Ẹ wo àwọn adári tuntun fún ẹgbẹ́ ọmọ Yoruba, Afenifere

Oríṣun àwòrán, BBC/Facebook/Chief Adebanjo
Ẹgbẹ Afẹnifẹre ti wọgile ipo adele adari ati igbakeji rẹ, ti Oloye Ayo Adebanjo ati Oba Oladipo Olaitan di mu ninu ẹgbẹ naa.
Lẹyin Ipade oloṣooṣu ti o waye ni ilu Akure ni ile adari ẹgbẹ ọun, oloye Rueben Fasoranti, ni Afẹnifẹre ti ṣalaye pe igbesẹ naa ṣe koko lati dena ipinya ati dida igun ẹgbẹ miran silẹ.
Ẹgbẹ Afẹnifẹre gbe igbesẹ lati wọgile awọn ipo mejeeji lẹyin ti Otunba Samuel Ibikunle lati ipinlẹ Ogun mu aba naa wa nibi ipade ọhun.
Ibikunle sọ pe "esi iwadii igbimọ ti wọn gbe kalẹ lati pari ija ninu ẹgbẹ fihan pe a ti de ikorita ti atunṣe ko lee waye mọ".
Aba naa ni Niyi Ikumelo lati ipinlẹ Ondo keji rẹ, ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati ipinlẹ Ekiti, Kwara, Oyo, ati ipinlẹ Ondo si fọwọsi.
Adari ẹgbẹ naa, alagba Reuben Fasoranti waa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati tubọ gbaju mọ awọn nnkan ti ẹgbẹ Afẹnifẹre duro fun, ki wọn si jẹ ọmọluwabi ninu gbogbo idawọle wọn bii ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre ni ipinlẹ wọn.
Awọn ọmọ igbimọ tuntun ti Afenifere yan
Akọwe ẹgbẹ, ọgbẹni Ajayi wi pe awọn ọmọ igbimọ agba ẹgbẹ tuntun ni:
- Oloye Rueben Fasoranti gẹgẹ bi Alaga
- Oloye Ayo Adebanjo
- Olu Falae
- Sẹnetọ C. O. Adebayo
- Femi Okunrounmu
- Baṣọrun Seinde Arogbofa
- Sẹnetọ Kofo Bucknor Akerele
- Biṣọọbu Ayo Ladigbolu
- Ajagun-fẹyinti Alani Akinrinade
- Ajagun-fẹyinti Olu Bajowa
- Ọjọgbọn Bolaji Akinyemi
- Ọjọgbọn Banji Akintoye
- Otunba S. A. J. Ibikunle
- Oloye Femi Aluko
- Ọmọọba Alonge
- Dokita Yomi Finnih
- Ọmọọba Olusi
- Ọnọrebu Korede Duyile
- Ọjọgbọn Ropo Sekoni
- Ọnọrebu Lekan Alabi
- Dokita Kunle Olajide.















