Ohun tí òfin Nàìjíríà sọ rèé nípa ìgbéyàwó akọ s’ákọ àti abo s’ábo, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kìlọ̀

Aworan ọgagba ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, Prince Olumuyiwa Adejobi/X

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kilọ fun araalu pe ofin orilẹede Naijiria ko faye gba igbeyawo laarin akọ si akọ ati abo si abo.

Ikilọ yii waye lẹyin tawọn eeyan kan sọ ninu fọnran to lu ori ayelujara pa laipẹ yii pe ẹgbẹ akọ sakọ ati abo sabo ni awọn wa.

Ninu atẹjade to fi sita loju opo X rẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi ni o ṣe pataki fun ileeṣẹ ọlọpaa lati ran awọn araalu leti ohun ti ofin sọ nipa igbeyawo akọ sakọ ati abo sabo ni Naijiria.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ofin lawọn ipinlẹ apa guusu Naijiria, ‘’oju ewe 214 si 217 sọ pe iwa ọdaran ni ibalopọ pẹlu ẹnikẹni lọna to yatọ si bi Eledua ti laa kalẹ.

Bakan naa, ofin ko faye gba biba ẹranko ni ibalopọ, ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ yii ba ṣi mọ lori yoo foju wina ofin.

Oju ewe 284 ofin to de awọn ipinlẹ apa ariwa Naijiria sọ nkan naa lori iwa yii.

Bakan naa, gbogbo eeyan ni lati mọ bayii pe ofin Naijiria ko faye gba igbeyawo laarin ọkunrin si ọkunrin ẹgbẹ rẹ tabi igbeyawọ laarin obinrin si obinfrin.

Iwa ọdaran ni Naijiria, koda wọn o gbọdọ fi ara wọn lawujọ gẹgẹ bi ọkọ ati aya.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

A n fi asiko yii ṣe ilanilọyẹ fwọn araalu ki wọn le mọ pe ẹnikẹni to ba tasẹ agẹrẹ yoo foju wina ofin.’’

Adejobi ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni beṣu bẹgba lati ri pe ẹnikẹni ko fọwọ pa ida ofin loju.

O wa ke si awọn araalu lati ta awọn ọlọpaa lolobo ti wọn ba kẹfin iru iwa bayii lawujọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni o yẹ ki gbogbo eeyan fọwọ so ọwọ pọ lati kọju ija si iru iwa yii lawujọ.

Adejobi wa ke pe awọn obi ati alagbatọ lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lati le dẹkun iwa ọdaran yii to lodi si aṣa orilẹede Naijiria.