Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìjàmbá iná tó ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ 17 ní Zamfara

Oríṣun àwòrán, Yahaya Mahi
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Zamfara ni ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti fìdí ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá iná tó mú ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́tàdínlógún lọ ní ilé ẹ̀kọ́ Kùránì kan ní Kauran Namoda lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kejì, ọdún 2025.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Zamfara, Yazid Abubakar sọ fún BBC pé ọ̀sán ọjọ́rú ni àwọn èèyàn ìlú náà ti sin òkú àwọn ọmọ náà àti pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà da omi tútù sọ́kàn àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà.
"Àwọn tí wọ́n farapa nínú ìjàmbá iná náà ni à ń mójútó báyìí, tí a sì ń ṣe gbogbo nǹkan tó wà ní ìkápá wa láti ṣe ìrànwọ́ fún wọn. Àwọn mẹ́tàdínlógún ló farapa, tí wọ́n sì ti ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn," Yazid ṣàlàyé.
Ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ìjàmbá iná ṣẹ́yọ ní ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Islam kan níbi tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Kùránì tí iná náà sì jó ilé ìgbé táwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n máa ń pè ní "Almajiri" náà ń sùn.
Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni wọ́n há sínú ilé náà lásìkò tí ilé náà ń jó lọ́wọ́. Nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì fi máa dé ilé náà, iná náà ti ṣekúpa ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Bákan náà ni àwọn mìíràn ti farapa gidi.
Kaura Namoda ni ìlú kejì tó tòbi jùlọ ní ìpínlẹ̀ Zamfara. Àwọn aláṣẹ gbàgbọ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà tó ọgọ́rùn-ún. Àwọn ọmọ náà ni ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́wàá sí ọdún mẹ́rìndínlógún tí ọ̀pọ̀ wọn sì wá láti ìlú Kaura Namoda láti àwọn ìlú mìíràn káàkiri láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Kùránì.
Ìjàmbá ina ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ 17 ni Zamfara

Oríṣun àwòrán, Others
O to akẹkọọ mẹtadinlogun to padanu ẹmi wọn lasiko ti iṣẹlẹ ijamba ina waye ni ilẹẹkọ Islamic ni ijọba ibilẹ Kaura-Namoda nipinlẹ Zamfara.
Iṣẹlẹ ina naa to waye ni alẹ ọjọ Isẹgun, ọjọ kẹrin oṣu keji lo n jo fun odidi wakati mẹta, ti ọpọ akẹkọọ si tun farapa yanayana.
Oṣojumikoro, Yahaya Mahi to ba akọroyin BBC sọrọ ni ina naa bẹrẹ ni ile kan to wa ni iwaju yara awọn akẹkọọ ko to di pe o tan mọ ile awọn akẹkọọ.
"Nigba ti Ina kere kọkọ jẹyọ, ti wọn eeyan si n sa kiri ṣugbọn ina naa tun bu gbamu, to si mu ilẹkun ile awọn akẹkọọ, ti ko si fun wọn ni anfani lati jade sita.,"
O fikun pe akẹkọọ mẹtadinlogun lo padanu ẹmi wọn, ti mejila si farapa yanayana.
Ọkan ninu iya ọmọ to farapa sọ fun BBC pe inu ibanujẹ ni ọpọ wa bayii.
"A gbagbọ pe a mu wa Ọlọrun ni. Nigba ti a gbọ nipa iṣẹlẹ naa, inu wa ko dun ṣugbọn a gbagbọ pe Ọlọrun yoo fopin si iṣẹlẹ yii."
Ki gan an lo fa iṣẹlẹ?
Ohun pato to ṣokunfa iṣẹlẹ naa ni a ko le sọ awọn gbofinro ti n se iwadii.
Awọn olugbe agbegbe naa ni ile to sumọ ile ẹkọ naa ni ina naa ti bẹrẹ.
"A ko mọ bi ina naa se bẹrẹ ni ile eeyan kan ni agbegbe ti ile ẹkọ naa wa.















