Ààfáà Abdurahman, afurasí tí wọ́n bá òkú Yetunde nílé rẹ̀ n'Ilorin fojú balé ẹjọ́, dèrò ẹ̀wọ̀n

Aworan Abdurahman Bello ati Yetunde Lawal
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti gbe aafa Abdurahman Bello afurasi ti wọn ba oku akẹkọọbinrin Yetunde Lawal Hafsah nile rẹ niluu Ilorin lọ ile ẹjọ lọjọ Iṣẹgun ọjọ kejidinlogun oṣu Keji ọdun yii.

Abdurahman atawọn mẹrin mii ni wọn jọ foju ba ile ẹjọ lori ẹsun ipaniyan.

Igbẹjọ naa bẹrẹ ni nnkan bii ago mọkanla owurọ ọjọ Iṣẹgun ọjọ kejidinlogun oṣu yi ni ile ẹjọ majisireeti to dojukọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara.

Lasiko ti igbẹjọ naa bẹrẹ onidaajọ S.B. Muhammed ṣafihan awọn afurasi naa, ti o si tun kede ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Adajọ Muhammed sọ pe ọjọ kẹfa oṣu kẹta ọdun yii ni igbẹjọ yio bẹrẹ ni pẹrẹu, to si pasẹ pe ki wọn ko awọn afunrasi naa si ahamọ ọgba ẹwọn Okekura ni ilu Ilọrin.

Lasiko ton ba BBC yoruba sọrọ lọgba ile ẹjọ naa, aburo baba ọmọ ti wọn pa, Ọgbẹni Sikirulahi sọ pe awọn ọlọpaa fi idi rẹ mulẹ pe afunrasi naa Abdurahman mu awọn lọ agbegbe Oko Olowo ni Ilọrin ni ibi ti wọn ti ri ẹya ara bii itan ati ifun oloogbe naa.

O fikun ọrọ rẹ pe afurasi ọhun ko ti jẹwọ ibi ti o ta awọn ẹya ara to ku si.

Ọgbẹni Sikirulahi wa pe fun idajọ ododo lori ọrọ naa lati le pinnu iru iṣẹlẹ bayii lọjọ iwaju.

Ti ẹ o ba gbegbe, ọwọ awọn ọlọpaa tẹ Abdurahman Muhamadu Bello lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja lẹyin ti wọn ri oku Yetunde Lawal Hafsah ti wọn tti n wa nile rẹ ni Ilọrin.

Emir Ilorin gbarata lori iku Yetunde, o ni kawọn aafa wa iṣẹ sẹ

Aworan Abdurahman Bello ati Yetunde Lawal

Oríṣun àwòrán, Yetunde Lawal

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Emir iluu Ilorin, Alhaji Sulu Gambari ti pasẹ fun awọn Aafa Ilorin ati ilu mii ni ipinlẹ Kwara lati wa isẹ kan tabi omiran ṣe, ki wọn si mase jokoo ti isẹ Aafa gẹgẹ bii isẹ ounjẹ ojọ wọn.

Emir sọ eyi di mimọ latari bi ẹmi Yetunde Lawal ti iroyin gbe pe, o ti ọwọ afurasi kan ti o pe ara rẹ ni afaa, Abdulrahman Bello bọ.

Afaa yi ni a gbọ pe o kun ẹran ara obìnrin naa wẹlẹwẹlẹ ki ọwọ awọn ọlọpaa to tẹ ẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Emir ni Aafa le sisẹ olukọni ni ede Larubawa tabi imọ Islam ti a mọ si IRK, ni awọn ile ẹkọ.

O fi kun-un pe, iwa jibiti ni ki eniyan pe ara rẹ ni afaa lai ni isẹ kakan lapa.

Nigba ti Emir n ba BBC Yoruba sọrọ lonii nipasẹ agbẹnusọ rẹ, Abdulazeez Arowona, o ni oun ti gbe ikọ kan, ajọ Ulama dide lati maa lọ lati ojule de ojule, lati ilu de ilu, adugbo de adugbo ati agbegbe de agbegbe lati wu awọn afaa alapa ma sisẹ jade.

O wa gba awọn araalu niyanju lati sisẹ, wi pe, to ba jẹ ti Ọlọhun ni wọn gbe dani, ki wọn jisẹ, Ọlọhun, ki wọn jisẹ Anabi kan si se bi awọn ara ipinlẹ, awọn ẹni ana ṣe se.

Ẹyin ọdọ ẹ yago fun iwa janduku - Emir Ilorin

Ẹwẹ, Emir ilu Ilorin ti rọ awọn ọdọ pe ki wọn yago fun iwa janduku.

O wa koro oju si iwa afurasi Aafa Abdulrahman ti wọn fura si pe o pa Lawal, Alhaji Zulu Gambari ni ọdaju ati ọdaran eniyan ni ọdọmọkunrin naa.

Lẹyin eyi ni Emir Zulu Gambari pasẹ fun awọn aṣaaju ẹsin paapaa julọ awọn Imaamu ni Mọsalasi ni Ilorin ati ipinlẹ Kwara lapapọ lati rii daju pe, Khutbah wọn lọjọ Jimoh da lori pataki isẹ sise, ibu ọla ati ọwọ fun ọmọlakeji lai fi ti ẹya, ẹṣin tabi ti ipo se.

O rọ awọn afaa lati fọ isẹ naa mọ nipa ririi daju pe, asiri iru awọn eeyan bii Abdulrahman Bello ko bo si awọn agbofinro ko to di pe wọn yoo pa awọn alaisẹ jina.

O salaye pe isẹ takuntakun nikan lo se pataki, wi pe o yẹ ki wọn kede ogun ti ainisẹlọwọ, iwa ọlẹ ati fifẹsẹ ralẹ kiri awọn ọdọ.

Emir tun rọ ajọ ọlọpaa ati ile ẹjọ lati rii daju pe idajọ ododo waye lori ọrọ yii.

O ni o ti wa di baada bayi fun awọn obi ati alagbatọ lati maa tati kebi si isẹlẹ ni agbegbe wọn, ki wọn si rii daju pe awọn ti awọn ọmọ wọn n ba a rin jẹ awọn eniyan ti wọn mọ, tan si fọkan tan.