Àwọn kan ṣekúpa èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, dáná sun ọ̀pọ̀ mọ́lé l'Ebonyi, Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí kan

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ebonyi ti sọ pe awọn ti mu ọkan lara awọn to kọlu agbegbe Amagu Nkalaha, l'Ebonyi, laipẹ yii, nibi ti wọn ti pa eeyan mẹẹẹdogun ti wọn si dana sun ọpọ ile.
Ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Ebonyi, Joshua Ukandu, fi sita lo ti ṣalaye pe laaarin Nkalaha si Eha-amafu ni ọwọ ti ba afurasi naa pẹlu iranlọwọ awọn araalu.
Alukoro sọ pe afurasi tọwọ ba naa ka awọn kan ti wọn jọ lọwọ si ikọlu naa.
Eyi lo mu kawọn ọlọpaa gba ibi to ni awọn eeyan naa wa lọ.
O ni ṣugbọn bi wọn ṣe ganni ọlọpaa ni wọn fẹsẹ fẹ ẹ.
Alukoro ọlọpaa Ebonyi sọ pe awọn ba awọn ibọn ninu ile naa pẹlu awọn aṣọ ọlọpaa ati tawọn ṣọja.
Ukandu fi kun un pe iṣẹ iwadii ṣi n lọ lori awọn to sa lọ ọhun.
O rọ ẹnikẹni to ba ni olobó to le ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lati kan si wọn.
Báwo ni ìkọlù tó pa èèyàn púpọ̀ náà ṣe wáyé?

Laaarọ ọjọ Aiku, ọjọ keji, oṣu Keji ọdun 2025 ni wahala bẹ silẹ ni ibi kan ti a mọ si Amegu Nkakaha, nijọba ibilẹ Ishielu,ipinlẹ Ebonyi.
Awọn agbebọn la gbọ pe wọn kọlu ilu naa.
Bakan naa la tun gbọ pe awọn darandaran to fẹẹ gbẹsan awọn maaluu wọn ti wọn ni IPOB ati ESN pa lagbegbe naa ni wọn wa nidii ikọlu yii.
O kere tan, eeyan mẹwaa ni iroyin kọkọ sọ pe awọn agbebọn naa pa ninu ikọlu ọhun.
Bi wọn ṣe pa awọn eeyan naa ni wọn tun dana sun awọn ile kan pẹlu dukia awọn to ni ile naa.
Awọn ọlọpaa lo pada ṣabẹwo sibẹ ti wọn si gbe oku mẹwaa ti wọn kọkọ ri lọ lọjọ naa.
" Aṣọ mi nìkan ni dúkìá tó kù fún mi láyé "

Awọn eeyan ti ikọlu yii ba ṣugbọn ti ko pa, ti n sọ ohun ti oju wọn ri ati bi wọn ko ṣe ni nnkan kan mọ laye.
Obinrin kan ti ko darukọ rẹ, ṣalaye fun BBC pe
Awọn apaayan naa pa awọn aburo ọkọ oun meji ati baba wọn.
O fi kun un pe wọn ba ọpọlọpọ ile jẹ pẹlu aga ati awon nnkan eelo ile mi-in to wa nibẹ.
O ni wọn ko owo awọn mi-in lọ pẹlu.
" Wọn gbe awọn obinrin kan lọ, wọn ko owo wọn.
Wọn jo ile awọn obinrin ti ọkọ wọn ti ku, wọn si ko gbogbo dukia to wa ninu awọn ile naa lọ."
Bẹẹ ni obinrin yii ṣalaye.
Nwakaego ni ẹlomi-in to ba BBC sọrọ n jẹ.
O ni ohun to dun oun ju ni pe wọn jo ile oun kanlẹ raurau, wọn si ba awọn dukia oun jẹ loju oun.
"Awọn aṣọ ti mo n wọ nikan lo ku fun mi laye bayii.
"Wọn fa aṣọ ti mo wọ ya mọ mi lara. Awọn eyi tẹ ẹ ri ti mo n wọ yii, awọn eeyan lo da wọn jọ fun mi."
Bayii ni Nwakego wi.
Awọn eeyan naa waa rọ ijọba Ebonyi lati ran wọn lọwọ ninu iṣoro ai si aabo yii.
Gomina ipinlẹ Ebonyi, Francis Nwifuru, ti ni ijọba yoo tuṣu iṣẹlẹ naa de isalẹ ikoko.
Bẹẹ lo ni ikọlu naa ba oun ninu jẹ gidi.














