War in Yemen: Àwọn ìpànìyàn òṣèlú tí UAE gbọ́ búkàátà rẹ̀

Huda al-Sarari

Oríṣun àwòrán, Jack Garland/BBC

Àkọlé àwòrán, The son of Yemeni human rights laywer Huda al-Sarari's was fatally shot in 2019
    • Author, Nawal al-Maghafi
    • Role, BBC News Arabic Investigations

Iwadii ileeṣẹ BBC ti safihan pe orilẹede United Arab Emirates se owo iṣekupani oloṣelu kan, eyi to fa ija laarin orilẹede Yemen ati ikọ agbesunami, eyi to tun ti pada si oju awọn orilẹede agbaye, to si tun ti buru si.

Idanilẹkọ nipa kikoju eto abo ti orilẹede Amẹrika fun ikọ ologun Emirati ni Yemen ni wọn lo lati fi kọ awọn eeyan kan ti wọn n sisẹ labẹ lẹ- eyi ti jẹ iṣekupani laarin oṣelu gbooro, ọkan lara awọn pariwo sita sọ fun BBC Arabic.

Bakan naa ni iwadii tun safihan bo tilẹ jepe ikọ ologun Amẹrika sọ pe idi ti awọn fi ṣe idanilẹkọ naa ni lati fi ogun ja awọn ikọ agbebon al-Qaeda ati Isalamic State ni guusu orilẹede Yemen. Kọda, UAE gba ọmọ oloogun al-Qaeda tẹlẹri si sinu ikọm ologun kanti wọn da silẹ ni Yemen lati koja ija si ikọ Houthi ni awọn ikọ agbebọn mii.

Ijọba UAE ti ni irọ esi iwadii wa pe wọn ṣekupa awọn eeyan ti ko mọwọ ninu sise akoba fun eto abo, ti wọn irọ to jina sootọ ni, ti ko si ni ẹsẹ ni ilẹ rara.

O le ọgọrun iṣekupani to ti waye laarin ọdun mẹta ni Yemen, ohun kan lo fa gbọnmisi omi o to laain awọn orilẹede alagbara lagbaye ti n wọn fi koju ija si ara wọn ni awọn orilẹede Middle East

Isẹlẹ yii ko fi aye silẹ fun didagbara pada ni ijọba Yemen ti ti awọn ajọ agbaye fi ontẹ lu.

Eyi, eeyan le ni o ti fun Houthis ti orilẹede Iran n se atilẹyin fun ni iwuri si,- to si jẹ pe wọn n wa ninu iroyin fun bi wọn se n se ikọlu sio ọkọ oju omi, ti wọn si n dena de karakata ni lori okun pupa(Red Sea).

Laipẹ yii ni Ile ijọba Washington kede sita pe awọn yoo kede ikọ naa gẹgẹ bi ikọ agbesunami lẹkansi.

Mo n ti n kọ iroyin nipa rogbodiyan to n sẹlẹ ni ilu mi Yemi lati igba to ti bẹrẹ ọdun 2014.

Rogbodiyan jẹ ki ijọba padanu asẹ lori apa ariwa orilẹede Yemen sọwọ Houthis,- ti wọn si n ni agbara si pẹlu awọn ohun ija bi ọdun se n kọja.

Lọdun 2015, US ati UK se iranlọwọ fun awọn ẹgbẹ kan lati ilẹ Arabs eyi Saudi Arabia lewaju pẹlu UAE naa lati ja. Ifọwọsowọpọ yii lo si ogun wọ Yemen pẹlu erongba da ijọba ti wọn gba rẹ wọle pada si ijọba ati koju igbesunami.

UAE lo wa ni isakoso eto abo fun guusu, eyi to sọ di amugbalẹgbẹ US lato koju igbesunami ni ẹkun ijọba naa- al-Qaeda ti wa ni guusu fun igba pipẹ, ti wọn si n gba isakoso agbegbe naa.

Ija Yemen

  • Lọdun 2014, awọn ikọ agbebọn kan ti orukọ n jẹ Houthis, ti wọn wa lati apa ibi kan ni Yemen, Shia to jẹ agbegbe Musulumi ti wọn gba agbara olu ilu Sanaa.
  • Aarẹ Abdrabbuh Mansour Hadi da olu ilu ranpẹ si agbegbe guusu ilu Aden lẹyin to ri bi salọ lati ti wọn fi pamọ si ile rẹ lọdun 2015.
  • Saudi ati awọn orilẹede mii lati Arabs bẹrẹ ipolongo lati tako Houthis , ti wọn fẹsun kan Iran pe oun lo n pese ohun ija fun wọn. Ẹgbẹ ti Saudi lewaju n iranlọwọ irinsẹ lọwọ US, UK ati France
  • Awọn ẹgbẹ ti wọn fọwọsowọpọ n bara wọn ja. Ninu oṣu kẹjọ ọdun 2019, ija bẹ silẹ ni guusu laarin ikọ ti ijọba Saudi se atilẹyin fun ati ikọ Southern Transitional Council to fẹsun kan Aarẹ Hadi fun bi o na inakuna ati ibaṣepọ rẹ pẹlu ikọ agbebọn ti musulumi.
  • Awọn ologun agbesunami lati al-Qaeda ni Arabian Peninsula(AQAP) ati mikọ ologun agbesunami abẹle (IS) n lo anfani rogbpdiyan naa lati gba awọn ibudo ni guusu ati lati se ikọlu nla ni Aden.
  • Ikọ Houthis tun se afikun si bi wọn se tan ka- ninu oṣu kọkanla ọdun 2023, wọn se awọn ikọlu kan si karakata ni ori omi Red Sea.

