Wolíì ni Bàbá mi Yẹmi Elebuibon, òun ló ra Bíbélì mi àkọ́kọ́ fún mi – Yetunde Elebuibon

Àkọlé fídíò, Wolíì ni Bàbá mi Yẹmi Elebuibon, òun ló ra Bíbélì mi àkọ́kọ́ fún mi – Yetunde Elebuibon
Wolíì ni Bàbá mi Yẹmi Elebuibon, òun ló ra Bíbélì mi àkọ́kọ́ fún mi – Yetunde Elebuibon

Eekan Oniṣẹṣe ni Oloye Yẹmi Ẹlẹbuubọbọn, Araba ilu Osogbo, gbogbo agbaye lo si mọ fun gbigbe aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba ga.

Amọṣa, akọbi rẹ Yetunde Ẹlẹbuibọn ni oun ko gba ọna iṣẹṣe ti baba oun atawọn aburo oun kan gba, koda pasitọ ijọ kristẹni ni lọwọ yii.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, ṣalaye wi pe Bibeli akọkọ ti oun ni gẹgẹ bi Kristẹni, Baba oun iyẹn Oloye Yẹmi Ẹlẹbuibọn lo raa fun oun.

O ni eeyan to ni ibẹru Ọlọrun pupọpupọ ni Oloye Ẹlẹbuibọn koda wolii ni pẹlu.

'Wolii ni Baba, O jẹ eeyan to fẹran Ọlọrun, to ni ibẹru Ọlọrun to dẹ gba gbogbo ẹsin laaye.

Baba mi ko binu sii nigba ti mo fẹ di Kristẹni

Aworan Yetunde Ẹlẹbuibọn pẹlu baba rẹ, Oloye Yẹmi Ẹlẹbuibọn.

Oríṣun àwòrán, whatsapp/Yetunde Elebuibon

Ninu alaye rẹ, o ni lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni oun ti bẹrẹ si ni ni ifẹ si ẹsin kristẹni nitori awọn iwoye ati irisi kan ti oun n ri lara awọn akẹgbẹ oun ti wọn wa lati idile onigbagbọ.

O fi kun alaye rẹ pe nigba ti oun fẹ di oluṣọ aguntan, baba oun, Oloye Ẹlẹbuibọn ko binu sii rara, nitori pe gẹgẹbi ọrọ rẹ, o ni "obinrin ko lẹsin" .