Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún awakọ̀ tó pa tọkọtaya tó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́jọ́ ọdún tuntun

Kehinde àti Bukola Fatinoye

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ogun tó fi ibùjókòó sí Kobape ní Abẹ́òkúta ti ní kí wọ́n yẹgi fún Lekan Adekanbi, Ahmed Odetola àti Waherf Adeniyi títí tí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lọ́rùn wọn.

Ẹ̀sùn ṣíṣekúpa Kehinde Fatinoye, ìyàwó rẹ̀, Bukola Fatinoye àti ọmọ wọn Oreoluwa Fatinoye lọ́jọ́ Kìíní, oṣù Kìíní, ọdún 2023 ni ile ẹjọ́ ní àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jẹ̀bi.

Ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kìíní, ọdún 2023 ni àwọn ọ̀daràn náà lọ ká àwọn tọkọtaya náà mọ́lé lẹ́yìn tí wọ́n dárí ìsìn láti bọ́ sínú ọdún tuntun.

Nǹkan bíi aago méjì òru ọjọ́ náà ni Lekan Adekanbi tó jẹ́ awakọ̀ àwọn tọkọtaya náà kó àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lọ sílé àwọn ọ̀gá rẹ̀, tí wọ́n sì pa wọ́n sínú ilé.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n dáná sun òkú wọn mọ́ inú ilé.

Bákan náà ni wọ́n so ọmọ kan ṣoṣo táwọn tọkọtaya náà bí àti ọmọkùnrin kan tí wọ́n gbà sọ́dọ̀ lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí wọ́n sì lọ jù wọ́n sínú odò Ògùn.

Oreoluwa pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú odò náà àmọ́ orí kó ọmọkùnrin kejì yọ, tó sì jáde nínú odò náà láàyè.

'Ọ̀gá mi kọ̀ láti fi kún owó oṣù mi ni mo ṣe pa òun àti ìyàwó rẹ̀'

Ile wọn tí wọ́n dáná sun

Oríṣun àwòrán, Others

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nínú oṣù Kejì ọdún 2023, Adekanbi sọ pé nítorí àwọn tọkọtaya náà kọ̀ láti fi kún owó oṣù òun àti láti yá òun lówó ni òun ṣe lẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn òun láti ṣe ìkọlù sí wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ní àwọn ẹbí náà kọ̀ láti yá òun lówó láti fi ra ọ̀kadà ni òun ṣe kàn sí Odetola àti Adeniyi láti rán òun lọ́wọ́ láti lọ ja àwọn ọ̀gá òun lólè.

"Àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lúgọ dè wọ́n pé kí wọ́n dé láti ilé ìjọsìn. Ní kété tí wọ́n dé ni a ya bò wọ́n."

Adekanbi sọ pé àwọn jẹ́ kí Kehinde Fatinoye fi owó ₦1,102,000 ránṣẹ́ sí akoto owó báǹkì Access òun kí àwọn tó gba ẹ̀mí lọ́rùn wọn.

Ó ní àwọn pinnu láti pa wọ́n nígbà tí òun ri pé àṣírí òun ti tú sáwọn tọkọtaya náà lọ́wọ́ látàrí orúkọ báǹkì òun.

Adeniyi fi ọ̀bẹ dú Kehinde Fatinoye, tí Adekanbi sì la sledgehammer mọ́ Bukola lórí èyí tó ṣokùnfà ikú àwọn méjèèjì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ń lọ lọ́wọ́ ni Oreoluwa àti ọmọ tí wọ́n gbà sọ́dọ̀, Felix Olorunyomi wọlé báwọn níbẹ̀, wọ́n dè wọ́n lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí wọ́n sì lọ jù wọn sínú odò.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi ṣèrántí pé Adekanbi gbìyànjú láti sá mọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ nígbà tó wà ní ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

Oyeyemi ṣàlàyé pé ọjọ́ Kejì, oṣù Kìíní, ọdún 2023 ni Lekan Adekanbi ṣàdédé ṣubú lulẹ̀ ní àhámọ́ tó wà tí àwọn sì gbé dìgbàdìgbà lọ sí ilé ìwòsàn.

Ó ní ilé ìwòsàn yìí ló gba sá lọ kí àwọn tó gbọ́ pé ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kan tó wà ní ìlú Iseyin, ìpínlẹ̀ Oyo ló sá lọ.

Ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kìíní ni ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá padà tẹ Adekanbi ní ìlú Abeokuta, tí wọ́n sì nawọ́ gán Odetola àti Adeniyi ní ìlú Ogere, ìpínlẹ̀ Ogun ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kejì, ọdún kan náà.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye ni àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Ẹ̀sùn mẹ́rìnlélógún tó fi mọ́ ìpànìyàn, olè jíjà àtàwọn ẹ̀sùn míì ni ile ẹjọ́ kà sí Adekanbi, Odetola, Adeniyi àtàwọn mẹ́fà míì lọ́rùn àmọ́ tí wọ́n sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà.

Ìdájọ́ ilé ẹjọ́

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lọ́jọ́ Kẹta, oṣù Kejì, ọdún 2025, Adájọ́ Basirat Adebowale ní ilé fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Adekanbi, Odetola àti Adeniyi jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Ó dájọ́ ikú nípa yíyẹ igi fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta títí tí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lọ́rùn wọn fún wọn.

Bákan náà ni Adájọ́ tún ju Temitope Fadairo, ìyàwó Adekanbi sẹ́wọ̀n fún gbígbé ọkọ rẹ̀ pamọ́ àti ìyá rẹ̀, Adenike Adekanbi sẹ́wọ̀n ọdún kan fẹ́sùn píparọ́ fáwọn ọlọ́pàá.

Adájọ́ tún ní kí Azeez Usman, òṣìṣẹ́ welder tó tú ọkọ tí wọ́n jí gbé sí wẹ́wẹ́, lọ lo ọdún mẹ́rìnlá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.