Sugbọn kakaki alaafia jọba, rogbodiyan naa n tan si ni. Lasiko ti mo n rin irinajo iwadii, mo fi oju gan ni awọn isẹlẹ iṣekupani ni awọn agbegbe ti ijọba n se akoso le lori ni guusu agbegbe Yemen, ti wọn si n sekupa awọn araalu ti ko mọ nnkan nipa isẹlẹ yii.

Labẹ ofin agbaye, sise iku pa araalu lodi sofin. Pupọ awọn ti wọn gba ẹmi wọn ni wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Islah- ẹgbẹ awọn musulumi ni Yemen.

Ẹgbẹ yii jẹ ẹgbẹ kan to jẹ ilumọka ti orilẹede Amẹrika ko ti kede rẹ gẹgẹ ẹgbẹ agbesunanmi sugbọn ọpọ awọn orilẹede Arab lo ti fofin de wọn paapa ni UAE

Fọnran kan to safihan iṣekupani akọkọ to rapala jade sita lo fun anfani lati le bẹrẹ iwadii awọn iṣekupani yii.

Mo pade ọkan lara awọn to se iṣekupani naa to wa ninu fọnran ni ile ounjẹ kan niluu London lọdun 2020.

Isaac Glimore, jẹ osisẹ ileeṣẹ ologun oju omi to pada di ọga agba, to si wa lara awọn ologun to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika ti UAE gba lati ma sekupa awọn eeyan ninu Yemen.

Isaac Gilmore

Oríṣun àwòrán, Jack Garland/BBC

Àkọlé àwòrán, Isaac Gilmore was paid by the UAE to carry out targeted killings
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O kọ lati sọrọ nipa awọn to wa ninu iwe akọsilẹ eeyan ti wọn fẹ ẹ pa, eyi ti ikọ Spear lati UAE fi kalẹ - Ansaf Mayo, aṣofin kan ni Yemen, to tun jẹ olori ikọ Islah niluu Aden, nikan ni orukọ rẹ jẹyọ.

Idahun ti Ọgbẹni Gimore fun mi lori pe ijọba America ko fi igba kankan pe Islah ni ikọ agbesunmọmi, ni pe ni Yemen, ẹni to jẹ olori ilu fun ẹnikan, le jẹ olori ikọ igbesunmọmi fun ẹlomii.

Ọgbẹni Gilmore ati oṣiṣẹ Spear kan ni Yemen lasiko naa - Dale Comstock - sọ fun mi pe ọdun 2016 ni awọn ṣe ipaniyan naa.

Iwadii wọn fihan pe ọgọjọ ipaniyan lo waye ni Yemen laarin ọdun 2015 si 2018. Eeyan mẹtalelogun pere si lo ni nnkan ṣe e pẹlu igbesunmọmi ninu wọn.

Ilana kan naa si ni iku n wọn n gba - wọn o ju ado oloro silẹ lati fi ru awọn eeyan loju, asiko naa ni wọn o yinbọn mọ ẹni ti wọn fẹ ẹ pa.

Ipaniyan to lọwọ oṣelu ninu to waye laipẹ yii ni Yemen, gẹgẹ bi agbẹjọro too n ja fun ẹtọ ọmọniyan ni Yemen, Huda al-Sarari ṣe sọ, waye ni oṣu to kọja - iku imaamu kan ni Lahj, nipasẹ ilana kan naa.

Ọgbẹni Gilmore, Ọgbẹni Comstock, ati awọn alagbapa meji ti wọn ko fẹ ka darukọ wọn, sọ pe Spear lọwọ ninu kikọ awọn ọmọ ogun UAE ni ogun jija nibudo kan ni Aden. Akọroyin kan naa sọ fun wa pe oun ti ri fidio awọn ikọṣẹ naa.

Ansaf Mayo
Àkọlé àwòrán, Ansaf Mayo, leader of al-Islah, who was targeted by Spear and now lives in exile

Nitori bo ṣe dabi i pe aṣiri awọn alagbapa naa le tu ni Aden, wọn yi akọsilẹ nipa iṣẹ wọn pada si kikọ awọn ọmọ ogun UAE ni iṣẹ. Awọn wọnyii ni yoo kọ awọn eeyan ni Yemen.

Eeyan to le ni ,ejila la tun ba sọrọ, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọr ri bẹẹ.

Lilo awọn ọmọ orile-ede Yemen fun ipaniyan naa tumọ si pe ẹnikẹni ko le ronu kan UAE pe oun lo wa nidi rẹ.

