Ìbẹ̀rùbojo gbọkàn àwọn ọmọ Africa bí Trump ṣe ń lé ọ̀pọ̀ àjèjì kúrò ní Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, US Immigration and Customs Enforcement
- Author, Yusuf Akinpelu
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Níṣe ni ìbẹ̀rùbòjò pé kí wọ́n má gbé wọn tàbí dá wọn padà sílé gba ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Africa tó ń gbé ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà báyìí, èyí tó ń mú kí ọ̀pọ̀ wọn máa sá kíjokíjo kiri.
Àwọn ọmọ Africa tó ń gbé ní US sọ fún BBC pé àwọn kò ti sábà máa jáde mọ́, lọ sí ibiṣẹ́ dédé àti pé àwọn ti mú àdínkù bá báwọn ṣe ń yọjú sí ìgbooro.
Àwọn mìíràn sọ pé àwọn kò jẹ́ káwọn ọmọ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù pé káwọn òṣìṣẹ́ tó ń rí sí ìwọlé jáde ní orílẹ̀ èdè náà ìyẹn Immigration and Customs Enforcement (ICE) má ba à fi òfin gbé wọn.
Ọ̀kan lára àwọn èèyàn yìí ni Kaduli tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Congo tó ti wà ní Amẹ́ríkà láti ọdún mọ́kànlá sẹ́yìn.
Ní ìlú Bukavu, ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo, táwọn M23 ṣẹ̀ṣẹ̀ gba àkóso rẹ̀, ni wọ́n bi Kaduli sí.
Onímọ̀ nípa ìṣègùn òyìnbó ni Kaduli kó tó sá kúrò ní DR Congo láti bọ́ lọ́wọ́ fífi òfin gbé e lẹ́yìn tó bu ẹnu àtẹ́ lu ààrẹ tẹ́lẹ̀ ní DR Congo, Joseph Kabila lórí bó ṣe mú àyípadà bá ìwé òfin orílẹ̀ èdè náà láti fi ọjọ́ kún sáà rẹ̀ lórí ipò.
Kaduli sọ fún BBC pé òun ti dín ìrìn òun kù ní US, tó fi mọ́ lílọ sí ilé oúnjẹ àtàwọn ilé ìtajà nítorí ìbẹ̀rù pé kí wọ́n fi tipátipá lé òun padà sí orílẹ̀ èdè òun.
"bí wọ́n ṣe ń ṣa àwọn èèyàn káàkiri ń dá ìbẹ̀rùbojo sí wa lára nítorí gbogbo àwọn tí kìí ṣe ọmọ ìlú ni wọ́n ń fi ojú ọ̀daràn wò.
"Ẹ̀rù ń bà mí nítorí ogun ṣì ń tẹ̀síwájú ní Congo, ìwà títẹ̀ ẹ̀ta àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀ ṣì wà ní Congo. Dídá èèyàn padà sí Congo dàbí fífi ẹni náà sẹ́nu ikú."
Bíi ti Kaduli, Abdul láti Nàìjíríà náà ni ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀.
Nígbà tí Abdul wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá ló tẹ̀lé bàbá rẹ̀ lọ sí Amẹ́ríkà ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn.
"Mò ń gbìyànjú láti ri pé mi ò fi ara mi sínú ewu, tí mo sì ní ìgbàgbọ́ nínú Allah pé gbogbo rẹ̀ máa yanjú," Abdul tó ń gbé ní Wiscnsin sọ.
Ó ní òun ti gbọ́, tí òun sì ti rí báwọn ṣe ń ṣiṣẹ́ láwọn ìlú mìíràn. Ó ní òun ń bẹ̀rù pé kí irúfẹ́ bẹ́ẹ̀ má ṣẹlẹ̀ sí òun.
"Bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn èèyàn kò da rárá, bí ẹni wí pé wọn kìí ṣe èèyàn. Ẹlẹ́ran ara ni gbogbo wa, ẹ̀jẹ̀ kan náà ló ń ṣàn lára wa," ó sọ.
