Báàlù tó gbé àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Ukraine tí Russia mú l'ẹ́rú já lulẹ̀

Oríṣun àwòrán, RUSSIAN TELEGRAM
Ọkọ baalu ologun orileede Russia kan to gbe awọn eeyan ti ja lulẹ ni apa Guusu Belgorod lẹba ibode pẹlu Ukraine.
O kere tan awọn ọmọ ilẹ Ukraine mẹrindinlọgọrin ti Russia ko lẹru lo padanu ẹmi wọn gẹgẹ bi ileeṣẹ alaabo Russia ti ṣe sọ.
Ile iṣẹ iroyin Ria Novosti sọ pe eeyan mẹsan-an mii wa ninu ọkọ ofurufu yii to fi mọ awọn mẹfa to jẹ oṣiṣẹ inu baalu.
A ko tii le fidi ọrọ mulẹ lori gbogbo iroyin taa gbọ nipa iṣẹlẹ yii.
Oju opo ileeṣẹ iroyin Ukrainska Pravda sọ pe awọn gbọ lẹnu awọn alaṣẹ Ukraine, pe baalu naa n gbe awọn nnkan ija ogun ati ado oloro fun idaabo bo ofurufu S-300 Russia.
Wọn ko darukọ nkankan to jọ mọ ọrọ awọn ti wọn ko lẹru ogun.
Awọn ileeṣẹ iroyin Ukraine kan n daba pe o ṣeeṣe ki o jẹ pe awọn ọmọ ogun Ukraine lo fi ado oloro ja baalu naa bọ ṣugbọn wọn pada pa awọn iroyin yii rẹ.
Gomina agbegbe Belgorod Vyacheslav Gladkov sọ pe iroyin iṣẹlẹ naa ti de eti igbọ oun amọ oun ko le ṣe afikun si nkan to ṣẹlẹ.
Fidio kan to n lọ kaakiri ori ayelujara ṣafihan baalu kan to n ja lulẹ, ti ibugbamu si tẹle lẹba abule Yablonovo.
Abule yii jina ni iwọn aadọrin kilomita si ila oorun ariwa Belgorod.
Nkan bi aago mọkanla owuro ni iṣẹlẹ ọhun waye.
Gẹgẹ bi Ria Novosti ṣe sọ ''wọn fẹ lọ ṣe paṣiparọ awọn ti wọn ko lẹru ogun yii ni''
A ko le fidi ọrọ yi mulẹ pe bẹẹ lo ri.
Agbẹnusọ aarẹ Russia, Dmitry Peskov, sọ pe ọrọ yi ti de eti igbọ ijọba, ṣugbọn o kọ lati ṣe ẹkunrẹrẹ alaye lori rẹ.












