Wo ibi tí ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ tí Falana pe VDM dé dúró

Falana

Oríṣun àwòrán, FAlana/VDM/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile ẹjọ giga kan to wa ni Ikeja, niluu Eko, ti sun igbẹjọ ẹsun ibanilorukọjẹ ti agbẹjọro agba, Femi Falana, fi kan gbajumọ ori ayelujara, Martins Otse ti ọpọ mọ si Very Dark Man (VDM), si ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2025.

Adajọ Matthias Dawodu sun igbẹjọ ọhun siwaju lẹyin to gba lẹta lati ọwọ agbẹjọro VDM, Deji Adeyanju.

Lẹta naa rọ ile ẹjọ ọhun lati sun igbẹjọ naa siwaju si oṣu Kẹta tabi oṣu Kẹrin latari pe olori ikọ olujẹjọ, Marvin Omorogbe, ko ni le ri aye lati yọju sile ẹjọ fun awọn idi kan.

Bo tilẹ jẹ pe VDM ko si nilẹ ẹjọ naa, Femi Falana wa nibẹ.

Agbẹjọro ẹbi Falana, Omotayo Olatunbosun, sọ fun adajọ pe ikọ olujẹjọ kọ lẹta naa lọna ati mọọmọ fi akoko ṣofo ati lati maa wọ igbẹjọ naa nilẹ.

Olatunbosun tun sọrọ tako ẹbẹ VDM pe ko da ẹjọ ọhun nu.

Lẹyin eyii ni adajọ Dawodu sun igbẹjọ naa si ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 ti a wa yii.

Igbẹjọ to n waye laarin VDM ati agba amofin naa ko ṣẹyin fidio kan ti VDM ṣe lọdun to kọja, nibi to fi fi ohun Bobsrisky sita.

Ninu ohun ipe ti wọn ka silẹ naa ni Bobrisky ti sọ pe agbẹjọro Falana ti n ran oun lọwọ ki oun le jade kuro lọgba ẹwọn ati lati pe iwe ẹsun oun rẹ ni ọọfisi Aarẹ.

Bobrisky tun sọ ninu fidio naa pe oun ko fi akoko kankan sun lọgba ẹwọn, bi ko ṣe ninu ile kan ti wọn gba fun oun.

Lẹyin naa ni ẹbi Falana fi ẹsun ibanilorukọjẹ kan VDM.

Amọ ṣa, VDM ti sọ pe Bobrisky lo yẹ ki mọlẹbi naa pe lẹjọ, kii ṣe oun, ati pe oun ko jẹbi ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan oun.