Wo ìdí tí wọ́n fi yọ olórí Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun, Oluomo, nípò

Aworan Ọlakunle Oluọmọ ati Aworan ile aṣofin ipinlẹ Ogun lasiko ayipada adari ile naa

Oríṣun àwòrán, Imran Muhammad/X/screenshot

Lẹsẹkẹsẹ ti wọn yọ olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọlakunle Oluọmọ n'ipo, ni wọn rọpo rẹ pẹlu Họnarebu Daisi Olumide Ẹlẹmide.

Awọn aṣofin mejidinlogun ninu awọn aṣofin mẹrindinlọgbọn ti wọn di ile igbimọ naa mu ni wọn buwọlu iwe lati yọ Oluọmọ n'ipo.

Ẹkun Ifo kinni ni Oluọmọ n ṣoju nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, o si ti wa gẹgẹ bi olori ile igbimọ ọhun lati ọdun 2015, lati asiko iṣejọba saa keji Sẹnetọ Ibikunle Amosun.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Họnarebu Adegoke Adeyanju toun n ṣoju ẹkun ariwa Yewa kinni lo daba pe ki wọn yọ Oluọmọ gẹgẹ bi olori wọn lọjọ Iṣẹgun nigba ti Họnarebu Ademọla Adeniran toun n ṣoju ẹkun Ṣagamu keji, keji aba ọhun.

A tun gbọ pe ninu oṣu kẹsan, ọdun to kọja, iyẹn 2023 ni awọn aṣofin naa ti kọkọ fẹẹ yọ Oluọmọ nipo, nitori awọn ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan an.

Ṣugbọn wọn sọ pe Gomina Dapọ Abiọdun ati gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọṣọba ba a bẹbẹ.

Lati igba naa la gbọ pe awọn aṣofin yii ti bẹrẹ si ni wa ọna miran ti wọn yoo gba lati yọ Oluọmọ nipo, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe iṣakoso rẹ gẹgẹ bii olori ile ko tẹ wọn lọrun.

Aworan ile aṣofin ipinlẹ Ogun lasiko ayipada adari ile naa

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ni nnkan bi ọjọ mẹwaa sẹyin ni wọn lawọn aṣofin tun gbero lati yọ Oluọmọ, ṣugbọn ti wọn pinnu lati sun erongba wọn siwaju digba ti idajọ ile ẹjọ agba yoo waye lori idibo gomina ipinlẹ Ogun.

Wọn ni bi wọn ba yọ Oluọmọ ṣaaju ọjọ idajọ ile-ẹjọ giga to gbe gomina Abiọdun wọle fun igba keji, o ṣee ṣe ko dabaru eto wọn, ati pe o ṣee ṣe ki awọn araalu ro pe gomina lo n ṣagbatẹru wọn.

Koda, wọn sọ pe wọn ko fẹ ohun ti yoo ṣakoba fun agbekalẹ eto iṣuna ọdun 2024 ti gomina fẹẹ gbe wa siwaju ile igbimọ aṣofin lati buwọ lu.

A tun gbọ pe lẹyin ti idajọ ti pari lori eto idibo gomina, ti awọn aṣofin si ti buwọ lu eto iṣuna ọdun 2024, awọn aṣofin ọhun ri asiko to dara lati mu erongba wọn ṣẹ nipa yiyọ Oluọmọ.

Awọn ẹsun ti wọn fi kan Oluomo

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Oluọmọ ni dida ọwọ wu, aini afojusun, igberaga, adari ti ko dara, aini otitọ, ṣiṣe owo kumọkumọ, ati kikọju awọn aṣofin sira wọn.

Igbakeji olori ile igbimọ naa, Họnarebu Bọlanle Ajayi to n ṣoju ẹkun Guusu Yewa lo ṣakoso ile igbimọ lakoko ti wọn yọ Oluọmọ.

A gbọ pe niṣe ni Oluọmọ paṣẹ fun awakọ rẹ lati gbe awọn ọkọ ẹṣọ aabo rẹ dina lati ma le jẹ ki ẹnikẹni jade kuro ninu ọgba ile igbimọ aṣofin fun bii wakati meloo kan, iyẹn lẹyin ti wọn pari gbogbo eto lati yọ ọ nipo.

