Ẹ gbọ́dọ̀ kéde ohun ìní yín títí ìparí oṣù Kẹ́ta tàbí kí ẹ jìyà, Ààrẹ Mahama sáwọn tó yàn sípò

Aworan Aarẹ John Mahama

Oríṣun àwòrán, Ghana Presidency/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ John Mahama orilẹede Ghana ti fawọn to yan sipo di ipari oṣu Kẹta lati kede ohun ini wọn, bi bẹẹ kọọ, wọn o ri iya he.

Aarẹ Mahama sọrọ yii lẹyin to fi iwe to fi kede ohun ini rẹ ṣọwọ si ayẹwe owo wo agba orilẹede naa lọjọ kejidinlogun oṣu Keji yii.

Ofin orilẹede Ghana la a kalẹ pe ẹnikẹni to ba fẹ di ipo ijọba kan tabi omiran mu gbọdọ kede ohun ini wọn, dukia wọn ati gbese ti wọn ba jẹ ki wọn to le di ipo kankan mu.

Aarẹ Mahama ni oun ti fi fọọmu ohun ini ṣowọ si ayẹwe owo wo agba lorilẹede Ghana ni ikọkọ ri, amọ, oun pinnu lati fi fọọmu naa ṣọwọ si ayẹwe owo wo agba loju gbogbo eeyan lọtẹ yii ki gbogbo eeyan le ri i.

Aarẹ ni ohun toun mọ ni pe ijọba ko gbọdọ gbawọn eeayn laye lati huwa ibajẹ, o ni kii ṣe igba ti wọn ba huwa ibajẹ naa tanlo yẹ ki ijọba gbe igbesẹ.

Lootọ ni ofin ni ki ẹnikẹni to ba fẹ gba ipo kan tabi ominran lọdọ ijọba kede ohun ini wọn, amọ, ofin ko sọ pe ki ayẹwe owo wo agba ṣi iwe ti wọn kọ ohun ini wọn si yii.

Igba ti nnkan ba ṣẹlẹ si ẹni ti ijọba ba yan si po ni ayẹwe owo wo agba yoo ṣi iwe ohun oni ti iru eeyan bẹẹ ba kede fun iwadii.

Eyi lo jẹ ki awọn onwoye kan sọ pe bi ijọba ṣe mu ọrọ kikede ohun ini to ba fẹ di ipo mu ninu ṣiṣe ijọba kudiẹ kaato.

Nitori pe ayẹwe owo wo agba ko ni tu iwe ohun ini naa wo lati le mọ nnkan to wa nibẹ, ọpọ lo le maa sọ gbogbo nnkan ti wọn ni tan sinu iwe naa.

Idi niyii ti ẹgbẹ kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni ''Ghana Integrity Initiative'' fi n sọ pe kawọn oloṣelu kan ma maa fi iwe lasan ṣọwọ si ayẹwe owo wo agba nikan.

Ẹgbẹ naa sọ pe ki ẹnikẹni to ba ti fẹ dupo mu ninu ṣiṣe ijọba maa ka gbogbo nnkan ti wọn ba ni ki wọn to bẹrẹ iṣẹ ni ipo kipo ti wọn ba wa.

Ẹgbẹ naa ni eleyii yoo ṣe iranwọ lati gbogun ti iwa ibajẹ tori ko ni fawọn eeyan to fẹ fi owo ijọba ko dukia jọ lanfani lati ṣe bẹẹ.