Falana kéde láti ṣe agbẹjọ́rò fún bàbá tí Ọba Orile Ifo dá dọ̀bálẹ̀ níta gbangba

Aworan Ọba Semiu Ogunjobi, Areola Abraham ati Femi Falana

Oríṣun àwòrán, Femi Falana/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajugbaja agbẹjọro ati ajafẹtọọ, Femi Falana, ti kede wi pe oun yoo ṣe agbẹjọro fun fun baba agbalagba ẹni ọdun mẹtalelaadọrin, Areole Abraham, ti Olorile ti Orile Ifo, Ọba Semiu Ogunjobi da dọbalẹ ni gbangba ti ọkan ninu awọn ẹmẹwa rẹ si gba a leti.

Igbakeji aarẹ ajọ CDHR to n ja fun ẹtọ ọmọniyan, Yinka Folarin, lo kede igbesẹ yii.

Folarin sọ ninu atẹjade to fi sita pe Falana to jẹ alaga igbimọ alaṣẹ ajọ CDHR kede igbesẹ yii nigba ti baba naa ṣabẹwo si ọfiisi rẹ ni Ikeja GRA niluu Eko.

O ni Falana ṣetan lati tọpinpin ẹsun titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ eyi ti wọn fi kan Ọba Ogunjobi.

''Lẹyin ti Falana gbọ nipa ẹjọ naa tan ni o gba lati ṣe agbẹjọro fun baba yii.

O si fi da baba naa loju wi pe ileesẹ amofin oun yoo ṣatilẹyin fun un lori ẹjọ naa,'' Flolarin lo sọ bẹẹ.

Kọmureedi Soyombo Sunday to jẹ alaga ajọ CDHR tẹlẹ naa wa ni ijokoo nigba ti Falana kede igbesẹ rẹ yii.

Folarin to mu baba naa lọ si ọfiisi Falana gboṣuba rabandẹ fun ilumọọka ajafẹtọọ naa lori bi o ti n ja fawọn eeyan ti ko rọwọ họri lawujọ.

Ẹwẹ, majisireeti to ṣeto igbẹjọ naa paṣẹ pe ki wọn gbe kabiyesi Ogunjobi lọ si ọgba ẹwọn niluu Ilaro lẹyin to kuna lati pese gbogbo nnkan ti ilẹ ẹjọ n beere fun lati gba beeli rẹ.

Agbẹnusọ ọgba ẹwọn , Yinka Odukoya, lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin.

Ti ẹ o ba gbagbe, ijọba ipinlẹ Ogun naa ti paṣẹ pe ki kabiyesi naa lọ rọkun nle fun oṣu mẹfa.

Ọba tó fìyà jẹ olóyè níta gbangba sun ọgbà ẹ̀wọ̀n mọ́jú lẹ́yìn tó kùnà láti mú ìlànà béèlì rẹ̀ ṣẹ

Aworan Ọba Abdulsemiu Ogunjọbi

Oríṣun àwòrán, Others

Lẹyin ti o foju ba ile ẹjo tan lọjọ Iṣegun, Kabiyesi Olorile ti Orile Ifo, Ọba Abdulsemiu Ogunjọbi, ti dero ọgba ẹwọn niluu Ilaro.

Igbakeji agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu awọn akọroyin laarọ Ọjọru ọjo karun un oṣu Keji ọdun yii.

Igbakeji alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ogun sọ pe kabiyesi naa ko le ri gbogbo nnkan ti ile ẹjọ ni ko ṣe lati gba beeli lanaa ọjọ Iṣẹgun ni adajọ fi paṣẹ wi pe ki wọn gbe ori ade naa lọ si ọgba ẹwọn ilu Ilaro.

Ẹsun onikoko mẹta to da lori igbimọpọ lati ṣe ikọlu si eeyan ati ihuwasi to le ṣakoba fun alaafia awujọ ni wọn fi kan Ọba Ogunjobi.

Lẹyin ti ori ade naa sọ fun ile ẹjọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun ni agbẹjọro rẹ beere fun beeli.

