Ọmọ Mr Ibu méjì kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn jìbìtì N55m táwọn èèyàn dá fún ìtọ́jú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/RealMribu
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti tẹ ọmọkunrin ati ọmọbinrin agbatọ fun gbajugbaja oṣere adẹrinposonu, John Okafor, ti ọpọ mọ si Mr Ibu lori ẹsun pe wọn ji owo tawọn eeyan da fun itọju agba oṣere naa.
Onyeabuchi Okafor ati Jasmine Okekeagwu ni wọn fẹsun kan pe wọn tọwọ bọ foonu oṣere naa, ti wọn si fi gba owo to to miliọnu marundinlọgọta Naira ninu apo owo banki rẹ.
Owo naa lo jẹ owo ti awọn ololufẹ agba oṣere naa da fun itọju Mr Ibu, lẹyin to bẹrẹ aisan lọdun to kọja.
Ọsẹ to kọja ni Mr Ibu pada sile lẹyin to ti wa nile iwosan fun ọpọlọpọ oṣu.
Aisan naa lo faa ti Mr Ibu fi padanu ọkan lara ẹsẹ rẹ.
O to isẹ abẹ marun un ti Mr Ibu lakọja, gẹgẹ bi mọlẹbi rẹ ṣe kede sita.
Iroyin kan sọ pe awọn alasẹ ti ri owo to to aadọta miliọnu gba pada.
Ileeṣẹ iroyin abẹlẹ ni agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa to n risi iwadii, Mayegun Aminat lo kede ọrọ naa.
Gẹgẹ bi Arabinrin Mayegun ṣe sọ, awọn afurasi mejeeji n gbiyanju lati sa kuro lorilẹede Naijiria ni ọwọ tẹ wọn.
Saaju ni ile ẹjọ kan nipinlẹ Eko gba beeli miliọnu mẹẹdogun fun awọn afurasi mejeeji bi iwadii se n tẹsiwaju .
Awọn afurasi mejeeji yoo pada si ile ẹjọ ninu oṣu Kẹta, ọdun 2024.















