A ti mọ̀ pé báyìí ni ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ náà yóò ṣe rí ni a ṣe pinnu láti má ṣe kópa - PDP

Paroparo ni awọn oriko idibo da lasiko eto idibo ijọba ibilẹ to waye ni Ipinlẹ Ondo ni ọjọ Satide ọjọ kejidinlogun oṣu kini ọdun yi.
Abewo ileeṣẹ BBC YORUBA si awọn oriko idibo naa safihan rẹ pe, awọn ohun elo idibo pẹ de si awọn oriko idibo ti awọn ara ilu si benuate lu igbese yi latowo ajọ eleto idibo Ipinlẹ Ondo ODIEC.
Lara awọn oludibo to ba ileeṣẹ BBC YORUBA sọrọ ọgbẹni Adesida Matthew sọ pe inu ohun ko dun bi awọn ẹgbẹ alatako ko se kopa ninu eto idibo naa.
O sọ pe aikopa ẹgbẹ PDP ati awọn ẹgbẹ Oṣelu miran ninu eto idibo naa lo mu ki awọn eniyan ma jáde lati kopa ninu eto idibo to waye lọjọ Satide.
O wa rọ awọn ara ilu lati mọ pataki eto idibo ijọba ibilẹ fun idagbasoke ijọba tiwantiwa.
Bakanna oludibo miran Adetiba Iyabo, ẹni ti ko le pa aidunu rẹ mọra salaye pe ọna jinjin lo n ti wa dibo sugbọn iyalẹnu lo jẹ fun pe awọn eniyan pereje lo ba loriko idibo.
O rọ ijọba lati jẹ ki ajọ INEC ma dari eto idibo ijọba ibilẹ, ki awọn ara ilu le ni igbagbọ ninu eto naa.
Lasiko to n se abewo kakiri awọn oriko idibo nijọba ibilẹ Gusu ati Ariwa Akure, Alaga Ajọ ODIEC Joseph Aremo fi aidunu rẹ han bo se jẹ pe awọn eniyan pereje lo kopa ninu eto naa.
Aremo rọ awọn ẹgbẹ Oṣelu lati maa ṣe ilaniloye fun awọn ara ilu, ki wọn le mọ pataki eto idibo ijọba ibilẹ.
Alaga naa sọ pe Ajọ ODIEC ti gbiyanju ti wọn si se isẹ takuntakun lati ri daju pe wọn faye gba gbogbo ẹgbẹ Oṣelu lati kopa lai segbe lẹyin enikeni.
O gboriyin fun awọn osisẹ Ajọ naa fun bi wọn ṣe pakitimora ti wọn si se isẹ wọn ni ibamu pẹlu ofin.
Kí ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sọ lórí eto ìdìbò naa?
Ẹgbẹ Oṣelu PDP nipinlẹ Ondo Sapejuwe eto idibo to waye gẹgẹ bi ere ọmọde lasan, eyi to tako ofin ati ilana eto idibo.
Adari eto iroyin ati ipolongo lẹgbẹ Oṣelu PDP nipinlẹ Ondo Leye Igbagbo sọ pe wọn mọ pe ODIEC ko kun oju osuwọn lati dari eto idibo naa, idi rẹ niyi ti wọn ko fi kopa.
O salaye pe wọn ti mọ pe bayi gan ni eto idibo naa yoo se ri, nitori iwadi wọn ti fidi rẹ mulẹ saaju pe Ajọ ODIEC yoo ṣegbe lẹyin ẹgbẹ APC ninu eto naa.
O wa rọ awọn alatileyin ẹgbẹ naa, lati ni igbagbọ ninu ẹgbẹ Oṣelu PDP nipinlẹ Ondo.
Kìni àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC sọ lórí ètò ìdìbò náà?
Gomina Ipinlẹ Ondo Lucky Orimisan Aiyedatiwa ti gboriyin fun ajọ ODIEC fun aseyọri eto idibo ijọba ibilẹ l'ondo.
Aiyedatiwa kete lẹyin to dibo rẹ ni wọọdu 4, Ugbo Nla nijọba ibilẹ Ilajẹ, sọ pe eto idibo naa lọ laisi wahala kan, ti ODIEC si seto idibo naa ni ibamu pẹlu ofin.
O gboriyin fun awọn ara ilu bi wọn ṣe kopa ninu eto idibo naa.
Oludije sipo Alaga nijọba ibilẹ Gusu Akure Olugbenga Fasua sọ pe eto idibo naa jẹ eto idibo ijọba ibilẹ akọkọ nipinlẹ Ondo ti ko ni wahala kan ninu.
O gboriyin fun ODIEC fun isẹ takuntakun ti wọn se, saaju eto idibo ati lẹyin eto idibo naa.