Eyi ni wọn tun lo fẹẹ da wahala silẹ, ko to di pe wọn ranṣẹ pe kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Abiọdun Alamutu lati wa da si ọrọ naa.

Nigba to n sọrọ lẹyin ijokoo ati gbogbo eto ile igbimọ aṣofin, Họnarebu Oludaisi Olumide Ẹlẹmide sọ pe ki awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun maa reti ayipada rere ninu iṣakoso oun.

Aworan ile aṣofin ipinlẹ Ogun lasiko ayipada adari ile naa

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “awa aṣofin maa n tẹle ofin ati ilana.

A fẹ ki gbogbo agbaye mọ pe a ti ni ayipada ninu iṣakoso.

Awọn aṣofin mejidinlogun ni wọn buwọ lu iwe lati sọ mi di olori ile.

A ti gba iṣakoso ile bayii, a si wa n ṣeleri wi pe iṣakoso tuntun yoo gbaruku ti gomina.

Gomina ko mọ ohunkohun nipa iyọnipo to waye yii.”

Bakan naa nigba toun naa n sọrọ, Họnarebu Damilọla Ṣonẹyẹ to n ṣoju ẹkun Ọbafẹmi Owode jẹ ko di mimọ pe ipo akọkọ ti ko ni ẹlẹgbẹ ni ipo olori ile igbimọ aṣofin jẹ.

O ni “nitori awọn iwa ajẹbanu, aini afojusun rere, aini otitọ, igberaga, idari ti ko ni ọjọ iwaju rere ati kikọju awọn aṣofin sira wọn ni a ṣe yọ Oluọmọ nipo.''

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun yọ olórí ilé nípò

Ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ti yọ aṣofin Ọlakunle Oluọmọ gẹgẹ bi olori ile igbimọ naa.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kinni, ni awọn aṣofin mejidinlogun ninu ogun buwọ lu iwe ti wọn fi kede yiyọ Oluọmọ.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan aṣofin naa ni, aṣilo agbara, aini afojusun rere, aiṣe otitọ, ṣiṣe owo kumọkumọ ati awọn ẹsun miran.

Ọnarebu Oludaisi Ẹlẹmide t'oun n ṣoju ẹkun Ọdẹda nile igbimọ aṣofin ni wọn kede gẹgẹ bi ẹni ti yoo rọpo Oluọmọ, ti wọn si paṣẹ pe ko bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ.

Aworan iwe ti wọn fi yọ Oluomo ni ile igbimọ aṣofin Ogun

Ki lo sẹlẹ saaju?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọdun 2022 ni awuyewuye bẹ silẹ laarin olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Olakunle Oluomo ati igbakeji rẹ, Oludare Kadiri.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022, ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Najiria, EFCC, mu olori ile aṣofin naa fun ẹsun kiko owo ilu jẹ.

Ọwọ tẹ ẹ ni papakọ ọkọ ofurufu Murtala Muhammed niluu Eko.

Wọn fi ẹsun kan Ọgbẹni Oluomo ati awọn aṣofin mii, pe wọn yí iwe, wọn si tun ṣe mago-mago iwe akọsilẹ owo ile aṣofin naa.

O lo ọjọ diẹ ni ahamọ ajọ naa, ki wọn to o pada yọnda rẹ, botilẹ jẹ pe iwadii ṣi n lọ lori ẹsun naa.

Diẹ lara awọn ọmọ ile aṣofin naa, to fi mọ olori ile funra rẹ si lo gbagbọ pe, wọn igbakeji lo ditẹ pẹlu EFCC lati parọ ole mọ Ọgbẹni Oluomo.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, igbakeji ile aṣofin naa, Ọgbẹni Oludare Kadiri, sọ pe olori ile fi orukọ oun fọwọ si awọn iwe owo kan to to ọgọrun miliọnu Naira ti oun ko mọ nipa rẹ.

Bakan naa lo sọ pe awọn igbesẹ olori ile naa le sọ oun di eero ẹwọn lọjọ iwaju ni oun ṣe kesi EFCC.

Ṣugbọn ninu ọrọ rẹ, Aṣofin Oluomo to jẹ olori ile sọ pe fifi ẹjọ sun EFCC tako ofin ihuwasi awọn aṣofin.