Ṣíṣe irun 'dreadlock', gbígbé ṣòkòtò sí bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí, lílo ìlẹ̀kẹ̀ ìdí àtàwọn ìmúra míràn tí ìjọba ìbílẹ̀ Owo sọ̀ di èèwọ̀ nínú òfin tuntun tó jáde

Aworan eeyan to ṣe irun igbalode dreadlock ati ilẹkẹ idi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O ti di eewọ bayii fun awọn ọdọkunrin lati maa ṣe irun dada atọwọda, bẹẹ lawọn obirin ko gbọdọ wọ ilẹkẹ idi mọ ni ijọba ibilẹ ilu Owo nipinlẹ Ondo.

Ofin yii atawọn ofin mii ni awọn alaṣe ijọba ibilẹ naa gbe kalẹ lẹyin ti eto abo ilu ọhun dojude latari ija ati if̣emiṣofo awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to waye nibẹ lẹnu ọjọ mẹta yii.

Alaga kansu ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni ijọba ibilẹ naa, Alagba Tope Omolayo, lo fi awọn ofin ọhun sita ninu atẹjade kan, eyii to tẹ akọroyin BBC Yoruba lọwọ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kini, ọdun 2025 yii ni eto idibo ijọba ibilẹ waye nipinlẹ Ondo, ninu eyii ti ijọba ibilẹ Owo wa ninu rẹ.

Oni, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji, ọdun 2025 ni gomina Lucky AIyedatiwa yoo ṣe iburawọle fun awọn alaga ijọba ibilẹ tuntun naa niluu Akure.

Alagba Tope Omolayo sọ fun BBC pe awọn yoo ṣe ilanilọyẹ fun awọn olugbe ilu Owo, bẹẹ lawọn yoo ri awọn patako ajuwe ti wọn yoo kọ awọn ofin tuntun naa si kaakiri ilu Owo ki wọn to ḅerẹ si n fi iya to tọ jẹ ẹnikẹni to ba tapa si i.

Awọn ofun tuntun mẹwaa ti ijọba ibilẹ Owo gbe kalẹ

  • O ti di eewọ fun awọn awakọ lati maa gba "one way" loju popo
  • Ẹnikẹni to ba n kiri ọja laarin igboro tabi ta ọja ni ẹgbẹ oju popo to yẹ ki awọn araalu maa gba yoo foju wina ofin
  • Araalu ko gbọdọ ja yẹpẹ, okuta tabi yanri si oju titi mọ
  • Ko si aye fun ipade awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun mọ niluu Owo, bẹẹ ni ikorajọpọ ti ko ba gba ontẹ ijọba ti lodi si ofin
  • Gbogbo ẹni to ba n sin ẹranko bii ewure, aja tabi ẹranko ile mii gbọdọ maa mu wọn so ni gbogbo igba
  • Ko si aye fun awọn ọdọ lati maa wọ aṣọ iwọkuwọ mọ bii aṣọ to ṣi ara silẹ, gbigbe ṣokoto si bẹbẹrẹ idi, ṣiṣe irun dada atọwọda, lilo ilẹkẹ idi atawọn imura mii ti ko bojumu
  • O ti di eewọ lati dede maa gbe ọkọ ẹni si ẹgbẹ titi tabi gbigbe ọkọ meji si ẹgbẹ ara wọn "double parking"
  • Ṣiṣe igbọnsẹ laarin igboro tabi ni ẹba ọna ti di eewọ
  • Dida idọti ile ẹni si ẹba ọna tabi agbegbe ti ijọba ko fi ọwọ si ti di eewọ
  • Ijọba ibilẹ Owo ti fofin de ariwo lati ọdọ awọn ile ijọsin ati mọṣalaṣi, awọn ile ijo tabi ile itura lasiko ti ijọba ko fi ọwọ si

Alagba Tope Omolayo pari atẹjade naa pe ẹnikẹni to ba tapa si awọn ofin naa, eyii ti ko yọ ẹnikẹni silẹ, yoo foju wina ofin.