Ọkùnrin kan di èrò ọ̀run lẹ́yìn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin ní ilé ìtura l'Ondo

Aworan

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti kede pe ọwọ ti tẹ eeyan meji kan lori iku ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Abiodun Akintomowo niluu Ondo.

Akintomowo padanu ẹmi rẹ lẹyin to ni ibalopọ pẹlu obinrin kan to jẹ ọrẹbinrin rẹ ti wọn n jọ wọlewọde, ni ile itura kan to wa ni agbegbe Akinjagunla lọjọ Aiku ọsẹ yii.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami, ẹni to kọ lati darukọ awọn afurasi naa salaye pe ọkan lara wọn jẹ ọrẹbinrin oloogbe ti ikeji si jẹ alakoso ile itura nibi ti isẹlẹ naa ti waye.

“Ara oloogbe o ya lẹyin ibalopọ pẹlu arabinrin yii ni ile itura, ti wọn si gbe lọ si ile iwosan, to si jẹ pe ibẹ lo gba jade laye.

“Awọn afurasi mejeeji si ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii.”

Odunlami ni iwadii lori isẹlẹ naa si n tẹsiwaju lọwọ, ti wọn si ti gbe oku oloogbe lọ si mọṣuari ni ile iwosan kan niluu Ondo.

Oṣojumikoro to ba awọn akọroyin The Punch sọrọ ni ọrẹbinrin oloogbe pariwo sita lẹyin ti oloogbe na daku ninu yara ile itura ilẹ ibalopọ.

“Obinrin naa pariwo sita lẹyin to ri pe ọkunrin naa ti daku. Alakoso ile itura ati awọn eeyan agbegbe sure lọ si ibẹ lati doola ẹmi oloogbe naa sugbọn ẹmi pada bọ.