Wo ìpínlẹ̀ 31 tí ọ̀rọ̀ ìdásílẹ̀ wọn tó wà níwájú ilé aṣòfin àpapọ̀ Nàìjíríà ń fún ọ̀pọ̀ ní ìrètí

Aworan maapu Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile aṣoju-ṣofin l'Abuja ti pe fun idasilẹ ipinlẹ mọkanlelọgbọn mii lorilẹede Naijiria.

Igbimọ to n ri si atunṣe iwe ofin Naijiria nile lo ṣe agbekalẹ aba fun idasilẹ ipinlẹ mọkanlelọgbọn ọhun.

Ni Ọjọbọ ọjọ kẹfa oṣu Keji ni igbimọ naa gbe aba naa kalẹ niwaju ile ti wọn si ka a seti awọn ọmọ ile to wa ni ijokoo.

Igbakeji adari ile aṣoju-ṣofin, Benjamin Kalu lo dari ijokoo naa ni Ọjọbọ.

Alaga igbimọ naa sọ pe awọn ti da aba pe ki ijọba da ipinlẹ mẹfa tuntun silẹ ni ẹkun araringbungbun Naijiria, mẹrin mii ni ẹkun ila oorun ariwa.

O ni igbimọ naa tun da aba fun idasilẹ ipinlẹ marun un ni iwọ oorun ariwa, marun un ni ẹkun ila oorun guusu, mẹrin fun ẹkun guusu-guusu ati meje ni ẹkun iwọ ooru ariwa.

Ti ile igbimọ aṣofin agba ba buwọlu aba yii, eyi yoo tumọ si pe orilẹede Naijiria yoo ni ipinlẹ mẹtadinlaadọrin.

Ipinlẹ mẹtadinlaadọrin yii yoo ju ti orilẹede Amẹrika to ni aadọta ipinlẹ lọ.

Igbimọ to n ṣatunṣe iwe ofin Naijiria nile sọ ninu lẹta ti wọn ka niwaju ile pe ''a n fi asiko yii sọ fun ile wi pe igbimọ to n ri si atunṣe iwe ofin Naijiria ti gba ẹbẹ fun idasilẹ awọn ipinlẹ tuntun ati ijọba ibilẹ tuntun.

Wọnyi ni awọn ipinlẹ ti ile aṣoju ṣofin n da aba fun idasilẹ wọn ni ẹkun jẹkun:

Ẹkun Ararin gbungbun Ariwa Naijiria(North-Central)

Ipinlẹ Benue Ala lati ara ipinlẹ Benue

Ipinlẹ Okun lati ara Kogi

Ipinlẹ Okura lati ara Kogi

Ipinlẹ Confluence lati ara Kogi

Ipinlẹ Apa-Agba lati ara Benue ati

Ipinlẹ Apa lati ara Benue

Ipinlẹ Olu ilu Naijiria Abuja

Ẹkun ila - Oorun Ariwa Naijiria (North East)

Ipinlẹ Amana lati ara Adamawa

Ipinlẹ Katagum lati ara Bauchi

Ipinlẹ Savannah lati ara Borno

Ipinlẹ Muri lati ara Taraba

Ẹkun Iwọ oorun - Ariwa (North West)

Ipinlẹ Kaduna tuntun lati ara Kaduna

Ipinlẹ Gurara lati ara Kaduna

Ipinlẹ Tiga lati ara Kano

Ipinlẹ Kainji lati ara Kebbi

Ipinlẹ Ghari lati ara Kano

Ẹkun Ila oorun - Guusu (South East)

Ipinlẹ Etiti ti yoo sikẹfa awọn ipinlẹ lati ẹkun ila oorun guusu Naijiria

Ipinlẹ Adada lati ara Enugu

Ipinlẹ Urashi

Ipinlẹ Orlu

Ipinlẹ Aba lati ara Abia

Ẹkun Aarin gbungbun Guusu Naijiria (South South)

Ipinlẹ Ogoja lati ara Cross River

Ipinlẹ Warri lati ara Delta

Ipinlẹ Bori lati ara Rivers

Ipinlẹ Obolo lati ara Rivers ati Akwa Ibom

Ẹkun Iwọ Oorun Guusu Naijiria (South West)

Ipinlẹ Toru-Ebe lati ara Delta, Edo ati Ondo

Ipinlẹ Ibadan lati ara Oyo

Ipinlẹ Lagoon lati ara Eko

Ipinlẹ Ijebu lati ara Ogun

Ipinlẹ Oke Ogun lati ara Oyo

Ipinlẹ Ife-Ijesha lati ara Oyo ati Osun