Gbigbe iṣẹ agbenipa fawọn eeyan Yemen tumọ si pe o maa nira lati mọ pe orilẹede UAE lo wa nidi iṣekupani naa.

Lọdun 2017, UAE ṣe iranwọ lati kọ ile igbimọ aṣofin, eyi to wa lara awọn nkan ti Emirati ṣe agbatẹru rẹ, Emirati yii lo jẹ ikọ ologun to n ṣakoso agbarijọpọ awọn sọja kaakiri guusu Yemen.

Ikọ ologun yii n ṣiṣẹ lẹkun Guusu Yemen fun ijọba orilẹede Yemen, amọ lati UAE ni o ti n gba aṣẹ.

Kii ṣe iwaju ogun nikan lawọn lawọn omogun yii ti gba idanilẹkọ.

Awọn kan wa lara wọn ti wọn ti gba ẹkọ lori iṣekupaniyan, gẹgẹ bi ami kan to tu aṣiri ṣe sọ fun wa.

Ẹni to tu aṣiri naa sọ nipa orukọ mọkanla ọmọ ẹgbẹ al-Qaeda tẹlẹ ti wọn n ṣiṣẹ pẹlu ikọ STC bayii.

A ba orukọ Nasser al-Shiba pade ninu iwadii wa, ọga ni o jẹ ninu ẹgbẹ al-Qaeda tẹlẹ.

Koda o lọ sẹwọn lori eṣun igbesunmọmi, amọ, o pada gba ominira nigba to ya.

Minisita ijọba Yemen kan sọ fun wa al-Shiba to jẹ afurasi ninu ikọlu ọkọ oju-omi ijagun orilẹede Amẹrika USS Cole ninu eyi ti awakọ oju omi mẹtadinlogun to jẹ ọmọ Amẹrika ti padanu ẹmi wọn lọdun 2000.

Ọpọ lo sọ fun wa pe o wa lara awọn ọga to n dari ọkan lara awọn ikọ ologun ajọ STC.

Agbẹjọro Huda al-Sarari ti n ṣe iwadii bi ikọ ologun yii ti UAE n ṣe atilẹyun fun ṣe n tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.

Ọpọ lo ti n dunkoko mọ ọ nirori iṣẹ iwadii to n ṣe, ọmọkunrin rẹ ọmọ ọdun mejidinlogun lo fori faa.

Aya ni wọn ti yinbọn fun un loṣu kẹta ọdun 2019 lọna rẹ si ile epo, oṣu kan si asiko ti wọn yinbọn fun un lo dagbere faye.

Nigba ti Huda bẹrẹ iṣẹ rẹ pada lẹyin ti ọmọ rẹ ku, o ni, awọn kan kilọ foun pe ki oun da iṣẹ naa duro.

wọn sọ pe ''ṣe ọmọkunrin rẹ ti a pa ko to ẹ ni? Ṣe o fẹ ki a pa omiran ni?''

Iwadii ti olupẹjọ ijọba ti Aden dari rẹ fihan pe ọmọ ẹgbẹ ikọ kan to n kọju ija si awọn agbesunmọmi eyi ti UAE n ṣe atilẹyin fun lo ṣekupa Moshen.

Awọn eeyan to wa ni ọfiisi olupẹjọ ijọba ti a ko le darukọ sọ fun wa pe iṣẹlẹ iṣekupani to wọ pọ ti da ibẹrubojo silẹ eyi to jẹ kawọn naa maa bẹru lati fẹ beere fun idajọ ododo lori ẹsun to nii ṣe pẹlu awọn ologun ti UAE n ṣe atilẹyin fun.

Iwe atẹjiṣẹ kan lati ọwọ UAE lo lu sita fidi rẹ mulẹ pe Spear si gbowo lọdun 2020, amọ, ko si ẹni to mọ ohun ti owo naa wa fun.

A beere lọwọ oludasilẹ ikọ Spear, Abraham Golan, boya awọn to n ba a ṣiṣẹ ṣe idanilẹkọ fun Emiratis lori iṣekupaniyan, ṣugbọn ko fesi.

Gbogbo ẹsun to wa ninu iwadii wa ni a bi ijọba UAE leere.

Ijọba UAE sọ pe irọ pe oun doju ija kọ ẹnikẹni to ni ohunkohun ṣe pẹlu igbesunmọmi, ati pe oun ṣe atilẹyin fun kikọju ija si igbesunmọmi ni Yemen nigba kugba ti ijọba Yemen pe oun.

Ijọba UAE sọ pe ''oun ti gbe igbesẹ ni ibamu pẹlu ofin to de awọn orilẹede lagbaaye lasiko awọn ikọlu to waye.''

A beere lọwọ ileeṣẹ ijọba Amẹrika to n ri si ọrọ eto abo lati sọ fun wa nipa ikọ Spear, ṣugbọn wọn kọ lati sọrọ.

Ikọ ọtẹlẹmuyẹ ijọba Amẹrika sọ ninu atẹjade kan pe ''irọ ni ero awọn eeyan kan pe ajọ CIA yọwọ ninu ija ti wọn n sọrọ rẹ.''