Ọlọ́pàá mú ajìjàgbara Yorùbá Nation l’Eko lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n ti ń wá a

Aworan Olamilekan Odofin

Oríṣun àwòrán, X/ Benjamin Hundeyin

Ileeṣẹ ọlọpaa ti fọwọ ofin mu ajijagbara idasilẹ orilẹede Yoruba, Olamilekan Odofin lẹyin ti wọn ti n wa a fun ọdun kan.

Ninu ọrọ to fi lede loju opo X rẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, ṣalaye pe awọn ọlọpaa to wa ni agọ ọlọpaa Ayobo lo mu ọkunrin naa.

Hundeyin ni Odofin ṣiwaju ikọlu sawọn onimọto atawọn ọlọpaa lọjọ Kẹsan oṣu Kinni ọdun 2023 lorukọ ṣiṣe ijijagbara fun Yoruba Nation.

Agbẹnusọ ọlọpaa ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lẹyin ti ọwọ ti tẹ Odofin.

Hundeyin ni o kere tan, eeyan kan padanu ẹmi rẹ, nigba tawọn ọlọpaa meji farapa bakan naa lasikọ iwọde fun Yoruba nation.

O ni ọpọ ọkọ ni wọn tun bajẹ lasiko iwọde ọhun to waye ni agbegbe Ojota lọdun 2023 niluu Eko.

Aawọ bẹ silẹ laarin awọn ọlọpaa atawọn to n ṣe iwọde Yoruba nation lẹyin ti wọn n na ika alebu si ara wọn.

Awọn olufẹhonuhan naa ni awọn ọlọpaa lo wa nidi aawọ to ṣẹlẹ lẹyin ti wọn fẹ da iwọde awọn ru eleyii tawọn naa o gba.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post