Ẹ wo Òkè Àgbélé tí ìtàn sọ pé obìnrin kan pẹ̀lú ọmọ tó pọ̀n sẹ́yìn ló paradà dì í

Itan kan ninu Bibeli sọ pe arabinrin kan to jẹ iyawo Lọọti, aburo Abraham, di ọwọn iyọ nitori pe o boju wẹyin.
Bẹẹ gan an ni ọrọ ri fun apata iyanu kan to wa niluu Igbeti, nipinlẹ Oyo.
Apata yii ti wọn n pe ni Oke Agbele, ni itan sọ pe obinrin kan ti oju ọmọ n pọn pada bimọ lẹyin ti wọn ṣe awọn etutu kan fun un.
Itan naa sọ pe obinrin ọhun pada bimọ, to si pada wa si ori oke kan, pẹlu babalawo, lati san ẹjẹ to jẹ nigba to n wa ọmọ.
Amọ wọn fun ni ikilọ kan bo ṣe n gun oke naa, pẹlu awọn nnkan to fẹ fi san ẹjẹ to gbe ru si ori.
“Wọn fi ye e pe lilọ lo n lọ si ori oke yii o, ma wo ẹyin.”
Amọ obinrin naa dẹja, eyi to mu ko di okuta nla.
Okuta ti igbagbọ wa pe obinrin naa di, ni wọn n pe ni Oke Agbele titi di oni.
Ori apata ti Oke Agbele duro si ni wọn n pe ni Oke Amule.
Gẹgẹ bo ṣe sọ fun BBC Yoruba, Alagba Alawode Ganiyu, to jẹ onimọ nipa itan ilu, o ni oke Agbele jẹ ọkan lara awọn iṣẹ iyanu ti Ọlọrun kan da silẹ, “ṣugbọn to ni itan to gbe e lẹyin”.
Ninu alaye rẹ nipa Oke Agbele lo ti sọ pe irisi oke naa da bi i pe eeyan ru ẹru sori, to si tun pọn ọmọ sẹyin.
“Iyalẹnu lo jẹ lati ri iru okuta yii ni Igbeti, nitori pe awọn onimọ fiye wa pe ilẹ aṣalẹ ni iru okuta naa ma n wa, amọ ilẹ igbo ni eleyi wa.
“Eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.”
Bakan naa lo sọ pe arọba itan sọ pe awọn eeyan kan wa lati ilẹ Ibariba lẹyin ti wọn gbọ pe ko si nnkan ti eeyan tọrọ ni ori oke Iyamọpo, ti ko nii ri gba.ọmọ
“Wọn tọrọ pe ki ojo rọ nillu wọn, ojo si rọ.
“Nigba ti wọn n pada bọ wa a san ẹjẹ ni wọn mu obinrin kan lẹyin, ti ko ri ọmọ bi.”
Alagba Alawode sọ pe obinrin naa ko pa ikilọ ti wọn fun un mọ, nigba to pada wa a dupẹ pe o ri ọmọ bi, lo mu ko di okuta.
“Wọn ni ko ma wo ẹyin titi ko fi ni i ri Oke Iyamọpo mọ.
“Ọgangan ibi to de to ti wẹyin, naa lo di okuta si.”
Ẹlomiran to tun ba BBC sọrọ, Ọgbẹni Adekunle Oluwọle, to jẹ ọmọ ilu Igbeti, o ni s ko si nnkan to buru ki awọn eeyan ma a wa wo oke naa gẹgẹ bi nnkan iyanu l’agbaye.
Ọgbẹni Oluwole sọ pe awọn ti gbe igbesẹ lati mu ki idagbasoke ba awọn nnkan afẹ naa.



