Ṣé lóòtọ́ ní amòfin àgbà Nàìjíríà ti pàṣẹ káwọn agbófinró dẹ́kun fífojú àwọn afurasí ọ̀daràn hàn?

Oríṣun àwòrán, Adejobi Olumuyiwa
Agbẹjọro agba fun orilẹede Naijiria, Lateef Fagbemi (SAN), ti paṣẹ pe o ti di eewọ fun awọn ọlọpaa lati maa fi oju awọn afurasi ọdaran lede.
Nigba ti awọn akọroyin kan si awọn ọga ọlọpaa lori ọrọ naa, wọn ni ọrọ ọhun ti to awọn leti.
Ọkan ninu awọn ọga ọlọpaa naa sọ fun akọroyin Punch pe "lootọ ni mo gbọ nipa aṣẹ tuntun naa, o jọ bii pe adajọ agba Naijiria lo paṣẹ ọhun, awọn ̣̣ọga wa si sọ fun wa, ẹ o ri pe a ko fi bẹẹ fi oju awọn afurasi lede mọ bii tẹlẹ."
Ẹlomiran to tun jẹ ọga ọlọpa niluu Abuja sọ pe "lootọ ni wọn ti sọ fun wa ki a dẹkun ati maa fi oju awọn afurasi lede fun awọn akọroyin."
Akitiyan BBC Yoruba lati kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Olumuyiwa Adejobi, lati da si ọrọ naa lo ja si pabo.
Amọ a gbọ pe Adejobi ti sọ ṣaaju pe ọọfisi oun yoo fi atẹjade lede lori aṣẹ tuntun naa laipẹ.
- Ṣíṣe irun 'dreadlock', gbígbé ṣòkòtò sí bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí, lílo ìlẹ̀kẹ̀ ìdí àtàwọn ìmúra míràn tí ìjọba ìbílẹ̀ Owo sọ̀ di èèwọ̀ nínú òfin tuntun tó jáde
- Àwọn ọ̀dọ́ jó àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n pa èèyàn kan sí àgọ́ wọn
- Ìjọba kéde ìgbà tí ìsọ̀rí àkọ́kọ́ ọmọ Nàìjíríà tí ìjọba Trump lé kúrò l'Ámẹ́ríkà yóò dé
Oju awọn ọdaran kekeke nikan ni ọlọpaa maa n fi lede – Falana
Nigba ti awọn akọroyin kan si agbẹjọro agba Femi Falana (SAN), lori ọrọ ọhun, Falana sọ pe o lodi si ofin ilẹ wa lati maa fi oju afurasi lede fun awọn akọroyin.
Falani ni "ko ba ofin mu lati maa fi oju afurasi lede fun awọn akọroyin nitori o jẹ iwa titẹ ẹtọ awọn afurasi bẹẹ loju mọlẹ nigba ti ile ẹjọ ko tii dajọ fun wọn gẹgẹ bo ṣe wa ninu abala kẹrindinlọgbọn ofin orilẹede Najiria ti ọdun 2004.
"Bakan naa, awọn ọdaran kekeke ti ko lẹnu lawujọ nikan ni awọn ọlọpaa atawọn agbofinro mii maa n fi oju wọn lede faraye.
"Nigba ti awọn ọlọpaa ba n fi oju awọn ọdaran to ji iṣu tabi ẹrọ ilewọ ti iye owo rẹ ko to ẹgbẹrun mẹwaa naira pere lede, wọn kii fi oju awọn oloṣelu to n ji owo ti iye rẹ to biliọnu mẹwaa naira lede."
Falana fi kun pe nnkan bii idajọ ile ẹjọ mẹwaa ọtọtọ lo ti fidi rẹ mulẹ pe ko ba ofin mu lati maa fi oju awọn afurasi lede fun araye ni Naijiria amọ awọn ọlọpaa n kọ eti ikun si awọn idajọ naa.
O ṣalaye siwaju si pe "awọn ọrọ to le ṣe akoba ti awọn afurasi maa n sọ nigba ti ọlọpaa ba fi oju wọn lede faraye gan ko ṣe itẹwọgba niwaju adajọ ile ẹjọ."
Agbẹjọro agba naa ni ọlọpaa kan n mọọmọ lo awọn ọrọ naa lati lo araalu lati ṣedajọ afurasi ni.
Falana pari ọrọ rẹ pe igba marun un ọtọtọ ni ile ẹjọ giga Naijiria ati ile ẹjọ ajọ ECOWAS ti sọ pe irufẹ iwa bẹẹ lodi si ofin.