Gbogbo àwọn tí a bá sọ̀rọ̀ ni kò fẹ́ dárúkọ wọn ní kíkún fún wa nítorí ìbẹ̀rù àwọn aláṣẹ.
Lílé ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò ní Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Láti ìgbà tí Donald Trump ti gbàkóso ìjọba Amẹ́ríkà padà nínú oṣù Kìíní ló ti bẹ̀rẹ̀ ètò lílé àwọn èèyàn tí kìí ṣe ọmọ Amẹ́ríkà kúrò ní ìlú, tí wọ́n sì ti ń kó àwọn èèyàn káàkiri.
Trump pa iléeṣẹ́ ológun láṣẹ láti gbé agbára wọn àwọn òṣìṣẹ́ immigration láti lè máa fi òfin gbé àwọn èèyàn tó fi mọ́ nílé ẹ̀kọ́, ilé ìjọsìn àti ilé ìwòsàn.
Ọ̀pọ̀ àwọn àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ló ti bui ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ yìí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tó fi mọ́ àwọn tí wọ́n ti ní àkọ́ọ́lẹ̀ ìwà ọ̀daràn àtàwọn tí kò ní ni wọ́n ti fi sí àhámọ́ báyìí.
Ní àfiwé, ìṣèjọba Joe Biden máa ń lé àwọn èèyàn pàápàá àwọn ọ̀daran tí iye wọn tó 311 kúrò ní Amẹ́ríkà lọ́jọ́ kan gẹ́gẹ́ bí ICE ṣe sọ.
Trump tún gbèrò láti gbé òfin Alien Enemies Act kalẹ̀, èyí tó máa fún wọn láṣẹ láti tètè lé àwọn àjòjì tí wọ́n bá fúra pé wọ́n pa ìlú lára kúrò ní kíákíá – àsìkò ogun ni wọ́n lo òfin yìí rí.
Káhúnsílọ̀ kan ní ìlú Portland ní ìpínlẹ̀ Maine, Pious Ali sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe ohun tuntun láti lé àwọn èèyàn kúrò ní orílẹ̀ èdè, ó ní ìgbésẹ̀ lílọ sí àwọn ilé ẹ̀kọ́, ilé ìjọsìn láti lọ máa ṣa àwọn èèyàn bíi ọ̀daràn kò bá òfin mu rárá.
Ali sọ fún àwọn tó wà nínú ìbẹ̀rù láti kọ àkọ́ọ́lẹ̀ fáwọn ẹbí wọn, kí wọ́n sì ri pé wọ́n fi owọ àti oúnjẹ sí ìpamọ́.
Ààbò 'Temporary Protected Status'

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Africa tó wà ní Amẹ́ríkà ni wọn kò mọ nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí àìmọ nǹkan tó yóò ṣẹlẹ̀ síwọn lábẹ́ ètò ààbò fídí ẹ Temporary Protected Status tó wà fún wọn.
Ètò yìí ló wà fún àwọn èèyàn tí làlúrí bíi ogun, ìjàmbá kan tàbí òmíràn ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè tí wọ́n sì wà bí Amẹ́ríkà fún ààbò, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.
Sylvie Bello, adarí àjọ Cameroon American Council (CAC), àjọ tó fi ìkalẹ̀ sí Washington DC, tó máa ń pè fún fífi àyè gba àwọn tó bá ṣe ìrìnàjò sí Amẹ́ríkà, ní nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ yìí wáyé látàrí àwọn ètò tó wáyé lábẹ́ ìṣèjọba Biden.
Ó ní àwọn ti gbèrò pé Biden máa mú àlékún bá ètò TPS fún Angola àti DR Congo nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí àjọ náà nínú oṣù Kọkànlá ọdún tó kọjá.
Bello ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Africa tí kò rí àlékún ọjọ́ ló ṣeéṣe kí wọ́n dá padà sí orílẹ̀ èdè wọn báyìí lábẹ́ ìṣèjọba Trump.
