Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Iwọ nikan, o gberun dada sori, o tun gbe ṣokoto si bẹbẹrẹ idi, o si lo n lọ si ilu Owo

Ẹhn ẹhn, bi n ba lọ silu Owo nkọ?

Ṣe iwọ o gbọ pe ijọba ibilẹ Owo ti kede awọn ofin tuntun mẹwaa ni?

Ofin wẹ̀?

Bẹẹ ni o, lara rẹ ni pe wọn o faaye gba ilẹkẹ idi, irun dada ati

Ati ki ni ki n ma lọ ṣẹ sofin?

Kan si oju opo bbcnews.com/yoruba lati ka wọn lẹkunrẹrẹ

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Lonii ni Oriyomi Hamzat ati Olori Silekunola tun foju ba ile ẹjọ

Lori ẹsun iku awọn ọmọde marundinlogoji to jade laye nibi apejẹ ọdun to waye nIbadan lọdun to kọja

Oni lo yẹ ki ile ẹjọ ka ẹsun awọn olujẹjọ naa siwọn leti

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Niṣe ni awọn ẹṣọ aabo duro wamuwamu si ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Osun

Lẹyin ti eeyan mẹfa padanu ẹmi wọn nibi wahala to bẹ silẹ ni ipinlẹ naa lọjọ Aje

Lasiko tawọn alaga kansu ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun da lare gbiyanju lati pada si ọfiisi

Amọ ti ijọba ipinlẹ naa ni ile ẹjọ ko ni ki wọn pada si kansu

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́