọn o fi idije bọọlu kan sọri rẹ ni papa iṣere Akure, niluu Akure.
Isin idupẹ ni yoo kadii gbogbo ayẹyẹ naa ni ile ijọsin St. Andrews Church, Imola, Owo.