Àwọn èèyàn tí iye wọn fẹ́ ẹ̀ tó mílíọ̀nù kan láti orílẹ̀ èdè mẹ́tàdínlógún tí márùn-ún níbẹ̀ jẹ́ Africa ni ètò TPS ń dá ààbò bò. Ọdún yìí ni ètò TPS fáwọn èèyàn láti Cameroon, Ethiopia àti South Sudan máa parí nígbà tí táwọn èèyàn láti Somalia àti Sudan máa parí lọ́dún 2026.
"Gbogbo àwọn èèyàn mi ni wọ́n wà nínú ìbẹ̀rù pé wọ́n máa lé àwọn padà sí orílẹ̀ èdè wọn," Sylvie Bello sọ.
Gbígbé nínú ìbẹ̀rù
Láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, míṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Africa ń ṣe ìrìnàjò lọ sí Amẹ́ríkà nípa gbígba South America àti Mexico. Nneka Achapu, onímọ̀ nípa ètò Amẹ́ríkà àti Africa tó fi Texas ṣe ibùgbé sọ pé èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí gbígba ọ̀nà orí omi Mediterranean lọ sí Europe jẹ́ ohun tó léwu púpọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìjábọ̀ ICE fún ọdún 2024, ọmọ Africa tí iye wọn tó 1,818 ni wọ́n lé kúrò ní US lọ́dún 2024, ọmọ Senegal, Mauritania àti Nàìjíríà ló pọ̀ jù nínú wọn.
Ìdá mẹ́ta ni àwọn ọmọ Africa tó wà nínú èèyàn 1.4m tí wọ́n fẹ́ lé kúrò ní orílẹ̀ èdè náà bí ICE ṣe sọ nínú oṣù Kókànlá ọdún 2024.
Àwọn ọmọ Somalia ló pọ̀ jùlọ níbẹ̀ pẹ̀lú èèyàn 4,090, Mauritania ní èèyàn 3,822, àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà níbẹ̀ jẹ́ 3,690 nígbà tí Ghana sì ní 3,228.
Mímọ̀ pé òfin ti wà láti lé àwọn èèyàn yìí kúrò ní Amẹ́ríkà ń lékú ìbẹ̀rù táwọn ọmọ Africa ń kojú.
Abdul wòye pé ọdún mẹ́rin ni àwọn fi máa lẹ́nu rẹ̀ báyìí.
Nneka Achapu ní pẹ̀lú ìkọlù táwọn àlejò ń kojú ní Amẹ́ríkà báyìí, jẹ́ ìràntí pé wíwà ní ìṣọ̀kan àti ṣíṣe iṣẹ́ papọ̀, láti dá ààbò bo àwọn tó le fara kásá jùlọ.
Achapu ní òun gbàgbọ́ pé àsìkò rèé fáwọn ìjọba ilẹ̀ Africa láti ṣe àtúntò orílẹ̀ èdè wọn, kí wọ́n ṣe àmójútó ohun tó ṣokùnfà ìdí táwọn èèyàn fi ń fi orílẹ̀ èdè wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì ṣàmójútó ètò ọrọ̀ ajé wọn.
"Tí US bá tẹ̀síwájú láti máa lé àwọn èèyàn kúrò ní ìlú wọn, China, Russia àtàwọn orílẹ̀ èdè tó to gòkè àgbà mìíràn yóò lo àǹfàní náà láti tan ipa wọn ní Africa nípa fífún àwọn èèyàn ní àǹfàní láti ṣe ìrìnàjò lọ sí orílẹ̀ èdè wọn.
Kaduli, nínú ọ̀rọ̀ sí Trump sọ pé, " Tí Amẹ́ríkà yóò bá tún ga si, US nílò láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, kí wọ́n wo àwọn àǹfàní táwọn àlejò le mú bá orílẹ̀ èdè wọn àti ọ̀npa tí wọ́n le fi ran ètò ọrọ̀ ajé wọn lọ́wọ́."
"Mà á sọ fún ààrẹ láti gbé ìrònú rẹ̀ lórí ọmọnìyàn dípò òṣèlú."












