Gómìnà Adeleke sọ̀rọ̀ lórí rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ nílùú Esa Oke, Ọba Owamiran ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo

Aworan Gomina Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Osun State government/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina Ademola Adeleke ipinlẹ osun ti sọrọ lori rogbodiyan to bẹ silẹ niluu Esa Oke lori iyansipo ọba tuntun nibi ti ọpọ dukia ti ṣofo tawọn eeyan si farapa yanayana.

Nigba ti gomina Adeleke n ba awọn ọmọ iluu Esa-oke sọrọ, o fi da wọn loju wi pe, ẹnikẹni to ba wa nidi Isẹlẹ naa yoo fimu ko ata ofin.

Gomina Adeleke wa rọ gbogbo eeyan ilu Esa Oke lati faye gba awọn agbofinro ati ìjọba ipinlẹ Osun lati ṣe iwadii to peye lori Isẹlẹ naa.

Aworean alupupu kan ti wọn dana sun.

Gomina ipinlẹ Osun ṣeleri wi pe gbogbo ẹni to ba n ṣagbatẹru rogbodiyan ati fifi ẹmi ati duki ṣofo ni yoo foju wina ofin.

Gomina sọ pe ''rogbodiyan to ṣẹlẹ ba mi lọkan jẹ tori ko le si idasoke lawujọ ti rukerudo ba ti n waye.

Mo fẹẹ fi da a yin loju pe ijọpa yoo ṣe iwadii iṣẹlẹ yii, ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ yii ba si mọ lori yoo jiya ẹṣẹ rẹ labẹ ofin.''

Gomina tun lọ wo ọkọ Toyota Highlander ati apa aafin Ọba ilu Esa-Oke tawọn janduku dana sun.

Sẹnẹtọ Adeleke tun fi dawọn eeyan ilu Ido Ayegunle naa loju nigba to ṣabẹwo sibẹ naa pe ijọba oun yoo gbiyanju agbara rẹ lati daabo bo wọn.

Aworan ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wọn dana sun lasiko rogbodiyan to waye ni ilu Ẹsa Oke ni ipinlẹ Ọṣun.

Owamiran Esa - Oke pe fun idajọ ododo

Ẹwẹ, Ọba Adeyemi Adediran Owamiran ti ilu Esa-oke ti pe fun idajọ ododo lori ikọlu to waye niluu naa.

Ọba AAdediran, jẹ ki Gomina Adeleke mọ wi pe, ẹgbẹ oselu PDP ni oun n ṣe ati gbogbo ọmọ ilu Esa-Oke lapapọ.

Bamigboye Aremu, alagba fun ọmọ ilu Esa-Oke ṣalaye ohun ṣokunfa bi Isẹlẹ naa.

''Ọjọbọ ọgbọnjọ osu Kinni odun yii ni a gbọ wi pe, ijọba ipinlẹ ọsun mu lẹta kan wa si Ido Ayegunle lati fun iluu naa lọba.

Igba ti mo gbọ iroyin yii ni mo ti mọ wi pe wahala ni ìjọba fẹ da silẹ laaarin ilu Esa-Oke ati Ido Ayegunle.

Ido Ayegunle kii ṣe ilu to to lati gba Ọba nitori wi pe, ọkan lara awọn abule to wa lara ilu Esa-Oke ni Ido Ayegunle jẹ.

Ẹni ti ijọba fun ni ọba Ido Ayegunle, lo wa lati ilu Ilesa ti ko si ni ẹtọ kankan lati jọba nibẹ rara.

Ṣadeede la gburo ibọn ni ọjọ Aje ọjọ Kẹta Osu Keji ọdun yii, t àwọn janduku naa si mura bi ọlọpaa, ti wọn n si doju ìbọn wọn kọ awọn eeyan ilu Esa-Oke.

Paroparo ni eto karakata da ni ilu Ẹsa Oke

Aworan awọn ile itaja to wa ni titipa ni ilu Ẹsa Oke ni ipinlẹ Ọṣun

Paroparo ni ilu Ẹsa Oke da lọjọ Iṣẹgun to jẹ ọjọ keji iṣẹlẹ naa. Gbogbo awn olugbe ilu naa ni wọn joko si ile wọn nitori aile sọ ibi ti ọrọ naa yoo tun gba yọ.

Lasiko abẹwo BBC si ilu Ẹsa Oke, gbogbo awọn ibudo itaja lo wa ni titipa ti eto ọrọ aje si dẹnukọlẹ.

Pupọ awọn to ba BBC sọrọ sọ pe alaafia lo jẹ awọn logun ati wi pe ki ijọba atawọn ileeṣẹ agbofinro o ba awọn gbe igbesẹ idaabo bo to yanranti ki eto karakata le pada si ọwọ to wa ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Bawo ni rogbodiyan to bẹ silẹ ni Esa-Oke ṣe bẹrẹ?

Aworan ile ati ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn da ina sun.

Iwadii ti BBC Yoruba ṣe lati mọ oun to sokunfa wahala naa fi han pe awọn afurasi to ṣe ikọlu si iluu Esa-oke ni wọn mura bi ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti ki wọ aṣọ.

Atun gbọ wi pe, bi wọn ṣe ṣe ikọlu naa tan ni awọn ọdọ ilu Esa-Oke naa dihamọra ogun tẹ le wọn.

Ṣadeede ni awọn afurasi naa ya wọ ile isẹ Ọlọpaa to wa niluu Esa-Oke ti ẹni to jẹ ọga ọlọpaa DPO ẹka ile isẹ Ọlọpaa naa si da awọn ọdọ to tẹle awọn afurasi janduku naa pada.

Awọn araalu to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe awọn afurasi to da rogbodiyan naa silẹ kii ṣe ọlọpaa.

Wọn ni irọ to jina si otitọ ni pe ọlọpaa ni awọn to wa ṣe ikọlu si Esa-Oke.

Ninu iwadi wa lati tun fidi rẹ mulẹ wi pe, ko si eeyan kankan to ba Isẹlẹ naa lọ.

Bakan naa ni awọn ileeṣẹ ọlọpaa kọ lati jẹ ka ri awọn ọlọpaa to fi ara gba ọta ìbọn lasiko Isẹlẹ naa.