Ẹ má wò mí níran, ìfúnpá mi ti wọ 157, nǹkan ti yí wọ́ fún mi – Òṣèré Tíátà Hamima Abubakar pariwo síta

Oríṣun àwòrán, Instagram/Halima Abubakar
Gbajumọ oṣere sinima lorilẹede Naijiria, Halima Abubakar ti pariwo sita fun iranwọ nipa awọn ilakaka rẹ lati ri jẹ-ri mu.
Ninu ipe kan to pe loju opo ayelujara rẹ,, gbajumọ oṣere naa ṣalaye ohun ti oju rẹ n ri lọwọ yii, ati wi pe oun ti pada si abule lati nnkan bii ọdun kan sẹyin nigba ti ẹkọ ko ṣoju mimu fun oun mọ.
Hamima Abubakar ni aye ko dẹrun fun oun rara lọwọ yii ati wi pe ara oun gan ko ya bayii. O wa n rọ awọn ẹlẹyinju aanu lati dide fun iranwọ oun.
"Ọpọ eeyan ni ọrọ mi ati nnkan to n ṣẹlẹ si mi n ru loju. Emi lẹ n wo yii o, ṣugbọn idandan ayelujara ti mo n lo pẹlu awọn aworan ti mo n fi si ori ayelujara nitori pe mi o fẹ ki awọn eeyan ri bi mo ṣe ri gangan., awọn eeyan kan wa n sọ pe mo n parọ ni. Ki ni maa wa maa pa irọ fun? Ṣe maa ma parọ pe mo dubulẹ aisan ni? Ileewosan to tobi jul lorilẹede Naijiria ni mo lọ."
O fi kun un pe awọn eeyan kan lo yọ ọwọ awo oun lawo lagbo ere sinima ni Naijiria. O ni sibẹ awọn kan ti oun gbaralẹ ṣi wa nidi hihu iwa ọdalẹ si oun.
O ni ọrẹ oun timọtimọ kọ lati yọju si oun, sibẹ ọrẹ oun naa lẹni to n lọ kaakiri lati sọ pe ko si nnkankan to ṣe oun ati wi pe ere sinima ṣise su oun ni.
Halima Abubakar ṣalaye siwaju sii pe gbogbo awọn to yẹ ko ba oun ṣere ni agbo awọn oṣere ni wọn ko da si oun mọ ti wọn ko si tilẹ ṣetan ati ran oun lọwọ rara.
"Mo lowo ri: ọkọ mi mẹtẹẹta ni mo ta, lai si ohun kan pato ti mo n ṣe."
O ni ifunpa oun ti wọ ẹtadinlọgọjọ bayii ti oun ko si le sọ ni pato oun ti oun n ro.
"O ti pe ọdun mẹfa bayii ti mo ti kopa ninu sinima kankan gbẹyin. Ki lo tun ku ti ẹ n wa? Ṣe ẹ fẹ ki n ku ni tabi ki n pa ara mi ni"















