Agbébọn yawọ ilé ìjọ́sìn, síná bolẹ̀ fún Olùṣọ́ l'Ogun

Aworan ile ijọsin Celetial Church of Christ

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olusọ kan lati ile ijọsin Celetial Church of Christ, Yomi Adetula ni awọn agbebọn kan ṣekupa lasiko ti ijọsin n lọ lọwọ nipinlẹ Ogun.

Ni bi aago mẹwaa owurọ ọjọ kọkandinlogun osu kinni ọdun 2025 ni iṣẹlẹ yii waye ni ile ijọsin naa to wa ni ọna Old Baggage ni Odo Eran, Idiroko.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun fidi iṣẹlẹ naa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Omotola Odutola fi lede fun awọn akọroyin.

Atẹjade naa ṣalaye pe awọn ọkunrin mẹta kan lo wọle sinu ṣọọṣi naa lojiji.

Ibọn oloju meji ti wọn gbe dani ni wọn doju rẹ kọ Oluṣọ ti wọn fẹẹ yin in si i, wọn si yinbọn naa mọ ọn.

Eyi da ṣọọṣi ru, ti kaluku n sa kijokijo kiri.

Oloogbe naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣapejuwe gẹgẹ ẹni ọdun mẹrinlelaadọta, ti wọn si ba a ninu agbaara ẹjẹ lasiko ti Ọlọpaa de si ibi ti isẹlẹ naa ti waye.

"Gbogbo ara oloogbe ni ọta ibọn ba jẹ, ti awọn agbebọn yii si tun fi ake fọ oloogbe ni ori lati ri daju pe o ti ku.

"Iwadii fihan pe ọkunrin mẹta lo yawọ ile ijọsin naa pẹlu ibọn, ti wọn si kọ si Olusọ, ti wọn si daa si lara."

Ileeṣẹ ọlọpaa ni oku oloogbe naa ti wa ni ile ijọsin General niluu Ilaro.

Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe ọwọ ko ti tẹ ẹnikẹni sugbọn iwadii ti bẹrẹ lati mu awọn ọdaran naa.