Àlàyé ohun tójú Portable rí fún wákátí mẹ́rin kó tó rí béèlì gbà, àti ẹni tó ṣe onídúró fún un rèé

Aworan Portable lori ikunlẹ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Pupọ awọn ti wọn ri Habeeb Okikiola Badmus ti ọpọ mọ si Portable nile ẹjọ Majisireeti tiluu Abẹokuta ni deedee agogo mẹrin irọlẹ kọja ni wọn ti lero wi pe yoo sun ọgba ẹwọn mọju ọjọ keji.

Idi ni pe wọn ti lero wi pe lẹyin agogo mẹrin irọlẹ ti wọn maa n tilẹkun ile ẹjọ, ko tun si ohun miran to tun le ṣẹlẹ mọ.

Nnkan bi agogo mejila ku iṣẹju marundinlọgbọn aarọ ni ile ẹjọ paṣẹ pe ki wọn gba beeli beeli Portable pẹlu oniduro kan to n gbe nipinlẹ Ogun.

Portable

Oríṣun àwòrán, instagram/portablebaeby

Kete ti Onidajọ O. L. Oke ti paṣẹ, lo ti fi ile ẹjọ naa silẹ lọ sile iṣẹ eto idajọ to wa ni Oke Mosan.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ẹni to n pin iwe ẹjọ ni kootu, iyẹn Bailif ti fi aworan iyawo Portable ranṣẹ si adajọ gẹgẹ bi oniduro rẹ.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ Majisireeti naa to ba BBC sọrọ, sọ pe bi wọn ṣe fi aworan naa ranṣẹ ni ko tẹ adajọ lọrun, to fi paṣẹ pe ki wọn lọ sile rẹ lati gba gbogbo iwe to yẹ.

Oṣiṣẹ ile ẹjọ Majisireeti naa ṣalaye pe adajọ kan an nipa wi pe wọn gbọdọ ya aworan ati fọnran oniduro naa soun ni kete ti wọn ba ti debẹ fun aridaju.

Ta ni Oniduro to duro fun beeli Portable níléẹjọ?

Aworan Portable.

Nnkan bii agogo kan fẹẹ lọ lu ni awọn to lọ naa ṣẹṣẹ gbera kuro niluu Abẹokuta lati lọ ba oniduro ọhun ni Sango, ti wọn si debẹ ni nnkan bi agogo mẹrin ku bii iṣẹju marundinlọgbọn.

Lati ibẹ ni wọn ti tẹle aṣẹ adajọ, ti wọn si fi awọn aworan ati fọnran naa ranṣẹ, ko to di pe wọn lọ tẹ ẹ jade.

Oniduro naa to jẹ iyawo Portable buwọ lu awọn iwe to yẹ gẹgẹ bi oniduro, ko to di pe oun naa gbera wa siluu Abẹokuta lati pade ọkọ rẹ nile ẹjọ.

"Agogo mẹrin ni wọn maa n tilẹkun ile ẹjọ labẹ ofin, ṣugbọn niṣe lo dabi ẹni pe wọn fẹẹ foju aanu wo Portable lati ma ṣe sun ọgba ẹwọn mọju ọjọ keji," oṣiṣẹ naa sọ fun BBC.

"Bi wọn ko ba ti i ri beeli olujẹjọ gba ki agogo mẹrin irọlẹ too lu, o di dandan ki wọn gbe e lọ si ọgba ẹwọn titi ọjọ keji, tabi titi digba ti wọn yoo fi pari gbogbo eto beeli naa."

Bi gbogbo eto beeli naa ṣe pari ni nnkan bi agogo mẹrin kọja iṣẹju mejidinlọgbọn, ni wọn mu Portable jade sita kootu, to si lọ dupẹ lọwọ adajọ to buwọ lu iwe beeli naa fun un, to si ṣeleri pe oun yoo di ẹda tuntun.