Ibùdó ìwakùsà tó dàwó gbẹ̀mí ogójì ènìyàn

Oríṣun àwòrán, Getty Image
O kere tan eeyan ogoji lo ti padanu ẹmi wọn nigba ti ibudo iwakusa kan dawo ni Mali gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ti ṣe wi.
Omar Sidibe to jẹ ọkan lara awọn alaṣẹ ẹgbẹ awakusa sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe ariwo ni awọn kọkọ gbọ, ilẹ si bẹrẹ si ni mi jigijigi.
Aaye iwakusa yi dawo ni ibudo to wa ni guusu iwọ oorun agbegbe Koulikoro lọjọ Ẹti.
Titi di asiko yii, wọn ko tii sọ pato iye eeyan to padanu ẹmi ninu iṣẹlẹ naa.
AFP n jabọ pe awọn alaṣẹ kan n sọ pe o to eeyan aadọrin to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ọgbẹni Sidibe sọ pe ''o le ni igba awọn oṣiṣẹ iwakusa to wa nibẹ. Wọn ti dawọ idoola duro. A si ti ri oku awọn eeyan mẹtalelaadọrin.''
Agbẹnusọ ileeṣẹ iwakusa kan, Baye Coulibaly sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe iye awọn to padanu ẹmi wọn kọja ogoji.
Ijọba Mali ni awọn fẹdun ọkan han lori iṣẹlẹ naa ti wọn si ''fi ikini ikẹdun ranṣẹ sawọn idile to wa ninu ibanujẹ ati awọn eeyan Mali lapapọ''
Bẹẹ naa lo parọwa si awọn eeyan l'agbegbe ibi ti awọn ibudo iwakusa wa, lati tẹle ilana aabo ki wọn si ṣiṣẹ laaye ibi ti wọn ti le fọ goolu nikan.
Ijamba iwakusa kii ṣe nkan tuntun lorileede naa.
Ko si sẹyin bi ọpọ ṣe n wa kusa pẹlu awọn ilana ti ijọba ṣe lati maa fi wa kusa.
Arakunrin Coulibaly sọ pe ileeṣẹ awọn ti kilọ fawọn to n wa kusa lati yago faaye ti ijọba ko fọwọsi ṣugbọn ọpọ lo kọ eti ikun si ikilọ yi.
Ileeṣẹ naa tun sọ pe awọn yoo ṣe iwadii iṣẹlẹ yi ati pe awọn yoo gbe ikọ dide lọ si agbegbe naa lỌjọbọ.
Mali jẹ ọkan lara awọn orileede ni agbaye to lewaju ninu owo tita goolu.












