''Ètò fífún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ St. James Primary school lóúnjẹ kò dúró láti ìgba táwọn ọmọ kan ti dèrò ilé ìwòsàn''

Ijọba ipinlẹ Osun ti sọ pe oun ko da eto fifun awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ St. James Primary School, lagbegbe Owo Ope niluu Osogbo duro lati igba tawọn akẹkọọ ile ẹkọ ọhun kan dero ile iwosan lẹyin ti wọn jẹun tan loṣu Kejila ọdun 2023.
Oludamoran fun gomina ipinlẹ Osun, Ayodele Oluseyi ni o fi idi ọrọ yii mulẹ.
Arábìnrin Oluseyi sọ pe lati igba ti isẹlẹ naa ti sẹlẹ, fi fun awọn akẹ́kọ̀ọ́ loúnjẹ n tesiwaju ti ko si si wahala kankan rara lori rẹ.
O fi kun ọrọ pe ìjọba ipinle Osun labẹ ìṣejọba Gomina Ademola Adeleke ti gbe eto kan kalẹ, eyi to fi yan awọn ti yoo ma se abẹwo sile ẹ̀kọ́ kọọkan lati yẹ ounje ati agbegbe ti awọn tí ìjọba gba lati maa da ina oúnjẹ naa wo finnifinni.
Arabinrin Oluseyi wa pàrọwà fun awọn obi lati maa se itọju awọn ọmọ wọn daadaa.
Ẹwẹ, arabinrin Adebayo Aminat to jẹ ọkan lara obi awọn ọmọ to dero ile iwosan lẹyin ti wọn jẹ oúnjẹ nile ẹkọ ST James Primary school sọ pe ''lati igba ti isẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni mo ti mu ọmọ mi kuro nile ẹkọ ST James Primary school ti mo si mu lọ si ile ẹkọ aladani kan nilu Osogbo.''
BBC Yoruba ṣabẹwo si St. James Primary School
BBC Yoruba se abẹwo sile ẹkọ ST James Primary school lati wo bi wọn ṣe n ṣeto ounjẹ ti wọn n fawọn awọn akẹkọọ knibẹ.
Arakunrin Bunmi Ajala ẹni to jẹ Ọga ile ẹkọ ST James Primary school sọrọ lori ibi ti ọrọ oúnjẹ fi fun awọn akẹkọ ile ẹkọ naa gbe duro.
Arakunrin Ajala ti sọ pe, lẹyin ti isẹlẹ naa sẹlẹ tan ní wọn gbe oun wa si ile ẹkọ ST James Primary school.
Sugbọn o ṣalaye pe lati igba ti oun ti de, oúnjẹ fifun awọn akẹkọọ ko da ọwọ duro lati igba na.
Ọga ile ẹkọ naa ni ko si wahala kankan lori ounje awọn ọmọ naa rara ti di asiko yii.
Arakunrin Ajala wa parọwa fun awọn obi to ti mu awọn ọmọ wọn kuro, pe, ki wọn da wọn pada nitori iru isẹlẹ naa ko ni waye mọ.
Bakan naa lo tun rọ ìjọba ki wọn mase da ọwọ iranwọ ounjẹ ti wọn n ṣe naa duro rara.















