Èèyàn mẹ́fà ló kú lásìkò wàhálà tó wáyé láwọn ìjọba ìbílẹ̀ l'Osun lọ́jọ́ Ajé – Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti fidi rẹ mulẹ pe eeyan mẹfa lo padanu ẹmi wọn ninu rogbodiyan oṣelu to waye nibẹ lọjọ Aje.
Ninu atẹjade kan lọjọ Iṣẹgun, alukoro ileeṣẹ ọhun, Yemisi Opalola ba awọn to padanu ẹmi wọn atawọn ti dukia wọn ba iṣẹlẹ ọhun lọ kẹdun.
Opalola ni kọmiṣọna ọlọpaa, Mohammed Abba ti fi da awọn araalu loju pe iwadii ni kikun yoo waye lori ohun to ṣokunfa rogbodiyan naa.
O ṣalaye pe Abba fi idaniloju lede pe gbogbo awọn to lọwọ ninu idarudapọ naa ni yoo foju wina ofin.
Atẹjade ọhun sọ pe "nibi iṣẹlẹ to waye lana, eeyan mẹfa lo jade laye ti ọpọ si di ero ile iwosan.
"Iṣẹlẹ naa ba inu wa jẹ, a si ti ke si oniruru ẹlẹgbẹjẹgbẹ fun ipade. Kọmiṣọna ọlọpaa ti ṣe oniruru ipade lati ri daju pe irufẹ nnkan bẹẹ ko waye mọ.
"A ba gbogbo awọn ti ọrọ naa kan kẹdun, to fi mọ awọn to padanu ẹmi wọn atawọn to padanu dukia.
"Kọmiṣọna ọlọpaa ti ṣeleri pe iwadii ni kikun ni yoo waye, ti gbogbo awọn to si lọwọ ninu rogbodiyan naa yoo jẹ iya to tọ labẹ ofin."
Lasiko to n rọ araalu pe ki wọn ma fi ofin si ọwọ ara wọn, Opalola parọwa si awọn olugbe ipinlẹ Osun ki wọn ṣe suuru, ki wọn si fun awọn agbofinro laaye lati ṣiṣẹ wọn ki alaafia le jọba nipinlẹ naa.
Opalola fi kun pe "a rọ gbogbo awọn to n da wahala silẹ ki wọn jawọ nitori ipinlẹ alaafia ni a mọ ipinlẹ Osun si.
"A ko ni gba ẹnikẹni laaye lati da omi alaafia ipinlẹ wa ru. Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ti fi awọn ọlọpa kogbọregbe sọwọ si wa, wọn si ti de lalẹ ana.
"Gbogbo ohun to yẹ ni ileeṣẹ wa yoo ṣe lati ri daju pe alaafia pada jọba nipinlẹ Osun."
Rogbodiyan naa ko ṣẹyin ede aiyede to n waye laarin ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ipinlẹ naa, awọn ẹgbẹ oṣelu mejeji si ti n di ẹbi rogbodiyan ọhun le ara wọn lori.
Lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ni Remi Abbas, to jẹ alaga ijọba ibilẹ Irewole lẹyin ti wọn dibo yan an ninu oṣu Kini, ọdun 2018.