Adajọ majisireeti ni ileẹjọ ṣetan lati fun ni beeli pẹlu miliọnu marun un ati oniduro meji tawọn naa gbọdọ fi miliọnu marun un silẹ.

Awọn nnkan yii ni Olorile ti Orile Ifo ko le ṣe ti ori ade naa fi sun ita lọgba ẹwọn niluu Ilaro lọjọ Iṣẹgun.

Adajọ ti sun igbẹjọ si Ọjọbọ ọjọ kẹfa oṣu keji ọdun yii.

Ẹwẹ, igbakeji agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ti wa rọ araalu lati fi ọrọ Ọba Ogunjobi kẹkọọ.

O ni ko si ẹni to kọja ofin orilẹede Naijiria, iru ẹni yowu ti ẹni ba le mọ.

DSP Oluwole ni ofin lu mu Ọba Ogunjobi, kii ṣe awọn ọlọpaa.

Ọba tó dá olóyé dọ̀bálẹ̀ níta gbangba l'Ogun fojú ba iléẹjọ́, wo bí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ṣe lọ

Aworan Ọba Ogunjọbi ati alagba to da dọbalẹ ni ilu Orile Ifọ.

Oríṣun àwòrán, others

Ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ti gbe Kabiyesi Abdulsemiu ogunjọbi to gba baba agbalagba kan ti wọn pe ni oloye ni ilu Orile-Ifọ lọ si ile ẹjọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun pe wọn gbe oriade naa lọ siwaju ile ẹjọ lọjọ Iṣẹgun lati jẹjọ lori ẹsun mẹta.

Gẹgẹbi atẹjade naa tun ṣe sọ, ẹsun mẹta ti wọn fi kan ọba Ogunjọbi ni ẹsun igbimọpọ hu iwa ibi, ifiyajẹni ati ihuwasi ti ko ba ofin mu.

O ni wọn gba beeli Ọba Orile-Ifọ naa wọn si sun igbẹjọ rẹ si ọjọ kẹfa oṣu kẹta ọdun 2025.

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria wa tẹsiwaju ninu atẹjade naa lati fi da araalu loju pe awọn ko ni dẹkun fifi ilakalẹ ofin mulẹ ati iwa ọmọluwabi lelẹ lẹnu iṣẹ ọlọpaa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Eyi n waye lẹyin ti fidio kan to ṣafihan bi kabiyesi naa ṣe n fiya jẹ Oloye Areola Abraham lu ori itakun ayelujara pa.

Fọnran naa tun ṣafihan bi ọba ọhun ṣe n ṣẹ epe nla nla fun oloye yii ẹni ọdun mẹtalelaadọrin, ti ọkan ninu awọn ẹmẹwa rẹ si n gba baba yii leti nibi to ti wa lori ikunlẹ.

Ohun ti Ọba Ogunjobi sọ ninu fidio naa wi pe Oloye Abraham lẹdi apo pọ pẹlu awọn eeyan kan lati ditẹ mọ oun.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ ogun ti paṣẹ ki kabiyesi naa lọ rọọkun nile naa fun oṣu mẹfa. Wọn ni ko gbọdọ pe ara rẹ ni ọba ilu naa laarin asiko yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ṣalaye ṣalaye pe awọn ti fi ọrọ wa ọbalaye naa lẹnu wo, paapaajulọ lori ihuwasi rẹ ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ọmọọba Muyiwa Adejọbi ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni fi aye silẹ fun ẹnikẹni lati maa ta ẹrẹ ba orukọ ati iyi ileeṣẹ ọlọpaa ati iṣẹ rẹ .

Eyi ko ṣẹyin ọrọ ti ọbalaye naa n sọ ninu fọnran fidio to bọ sita ninu eyi tiọbalaye naa ti n sọ fun baba agbalagba naa pe oun le sọ ọ di oku ki oun si sin in ti ẹnikẹni ko ni beere rẹ, ati pe ikawọ oun ni awọn ọlọpaa wa.