Akọ̀wé ìjọba Amẹ́ríkà, Anthony Blinken ṣàbẹ̀wò sí Tinubu

Oríṣun àwòrán, STATE HOUSE
Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Bola Tinubu lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun gbàlejò Akọ̀wé ìjọba Amẹ́ríkà, Anthony Blinken ní ilé ìjọba Aso Rock, Abuja.
Blinken balẹ̀ sí Nàìjíríà fún ìpàdé láti mú kí ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà tún lè gbòòrò si.
Nàìjíríà wà lára àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ mẹ́rin tí Blinken ṣe àbẹ̀wò sí.
Yàtọ̀ sí Nàìjíríà, Blinken tún ṣàbẹ̀wò sí Ivory Coast, tí yóò sì tún lọ sí Cape Verde àti Angola.
Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú Tinubu, Blinken ní Amẹ́ríkà ní ìfarajìn láti túnbọ̀ tẹ̀síwájú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ láti rí dájú pé ètò ààbò fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ní Nàìjíríà.

Oríṣun àwòrán, STATE HOUSE

Oríṣun àwòrán, STATE HOUSE
Ó ní àwọn yóò tún tẹ̀síwájú láti máa ṣe àtìlẹyìn fún Nàìjíríà lórí gbígbógun ti àwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí.
Ó ṣàlàyé pé ó pọn dandan fún ìjọba láti mú ààbò ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn ní òkúnkúndùn.
Bákan náà ló ní àwọn iléeṣẹ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan àtàwọn aládàni ti ṣetán láti wá dókoòwò ní Nàìjíríà.
Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn iléeṣẹ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ló ti ṣetán láti kún Ààrẹ Tinubu lọ́wọ́ nípa pípèsè iṣẹ́ tó lé ní mílíọ̀nù kan nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé èyí tí Tinubu ń gbèrò láti pèsè.
Ó wòye pé fífòpin sí ìwà àjẹbánu yóò ṣe ìwúrí fún àwọn tó bá fẹ́ dókoòwò ní Nàìjíríà láti gbé okoòwò wọn wá.
Bẹ́ẹ̀ náà ló tún tẹmpẹlẹmọ pé lóòótọ́ ni àwọn ìgbésẹ̀ Ààrẹ Tinubu ń fa ìnira fún àwọn ará ìlú lọ́wọ́ lọ́wọ́, ó ní àwọn máa kún ìjọba lọ́wọ́ láti pèsè àwọn nǹkan tí yóò mú ìnira náà dínkù fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Blinken yóò tún ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn olùdókoòwò ní ìpínlẹ̀ Eko lọ́jọ́rú kó tó kúrò ní Nàìjíríà.















