Ìkọlù Russia sí Ukraine gbẹ̀mí èèyàn 18 lọ́jọ́ Ẹtì

Ikọlu ado oloro ti Russia ṣe si Ukraine mọjumọ ọjọ Ẹti

Oríṣun àwòrán, Reuters

Eeyan mejidinlogun ti padanu ẹmi wọn sinu akọtun ikọlu ti Russia tun gbe dide si Ukraine.

Orilẹede Russia tun ṣina ogun le awọn ilu kan lorilẹede Ukraine lọjọ Ẹti.

Aarẹ orilẹede Ukraine, Volodymyr Zelensky sọ pe gbogbo ohun ija ti Russia ni lo fi dojukọ Ukraine mọju ọjọ Ẹti.

Zelensky ni ile iwaosan igbẹbi kan wa lara awọn ibi ti ado oloro ti Russia ju ti ṣọṣẹ

Lara awọn ilu to fara kaasa ikọlu Russia naa ni Kyiv, Lviv lẹkun iwọ oorum Ukraine; Odesa ati Zaporizhzhia lẹkun gusu orilẹede naa nigba ti ina tun dahun ni ilu Dnipro ati Kharkiv lẹkun ila oorun Ukraine.

Ado oloro mejidinlaadọjọ (158) ni Russia ju si Ukraine – Ileeṣẹ ọmọogun

Ikọlu ado oloro ti Russia ṣe si Ukraine mọjumọ ọjọ Ẹti

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ileeṣẹ ọmọogun Ukraine ni awọn ado oloro to le ni mejidinlọgọjọ (158).

Ileeṣẹ ọmọogun ofurufu nibẹ ṣalaye pe awọn ko tii ri iru ikọlu bẹẹ leyi ti ọpọlọpọ agbegbe yoo maa foju wina ikọlu ado oloro lẹẹkannaa.

Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni Ukraine ti kọlu ọkọ ijagun ojuomi ti Russia.

Awọn ọmọde wa lara awọn to ṣeṣe ni Odesa

Ikọlu ado oloro ti Russia ṣe si Ukraine mọjumọ ọjọ Ẹti

Oríṣun àwòrán, Reuters

Gomina ẹkun Odesa, Oleh Kiper ni eeyan meji lo ku ni Odesa.

O ni awọn ileegbe ni Russia doju ado oloro rẹ kọ nibi ti awọn eeyan to ju mejila lọ ti ṣeṣe, meji ninu wọn lo jẹ awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹwaa lọ.

Iye awọn to ti ku ti di mejidinlogun

Awọn ilu to fara kaasa ikọlu ọjọ Ẹti

Ikọlu ado oloro ti Russia ṣe si Ukraine mọjumọ ọjọ Ẹti

Oríṣun àwòrán, Oleg Kiper

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Ukraine fi idi rẹ mulẹ pe eeyan mejidinlogun lo ti ku lapapọ.

Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Telegram rẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ni eeyan mejilelaadoje (132) pẹlu lo farapa.

Atupalẹ iye awọn to ku ni ilu kọọkan niyi:

  • Dnipro – Eeyan marun un ku, mejidinlọgbọ̀n ṣeṣe. Ọmọde kan ati ọlọ kan wa lara wọn.
  • Kharkiv – Eeyan mẹrin ku, mẹtala ṣeṣe.
  • Zaporizhzhia – eeyan mẹrin ku, mejila si fara pa.
  • Odesa – eeyan meji ku, mẹtadinlọgbọn fara pa, igbagbọ si tun wa pe pọ miran ṣi wa labẹ awọn awoku ile ti awọn ado oloro naa ba.
  • Lviv – Eeyan kan ku, mẹtadinlọgbọ̀n farapa