Mìmì kan kò lè mi ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Osun tí yóò wáyé lọ́la - Adeleke

Aworan Gomina Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Osun State Government

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gomina Ademola Adeleke ti jẹ kọ di mimọ pe mimi kankan ko ni mi eto ijọba ibilẹ nipinlẹ Osun ti ajọ eleto idibo nipinlẹ naa OSIEC si ti bẹrẹ iṣẹ.

Gomina sọ eyi lasiko to n gba alejo ajọ to n ṣamojuto eto idibo ni ọfiisi rẹ lowurọ ọjọ Eti, ọjọ kọkanlelogun oṣu keji ọdun 2025.

Gẹgẹ bii Gomina Adeleke ti ṣalaye, awọn araalu ti wa ni digbi lati se ẹtọ wọn ki wọn si dibo fun eeyan ti wọn ba fẹ lati soju wọn ni ijọba ẹsẹkuuku.

" Mo ki yin kaabọ si ipinlẹ Osun. Awọn eeyan wa ti gbaradi fun eto idibo ọla. Wọn yoo yan eeyan ti wọn ba fẹ gẹgẹ bii alaga ati kanselọ.

"OSIEC ti se iṣẹ nla lati jẹ ki eto idibo yii rọrun gẹgẹ bii ohun to wa ni iwaju mi. Ọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu ni yoo kopa ni neto idibo yii, ti onikaluku si ni anfani to dọgba."

Lori rogbodiyan ẹtọ idibo, Gomina jẹ ko di mimọ pe ijọba awarawa lo fi n dari ilu, ti ko si si ẹni to le yi aṣẹ ile ẹjọ pada.

."Amọran mi fun awọn ẹgbẹ oṣelu ni pe ki wọn tẹle ofin ijọba awarawa. Fun emi ati awọn eeyan mi, a duro ti ijọba awarawa ."

"Eto idibo yoo waye, ti esi rẹ yoo si han si gbogbo wa. Mo rọ awọn araalu lati jẹ ki alaafia jọba nitori ipinlẹ alaafia ni ipinlẹ Osun."

Òòyẹ̀ kan kò lè yẹ ìdìbò àwọn alága àti káńsílọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ l'Ọsun - Alága

Aworan awọn oludibo to n wo orukọ wọn nibi ti wọn lẹ ẹ mọ.

Oríṣun àwòrán, Others

Pẹlu bi nnkan ko ṣe fi bẹẹ fararọ lẹka ijọba ibilẹ nipinlẹ Osun, Alaga fun eto idibo sijọba ibilẹ ibẹ, Hashim Abioye, ti ni ooyẹ kan ko ni i yẹ idibo wọn lọjọ Kejilelogun, oṣu Keji ọdun 2025 yii.

Hashim sọrọ naa fun BBC nigba ti a kan si i lati beere boya idibo naa yoo waye pẹlu bi aibalẹ ọkan ṣe gba ọkan awọn eeyan.

Alaga eto idibo ijọba ibilẹ l'Osun naa sọ pe ko si giri, nitori gbogbo eto lo ti to pata fun idibo ọhun.

O ni idajọ ile ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun ko da idibo ijọba ibilẹ duro, afi ki idibo waye dandan.

Nigba to n sọrọ lori aabo, Hashim ṣalaye pe awọn ti ṣepade pẹlu awọn ẹsọ alaabo pata, wọn si ti ṣetan lati fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn lati ri i daju pe aabo wa fun ẹmi ati dukia awọn olugbe ipinlẹ Osun ṣaaju ati lẹyin idibo.

Alàga PDP Osun naa sọ̀rọ̀

Lori idibo ti wọn ni yoo waye yii, Sunday Bisi, Alaga PDP ipinlẹ Osun naa sọ pe ko si kinni kan ti yoo da ibo didi duro lọjọ kejilelogun, oṣu Keji yii.

Alaga PDP Osun ṣalaye pe gbogbo bi APC ṣe n gbiyanju lati lo awọn ọlọpaa lati tako ilana ti ajọ eleto idibo ijọba ibilẹ la kalẹ, ti gbogbo ẹ yoo fi da oju ru ni awọn ti mọ.

Sunday Bisi sọ pe ilẹdi apo-pọ ọga ọlọpaa pata ni Naijiria, Kayode Egbetokun pẹlu APC lati pa Gomina Ademola Adeleke ni awọn ti mọ bakan naa.

O rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ oselu PDP l'Osun pe ki wọn maa fi oju ṣọri bii alakan, ki wọn si maa fura.

'APC kò ní í kópa nínú ìbò yìí'

Ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun, Jamiu Olawumi, ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu APC ko ni i kopa ninu idibo ijọba ibilẹ n to bọ yii.

Olawumi sọ pe bi ọba kan ko ba ti i ku, ko yẹ ki omiran jẹ.

O tẹsiwaju pe nigba ti awọn alaga ti ile ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun da lare ti pada si ọfiisi koowa wọn, ko tun si idi kan lati kopa ninu idibo mọ.

Kí ni ìjọba Osun sọ?

Aworan Gomina Osun;Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/ X

Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Osun, Kolapo Alimi, ṣalaye fun BBC pe ohun ti Ile ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun sọ ko ye awọn ẹgbẹ oselu alatako.

O ni Ile ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun ko sọ pe kawọn alaga ijọba ibilẹ ti Ile ẹjọ giga fi ọwọ osi juwe ile fun pada si ofiisi wọn.

Kọmiṣanna eto iroyin Osun fi kun un pe awọn ko ni ile ẹjọ kankan ti awọn tun fẹ lọ mọ lori ọrọ yii.

O ni awọn ti mura silẹ fun idibo ijọba ibilẹ n to bọ lọjọ kejilelogun, oṣu Keji ọdun 2025.

Kolapo Alimi waa rọ awọn olugbe Osun lati ma ṣe feti si ohun ti ẹgbẹ oselu APC n sọ kiri.

O ni ki gbogbo wọn jade sita dibo lọjọ ibo ijọba ibilẹ.

Àlàyé ọlọ́pàá

Yemisi Opalola, agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ bawọn ṣe n gbọ pe ọlọpaa ti gbabode fun ẹgbẹ oṣelu kan.

O ni irọ to jinna si ootọ ni iroyin naa.

Opalola sọ pe awọn ọlọpaa ti gbaradi fun eto idibo ijọba ibilẹ to n bọ yii, awọn si ti ṣepade pẹlu ajọ eleto idibo ijọba ibilẹ ati awọn akẹgbẹ awọn yooku.

Alukoro ọlọpaa Osun waa fi gbogbo olugbe ipinlẹ naa lọkan balẹ nipa eto aabo, o ni ṣaaju, lasiko ibo ati lẹyin rẹ ni aabo wọn ko ni i yingin.