Òkùnkùn birimù ní Kwara báwọn òṣìṣẹ́ IBEDC ṣe bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì aláìní gbèdéke

Oríṣun àwòrán, BBC/Getty Images
Niṣe ni awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ to n pin ina mọnamọna, Ibadan Electricity Distibution Company,IBEDC tẹka ipinlẹ Kwara bẹrẹ iyanselodi alainigbedeke.
Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ gbe ilẹkun ileeṣẹ ti pa pe awọn ko ni ṣiṣẹ ayafi ti IBEDC ba dahun gbogbo ibeere awọn paapaa lori owo oṣu atawọn ajẹmọnu miiran.
Nigba ti BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ẹka ileeṣẹ naa to wa ni agbegbe Challenge, Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara, niṣe ni ilẹkun ileeṣẹ naa wa ni titi pa, ti ko si si oṣiṣẹ kankan lẹnu iṣẹ.
Oniruuru awọn akọle to n ṣafihan ẹdun ọkan awọn oṣiṣẹ lo wa lara ilẹkun ti wọn ti pa naa.
Yatọ si eyi, awọn oṣiṣẹ naa tun n ṣe ifẹhonuhan lori awọn iṣoro ti wọn n la kọja, ti wọn si n kọminu lori bi ileeṣẹ naa ṣe n yan awọn oṣiṣẹ rẹ jẹ.


Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ mọnamọna (IBEDC) ẹka ti ipinlẹ Kwara, Commrade Felix Oluwatosin Ologun salaye pe, ọpọ ipenija lawọn oṣiṣẹ naa n koju.
O ṣalaye pe idaji owo oṣu ni ileeṣẹ naa n san fun awọn lati bii oṣu meloo kan sẹyin ati pe awọn ri irinṣẹ to yẹ lati fi ṣe iṣẹ awọn.
Ologun sọ pe ko si ọkọ ti awọn le gbe jade lati fi ṣiṣẹ, bakan naa wọn tun da awọn oṣiṣẹ duro lẹnu iṣẹ, ko si ohun elo ti wọn fi le ṣiṣẹ, inu ewu ni awọn ti n ṣiṣẹ.
O fi kun pe awọn yoo tẹsiwaju pẹlu iyansẹlodi naa titi ileeṣẹ IBEDC yoo fi dahun ibeere awọn.
Bakan naa lo fi kun pe iyanṣẹlodi naa tumọ si pe awọn ko ni ṣe ohunkohun to jọ mọ titun ina ṣe nibikibi titi ti awọn fi maa pada sẹnu iṣẹ.
Ile iṣẹ mọnamọna IBEDC lo n pese ina fun ipinlẹ Kwara, Oyo, apakan Ọsun, apakan Kogi, ati apakan ipinlẹ Niger.
Gbogbo igbiyanju Asojukọroyin wa lati ba awọn alaṣẹ ile iṣẹ mọnamọna IBEDC naa sọrọ loja si pabo, nitori gbogbo wọn o le yọju si ọfisi, wọn ti ti ọfisi wọn pa, ti wọn si ko awọn agbofinro sibẹ.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ naa, Ọgbẹni Adekunle sọ pe, idaji owo oṣu ni oun gba, ti ko si to se kankan, o ni ile iṣẹ mọnamọna (IBEDC) ko tọju awọn to bo se yẹ.
Comrade Felix Oluwatosin Ologun ni ojojumọ lawọn yoo ma se ifehonuhan ni ọfisi naa bẹrẹ lati ọla lọ,titi awọn alaṣẹ ile iṣẹ mọnamọna IBEDC) yoo ṣe dahun ibeere awọn.














