Primeboy ń béèrè N50m lọ́wọ́ ìyá Mohbad, ó ní ó ba òun lórúkọ jẹ́

Prime Boy, Oloogbe Mohbad ati Iya Mohbad

Oríṣun àwòrán, Prime Boy@Instagram, Mohbad@Instagram, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Owo ti ko din ni miliọnu lọna aadọta naira (50m) ni Owodunni Ibrahim; Prime Boy ti i ṣe ọrẹ Oloogbe Mohbad n beere lọwọ iya olorin naa bayii, fun ẹsun ibanilorukọjẹ.

Tẹ o ba gbagbe, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 ni Prime Boy toun naa n kọrin, fi ẹsun kan Iya Mohbad, Abosede Adeyemo Aloba, pe o ba oun lorukọ jẹ nigba to ṣe ifọrọwerọ kan lori iku Mohbad.

Prime Boy sọ nigba naa pe Iya Mohbad kede pe oun ati Oloogbe ni aawọ kan tawọn n fa nigba ti Mohbad wa laye.

O ni Iya Mohbad sọ pe oun maa n ba Oloogbe ja pe ko tọju oun.

Bakan naa lo ni Iya Mohbad sọ pe awọn kan gba oun nimọran lati tete sa lọ lẹyin iku Mohbad, ki wọn ma baa fura soun nipa iku naa.

O ni ọrọ naa ko idọti ba orukọ oun, o si ba oun jẹ loju awọn eeyan to fẹran oun gẹgẹ bi olorin.

Prime Boy ṣalaye pe Iya Mohbad mọ-ọn-mọ sọ ọrọ naa lati fi ba oun jẹ ni.

Awọn ọrọ naa lo ni ki Iya Mohbad ṣe atunṣe lori rẹ, ko loun ko sọ bẹẹ mọ laaarin ọjọ meje tabi ko ṣetan lati foju wina ofin.

Ọrọ ọhun ni Primeboy ti waa sọ di nnkan bayii pẹlu bo ṣe n beere miliọnu lọna aadọta naira lọwọ iya ọrẹ rẹ.

Loju opo Instagram rẹ, Prime Boy tun kede l'Ọjọruu, ọjọ kọkandinlogun oṣu Keji ọdun 2025 yii, pe oun n wọ Iya Mohbad lọ sile ẹjọ.

Ninu ẹda iwe to fi kede naa lo ti ni miliọnu lọna adọta naira lo n run lori Iya Mohbad lati san foun fun ọrọ ibanilorukọjẹ to sọ nipa oun ninu fido kan lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2024.

Iwe naa sọ pe laaarin ọjọ mejilelogoji, Iya Mohbad gbọdọ ṣe ohun to tọ.

O ni boya obinrin naa wa si kootu tabi ko wa, idajọ yoo waye lẹyin rẹ bọjọ ba pe.

Tẹ o ba gbagbe, Ileri Oluwa Aloba (Mohbad), jade laye lọjọ Kejila, oṣu Kẹsan-an ọdun 2023, latigba naa ni gbuuru si ti n fa igbo lori iku ọhun.

Ara ko rọ okun, ko rọ adiẹ lati ori awọn obi ọmọ naa, iyawo rẹ, Wumi, aburo rẹ;Adura ati Prime Boy, ọrẹ rẹ.

Wọn ko si ti i sin oku naa titi dasiko yii.

Ẹda iwe ti Prime Boy fi n beere aadọta miliọnu lọwọ Iya Mohbad

Oríṣun àwòrán, Prime Boy/ Instagram