Ọmọ ẹ̀yìn Portable mẹ́sàn-án fojú ba iléẹjọ́ fún lílu òṣìṣẹ́ ìjọba, 'Wèrè olórin' na pápá bora

Oríṣun àwòrán, @Portablebaeby
Portable ọmọ Olalomi torukọ rẹ n gan-an n jẹ Habeeb Okikiola tun ti lẹjọ lati jẹ pẹlu ijọba Ogun bayii, lẹyin ẹsun pe oun ati awọn ọmọ ẹyin rẹ fiya jẹ awọn oṣiṣẹ ijọba kan to n ṣiṣẹ wọn.
Awọn oṣiṣẹ ijọba lati ileeṣẹ to n ri si aato ilu lati Ota, (Ota Zonal Planning Office) ni a gbọ pe Portable ati awọn ọmọ ẹyin rẹ kọju ija si l'Ọjọruu, ọjọ karun-un, oṣu Keji ọdun 2025 yii.
Awọn nnkan ija to le ṣe eeyan ni ṣùtá bii ada, ibọn, igo ni a gbọ pe Portable ati awọn eeyan rẹ fi koju awọn oṣiṣẹ ijọba ọhun, nigba ti wọn n gbiyanju lati ti ile ọti ati ọtẹẹli Were olorin ti wọn ni o kọ sibi ti ko tọ pa.
Ikọlu naa lo pada di rogbodiyan, ti awọn oṣiṣẹ ijọba n sa kijokijo kiri ki wọn too ranṣẹ fun iranlọwọ lati ọfiisi wọn.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Portable jẹ́jọ́ ní kóòtù, Wèrè olórin na pápá bora

Oríṣun àwòrán, Instagram Portable Omo Olalomi_1
Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe wi, wọn ni nigba ti iranlọwọ de fun awọn oṣiṣẹ eleto ilu ni wọn ko mẹsan-an ninu awọn ọmọ ẹyin Portable lọ.
Ọjọ keji iṣẹlẹ naa ti i ṣe Ọjọbọ ni wọn si fi oju wọn bale ẹjọ, ṣugbọn Portable funra rẹ ti na papa bora.
Sunday Ekong, ọlọpaa to ṣoju ijọba ninu ẹjọ naa to waye nile ẹjọ majisireeti kan l'Abeokuta, ka orukọ awọn tọwọ ba naa bayii:
Nurudeen Warris, Adetola Alashe, Samuel Adeleke, Oluwaseun Ayenuwa, Oluwapelumi Adeosun, Gospel Kanu, Precious Ohiegebo, Ifeoluwa Babatunde ati Fatimo Muhammed.
Ẹsun marun-un ni wọn fi kan wọn:
Aṣoju ijọba ṣalaye pe Ọjọruu ni Portable ati awọn ọmọọṣẹ rẹ huwa to le da omi alaafia ilu ru.
O ni aago mẹwaa owurọ ni lọjọ naa, laduugbo Oke-Osa, Tigbo Ilu, Sango-Ota, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ota, ipinlẹ Ogun.
Ekong sọ pe awọn to n jẹjọ naa pẹlu Portable funra ẹ ni wọn jọ fiya jẹ Abidemi Onabanjo, Ramon Lateef, ati Akinpelumi Oyero ti wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba lati ileeṣẹ to n ri si aato ilu.
O ni Portable ati awọn ọmọ ẹyin rẹ fẹẹ pa awọn oṣiṣẹ ijọba naa ni, pẹlu bi wọn ṣe kojuu wọn ti wọn si tun di wọn lọwọ iṣẹ wọn.
Eyi tako abala 516, 356(3), 80, 249(d), ati 320 ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ogun ti wọn ṣe ni 2006.
Nigba ti wọn n da kootu lohun, awọn olujẹjọ ni awọn ko jẹbi.
Adajọ Abielekọ O.M. Somefun, fi aaye beeli silẹ fun awọn olujẹjọ pẹlu miliọnu marun-in naira ati oniduuro meji ti wọn ni akọsilẹ lọdọ ijọba Ogun.
O sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, 2025.
Kí ni Portable wí?
Bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ ni Ọmọ Olalomi gba oju opo Instagram rẹ lọ to si kọ ọrọ sibẹ pe ohun to ṣẹlẹ naa ya oun lẹnu gan-an.
"Ki lo de ti wọn fi maa ṣe bẹẹ yẹn si dukia mi ti mo fi n bọ idile mi?
"Gbogbo eeyan ni wọn ko, o ju ogun eeyan lọ ti wọn ko lọ, ati awọn to n ṣere ati awọn onibaara mi. Wọn tun ko mọto onimọto pẹlu ọkada ati foonu wọn lọ. Ki lo de?
" K'ijọba jọọ da si ọrọ yii. Mo n lo ibi yii lati fi gba ode ere ati ayẹyẹ ni, ki i ṣe ohun mimu nikan ni mo n ta nibẹ. Mo n gbe awọn eeyan saye mo dẹ n ran adugbo lọwọ ni.
" Ki lo de ti wọn n doju ija kọ mi, paapaa latigba ti mo ti n fa ina sojuu popo ti mo dẹ n tun ọna to bajẹ ṣe. Ọlọrun ju wọn lọ."
Bẹẹ ni Portable Ọmọ Olalomi kọ ọ si oju opo Instagram rẹ
Kí ni ọlọ́pàá wí?
Igbiyanju wa lati ba Alukoro ọlọpaa Ogun, CSP Omolola Odutola, sọrọ ko kẹsẹ jari.
Odutola sọ pe oun ko gbe ọro kankan jade nipa Portable.
O ni oun wa ni ipade lọwọ, oun ko le fesi lasiko naa.
Tẹ o ba gbagbe, eyi kọ ni igba akọkọ ti Idaamu adugbo, bawọn mi-in ṣe tun maa n pe e yoo jẹjọ nipinlẹ Ogun.
Portable foju bale ẹjọ Majisreeti ilu Ifọ lọdun 2023, lori ẹsun pe o fiya jẹ awọn ọlọpaa kan nile ọti rẹ yii kan naa, ti ọkan ninu wọn si farapa.
Ẹsun ti wọn fi kan an nigba naa ju mẹfa ọtọọtọ lọ.













