Bí ìgbẹ́jọ́ ikú Whitney Adeniran ṣe lọ rèé lọ́sẹ̀ yìí

Oríṣun àwòrán, Others
Micheal Adeniran, Baba ọdọmọdebinrin oloogbe Whitney Adeniran to jẹ akẹkọọ ileẹkọ Chrisland Schools Opebi farahan si ileẹjọ giga ipinlẹ Eko Ikeja lọjọ Aje.
Adediran sọ fun ileẹjọ pe ọkan lara nọọsi ile ẹkọ naa sọ fun pe ọmọ oun ti jade laye saaju ki wọn to gbe e de Ile iwosan.
O ni nọọsi naa salaye fun oun pe oju ọmọ oun ti pade sugbọn ko le fidi rẹ mulẹ pe ọmọ ti ku nitori oun ko ki n se dokita.
Lọjọ kọkanlelọgbọn ọdun 2023 ni Ijọba ipinlẹ Ekọ gbe Chrisland School Limited Opebi ati ọga awọn akẹkọọ , igbakeji rẹ ati awọn meji mii lori iku ọkan lara akẹkọọ ileẹkọ, Whitney Adediran.
Iwaju Onidajọ Oyindamola Ogala ni wọn ti n jẹjọ.
Awọn olujẹjọ naa ni Ademoye Adewale, Kuku Fatia, Belinda Amao ati Victoria Nwatu, ti wọn jẹjọ lori ẹsun mimọ sekupa ((eyi ti kii ṣe taara) ati iwa pipa eniyan ti ti wọn fi kan ile ẹkọ Chrisland, awọn oṣiṣẹ wọn to fi mọ olutaja kan.
Nigba ti wọn bi Baba oloogbe pe se nitori Whitney se airẹ lo fa ti ko fi wa si ileẹkọ lọjọ Kejilelogun oṣu keji ọdun 2023.
Adeniran fesi pe “Ko wa si ileẹkọ lọjọ naa sugbọn ko ki n se nitori pe o se aisan.“
Ẹlẹrin na sọ pe ni Ogunjọ oṣu kinni ọdun 2023 ni ileẹkọ pe iyawo oun lati sọ pe o rẹ Whitney.
O ni ọmọ oun lọ si ile iwosan Inland Specialist to wa ni Ikeja, ti dokita si kọ awọn oogun fun lati lo sugbọn oun ko mọ orukọ oogun naa.
O tẹsiwaju alaye pe oun pada mọ orukọ oogun lẹyin ti oun gba esi dokita ni ile iwosan ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun 2023.
N ko se iwadii ogun ọmọ mi- Iya Oloogbe
Blessing Adeniran to jẹ iya oloogbe naa farahan siwaju ileẹjọ lati wi tẹnu rẹ.
Nigba to n sọrọ, o ni oun ko se iwadii kankan nipa oogun ti ọmọ lo nitori dokita lo kọ fun oun.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe oun ko ba ile ẹkọ Chrisland sọ ohunkohun nipa abọ oun lati ile iwosan.
O salaye pe Whitney ko ni anfani lati lọ si Ileẹkọ fun igba meji ọtọọtọ, ogunkọ oṣu kinni ati ọjọ keji oṣu keji nitori pe ara rẹ ko ya
“Mo pe ọkọ mi lati sọ fun pe ile ẹkọ ọmọ wa pe pe ara rẹ ko ya. O lọ gbe lati ile ẹkọ, to si gbe lọ si ile iwosan, to si ni ki emi darapọ mọ wọn.
“Nigba ti mo de ile iwosan, mo ba ọmọ mi ati Baba rẹ ti wọn n sere lori foonu ọkọ mi, ti ara rẹ si ya loju mi,
“Mo ni o da pe ẹ nifẹ lati wa si ile iwosan, ti gbogbo si bu sẹrin,”
O tẹsiwaju pe nigba ti dokita se ayẹwo tan, o ni pe ara rẹ ti ya, to si bere pe boya igbaradi idanwo lo fa kudiẹkudiẹ ilera naa sugbọn wọn pe oun gbaradi fun ere idaraya ileẹkọ ti a mọ si Inter House Sport.
O ni oun ko mọ iru itọju ti oogun ti wọn fun oun wa fun.
Nigba ti agbẹjọrọ Ile ẹkọ, Oloye Richard Ahonaruogho (SAN) ni bi iya oloogbe pe se ile iwosan Agege Central Hospital and Diagnostic sọ fun pe ipaya lo sekupa ọmọ naa, ẹlẹri naa ni wọn sọ fun oun.
Oloogbe naa ni wọn gbe lọ si ile iwosan yii lẹyin ti subu ni paapa isere .
Bakan ni Agbẹjọro Ahonaruogho bere lọwọ ẹlẹri pe se looto ni pe ina mọnamọna lo gbe oloogbe to fi ku, to si ni rara.
Ahonaruogho sọ fun ile ẹjọ pe oogun Nitrazepam ti wọn kọ fun awọn obi naa lo wa fun itọju awọn eeyan to ba ni ipaya ti Amitriptytline si wa fun awọn to ni irẹwẹsi ọkan.
O bi ẹlẹri pe se o mọ awọn nnkan yii, ti ẹlẹri si ni oun ko mọ.
Agbẹjọro ni nilo oogun mejeeji paapa fun ọmọde le laku lọ.















