Àbọ̀ ìpàdé láàrin Amẹrika àti Russia lórí ọ̀nà láti dá ogun pẹ̀lú Ukraine dúró rèé

Oríṣun àwòrán, RUSSIAN FOREIGN MINISTRY / HANDOUT
Minisita ọrọ ilẹ okeere fun Russia, Sergei Lavrov, ti sọ pe ijọba Aarẹ Vlamidir Putin ko ni gba ikọ apẹtusija ajọ NATO laye lati wa si orilẹede Ukraine.
Lavrov sọrọ yii lẹyin ipade to waye laarin Russia ati orilẹede Amẹrika lorilẹede Saudi Arabia lori ati wa ojutuu si ogun to n lọ laarin Russia ati Ukraine.
Ṣaaju ni Russia ati Amẹrika ti buwọlu adehun lati jiroro lori dida ogun naa duro.
Akọwe ijọba Amẹrika fun ọrọ ilẹ okeere, Marco Rubio ni ipade yii jẹ igbesẹ akọkọ lori ati wa bi ogun to n lọ laarin Russia ati Ukraine yoo ṣe wa sopin.
Wọn o pe Ukraine sibi ipade ọhun eyi ti Aarẹ Volodymyr Zelensky sọ pe o jẹ iyanlẹnu.
Lavrov sọ pe ijororo laarin Russia ati Amẹrika lọ daadaa tori awọn gbọ ara awọn ni agbọye.
Ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe Russia ko le faramọ ki Ukraine darapọ mọ ajọ NATO laelae.
O ni eyi le ṣakoba fun orilẹede Russia ti eleyii ba fi ṣẹlẹ.
Rubio to jẹ akọwe ijọba Amẹrika lori ọrọ ilẹ okeere sọ pe oun ni igbagbọ wi pe Russia yoo bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati pari ogun naa.
O ni gbogbo igun tọrọ kan ni wọn ni ipa kan tabi omiran lati ko lori ati pari ogun naa.
Ṣaaju lọjọ Aje lawọn olori orilẹede ni Yuroopu ṣe ipade kan ni Paris lati jiroro lori ijororo ti yoo waye laarin Amẹrika ati Russia.
Ṣugbọn awọn naa ko fẹnu ko lori igbesẹ kankan ti wọn fẹ gbe lori ọrọ naa.
Amọ, Rubio sọ nibi ipade to waye ni Saudi Arabia wi pe awọn aṣohu ajọ EU naa maa wa nibi ipade ọhun tori ọrọ naa kan wọn bakan naa.















