Ẹ jìnà sáwọn ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo l'Osun o, Adeleke ké sáráàlú lẹ́yìn tí èèyàn mẹ́fà kú níbi wàhálà káńsù

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/X
Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti ní ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dé àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yálà òṣìṣẹ́ tàbí olóṣèlú.
Ìdarí Adeleke yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí wáhálà bẹ́ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà lọ́jọ́ Ajé nígbà táwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí ilé ẹjọ́ dá láre ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá gbìyànjú láti gba ipò wọn padà.
Gómìnà náà fẹ̀sùn kàn pé àwọn alága àná gbìyànjú láti fi ipá gba àwọn ìjọba ìbílẹ̀ lọ́nà àìtọ́, tó sì jẹ́ pé ó yẹ kí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà wà ní títì pa nítorí àwọn òṣìṣẹ́ ti kò ní lọ sí ibiṣẹ́.
Àtẹ̀jáde kan tí gómìnà Adeleke fi léde lọ́jọ́ Ajé lórí ìkànnì X rẹ̀ ní òun ń gbé ìgbésẹ̀ láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Osun ni òun ṣe kéde pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ lọ sí àwọn ìjọba ìbílẹ̀.
Gómìnà Adeleke ní ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP márùn-ún ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù náà.
Nígbà tó ń bá ẹbí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn kẹ́dùn, ó ní ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP méjì ló jáde láyé ní Iragbiji, ìjọba ìbílẹ̀ Boripe, àwọn méjì míì tún pàdánù ẹ̀mí wọn ní ìjọba ìbílẹ̀ Ola Oluwa, tí ẹni karùn-ún sì jáde láyé ní Ikire.
Ó ní ó pọn dandan kí àwọn dáwọ́ ìtàjẹ̀ sílẹ̀ náà dúró ní kíákíá.
Yàtọ̀ sí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP márùn-ún tó pàdánù ẹ̀mí wọn, alága tẹ́lẹ̀ rí ní ìjọba ìbílẹ̀ Ayedire tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìkọlù náà.
Ó sọ pé ìdí nìyí tí òun fi darí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti gba gbogbo àwọn ìjọba ìbílẹ̀ lójúnà àti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn Osun.
Gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù ìpínlẹ̀ Osun ló máa fojú winá òfin - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Ẹ̀wẹ̀, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ti bu ẹnu àtẹ́ lu wàhálà tó ṣokùnfà ikú èèyàn mẹ́fà ní ìpínlẹ̀ Osun.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Nàìjíríà, Muyiwa Adejobi fi léde lọ́jọ́ Ajé ní ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà, Kayode Egbetokun ti darí kíkó àlékún ọlọ́pàá lọ sí ìpínlẹ̀ Osun láti mú ètò ààbò ìpínlẹ̀ náà gbópọn si.
Adejobi ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti mọ̀ nípa bí àwọn kan ṣe dá omi àláfíà ìpínlẹ̀ Osun rú, táwọn yóò sì ṣe gbogbo ohun tó wà ní ìkáwọ́ àwọn láti dá àláfíà padà sí ìpínlẹ̀ náà.
Ó ní ìwà jàgídíjàgan lòdì sí ètò ìjọba àwaarawa, tó sì máa ń mú ìpalara bá ìgbáyégbádùn àwọn èèyàn àwùjọ.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ní gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìdàlúrú náà ló máa fi ojú winá òfin.
Ó wà rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Osun láti kọ̀yìn sí ìwà jàgídíjàgan àtàwọn ìwà tó le da omi àlááfíà ìlú rú.
Bákan náà lọ ní kí àwọn èèyàn máa bá iṣẹ́ oòjọ́ wọn lọ bí àwọn ṣe ń gbìyànjú láti dá àláfíà padà sí ìlú náà.















