Oníṣẹ̀ṣe pọ́ńbélé ni mí, ọjọ́ tí mo bá ti ní n ò ṣe ẹbọ mọ́ ni kí ẹ̀mí mi bọ́ – Gbajúmọ̀ oníṣẹ̀ṣe, Tani Olohun fọnmú

Oríṣun àwòrán, others
Gbajumọ olufọnrere ẹsin iṣẹṣe, Ọgbẹni Adegbọla Ifatimilẹyin ti ọpọ mọ si Tani Ọlọhun ti ṣalaye pe ko si nnkan to le ya oun ya ẹsin iṣẹṣe laye oun mọ ati pe ọjọ ti oun ba gbimọran nnkan bẹẹ ni ki Eduwa o gbẹmi oun.
Tani Ọlọhun to ṣẹṣẹ n bọ ninu wahala ọrọ ẹjọ pẹlu awọn aṣiwaju ẹsin Islam kan ni ilu Ilọrin ni kopẹkopẹ yii ṣalaye pe ko si ipenija ti o wu ti oun le la kọja ti yoo mu ki oun pa ẹsin da kuro ni ẹsin iṣẹṣe bọ si ẹsin miran.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC News Yoruba lọwọlọwọ yii, Tani Ọlọhun ni ko si ohunkohun to tun le mu ki oun pada si idi ẹsin Islam nitori pe ẹsin ti oun ti yan bayii naa ni ẹsin Iṣẹṣe.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, laipẹ yii ni okiki gba igboro kan nipa iakangbọn to waye laarin Ọgbẹni Adegbọla Ifatimilẹyin atawọn aṣiwaju ati ẹgbẹ ẹsin Islam kan eleyi to mu di ero ilẹ ẹjọ ti o si gba ibẹ de ẹwọ fun oṣu diẹ.
Laipẹ yii ni ọrọ naa ni iyanju lẹyin asọye laarin oun atawọn Alfa ati ẹgbẹ ẹlẹsin Islam ti wọn gbe e lọ si ile ẹjọ.
Lara ẹsun ti wọn fi kan an nile ẹjọ ni ibanilorukọjẹ ati sisọrọ alufansa si ẹsin kan eyi ti wọn ni o ṣeeṣe ko da omi alaafia ilu ru, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Idi ti Tani Ọlọhun fi dara pọ mọ iṣẹṣe

Tani Ọlọhun to ni lootọ idile Musulumi ni oun ti jade wa ṣalaye pe Alhaji ati Alhaja to de Mecca bọ ni baba ati iya oun.
O ni oun ṣe awari ara oun loun fi kuro lẹsin Islam bọ si oniṣẹṣe.
Mo ṣe awari ara mi ni mo fi rii pe ko si ohun to n jẹ ẹsin Musulumi, ko si si ohun to n jẹ Kristẹni. Oniṣẹṣe lo bi gbogbo wa.”
O ni Oniṣẹṣe ni gbogbo ẹni to ba ti jẹ ọmọ ilẹ Yoruba pata nitoripe, gẹgẹbi o ṣe sọ, iṣẹṣe ni iṣẹdalẹ Yoruba.
Ki lo fa ifanfa laarin Tani Ọlọhun atawọn aṣiwaju ẹsin Islam ni Ilọrin?

Ọgbẹni Adegbọla Ifatimilẹyin ti ọpọ mọ siTani Ọlọhun naa tun ṣalaye bi ọrọ ṣe pa oun atawọn aṣiwaju ẹsin naa pọ.
O ni eto kan ti oun n ṣe loju opo ayelujara ‘Facebook’, ati ‘Youtube’ oun ni oriṣun gbogbo rẹ pẹlu bi awọn kan ṣee n sọọ pe ‘nitori ki o le maa ba awọn kan lorukọ jẹtabi gba ẹsin kan jẹ lo ṣe gbe eto yii kalẹ.’
O ni amọṣa, gbogbo oun to ṣẹlẹ yii tubọ kọ oun lọgbọn sii ni.
Ṣe lootọ ni adehun ati pada si ẹsin musulumi wa lara afẹnuko ti wọn tori fi i silẹ?

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ọpọ lo ti n sọ ọ kiri pe adehun wa laarin Tani Ọlọhun atawọn aṣiwaju ẹsin atawọn ẹgbẹ to pe e lẹjọ lati fi ẹsin iṣẹṣe silẹ pada si ẹsin Musulumi ni wọn tori fi i silẹ ninu ahamọ ti wọn si gbọn ẹjọ naa danu.
Amọṣa Tani Ọlọhun ni ọrọ to jina si otitọ ni eleyi jẹ.
“Wọn yi ẹjọ danu latari asọti ọrọ ti emi atawọn agbẹjọro mi wa ba mi sọ nigba ti mo wa nibẹ.”
O ni asọti ọrọ ọhun si ni pe ki oun bẹ awọn ti wọn fi ẹsun kan oun pe oun ba lorukọ jẹ.
O ṣalaye siwaju sii pe oun gba lati bẹ wọn nitori pe oun naa ko ni ọna mii lasiko ti oun fi wa ninu ahamọ ijọba.















