Ìjọba Saudi Arabia yóò fàyè gba ilé ọtí àkọ́kọ́ láti ọdún 1952

Bar Saudi

Oríṣun àwòrán, getty images

Orilẹ-ede Saudi Arabia ti kede pe oun yoo ṣi ile ọti kan laipẹ.

Ile ọti naa ni yoo jẹ akọkọ iru rẹ ninu itan Saudi Arabia lati nnkan bii aadọrin ọdun sẹyin, yoo si wa fun awọn alejo tii kii ṣe Musulumi nikan.

Awọn alaṣẹ Saudi sọ pe awọn ti yoo maa na ile ọti naa yoo jẹ awọn aṣoju ijọba ilẹ okeere ti wọn ti maa n ko ọti wọ ilẹ naa ṣaaju ninu apo ilewọ ti wọn n pe ni “diplomatic pouches.”

Wọn ni ile ọti ọhun yoo gbogun ti iṣoro tita ọti lọna ti ko ba ofin mu nilẹ ọhun.

Lati ọdun 1952 ni Saudi ti fofin de ọti tita, iyẹn lẹyin ti ọkan lara awọn ọmọkunrin ọba Abdulaziz yinbọn pa aṣoju ilẹ Gẹẹsi kan lẹyin to mu ọti yo tan.

Ileeṣẹ iroyi AFP ati Reuters jabọ pe agbegbe ti awọn aṣoju ijọba ilẹ okeere n gbe ni ile ọti naa yoo kalẹ si, ati pe laarin ọsẹ diẹ si asiko yii ni wọn yoo ṣi ile ọti ọhun.

Wayi o, yatọ si pe ile ọti naa kii ṣe fun gbogbo araalu, awọn ofin mii tun ran mọ ọ.

Awọn ofin wọn yii ni yoo rọ mọ ile ọti naa

  • Awọn to ba fẹ mu ọti gbọdọ forukọsilẹ ṣaaju ki wọn to wa sibẹ, wọn si gbọdọ gba aṣẹ ijọba lati lọ mu ọti nibẹ
  • Ko ni si aye fun ẹnikẹni ti ọjọ ori rẹ ko tii to ọdun mọkanlelogun, awọn alejo ile ọti naa si gbọdọ wọ aṣọ to tọ
  • Ko ni si aye lati ra ọti fun ẹlomiran, fun apẹrẹ eeyan ko ni le ran awakọ tabi oṣiṣẹ rẹ lati ra ọti fun un
  • Ko si ni amuyo nitori gbedeke yoo wa fun iwọn ọti ti eeyan le mu laarin oṣu kan

Ẹwẹ, Reuters jabọ pe awọn ofin naa ko ni mulẹ ju bo ṣe yẹ lọ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, eewọ ni ọti mimu labẹ ẹsin Islam, amọ awọn ilẹ ẹlẹsin Musulumi bii UAE ati Qatar ti faye gba ọti tita lawọn ile ijo kan.