TikTok ti ṣíwọ́ iṣẹ́ lórílẹ̀èdè America lẹ́yìn tí wọ́n fòfin dè é

Oríṣun àwòrán, EPA
Oju opo ikansiraẹni TikTok ti pana lorilẹede Amẹrika, wakati diẹ si gbedeke ifidimulẹ odin to wọgile e lorilẹẹdẹ naa.
Atẹjiṣẹ kan jade lori opo ayelujara naa fun awọn to n lo o lorilẹẹdẹ Amẹrikape wọn ti ṣe ofin kan to de TikTok nibẹ nitorinaa, "o ko le e lo TikTok lọwọ yii".
Awọn alaṣẹ ijọba lorilẹede Amẹrika gbegile Oju opo naa to gbajumọ fun titẹ fidio fun ọpọ lati wo nitori ajọṣepọ rẹ pẹlu ijọba orilẹede China, wọn si ti fun un ni gbedeke di ọjọ kọọkandinlogun oṣu kinni ọdun 2025 ki wọn fi ta a fun onibara ti Amẹrika fọwọsi.
Aarẹ Joe Biden ti sọ pe oun yoo fa igbesẹ to kan lori ọrọ naa le Donald Trump ti yoo gba ipo lọwọ oun lọwọ. Amọṣa o Trump ti sọ pe bi oun ba ti gba ọpa aṣẹ ipo aarẹ lọjọ Aje, o ṣeeṣe ki oun fun ileeṣẹ TikTok ni anfani aadọrun ọjọ lati wa nnkan ṣe lori ọrọ naa.
Donald Trump ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin NBC News lọjọ Abamẹta pe, " Gbedeke tuntun aadọrun ọjọ naa jẹ ohun to seeṣe ko ṣẹlẹ, nitoripe o tọna,".
"Bi mo ba pinnu lati ṣe eyi, o ṣeeṣe ki n kede rẹ lọjọ Aje."
Awọn to n lo oju opo ayelujara naa sọ pe wọn ri yọ ọ kuro lori atẹ ayelujara Google ati Apple lorilẹẹdẹ Amẹrika ati pe TikTok.com o gbe fidio kankan sita mọ.
Atẹjiṣẹ ti ileeṣẹ TikTok fi sita lẹyin ti ofin ti wọn fi de e ọhun bẹrẹ ifidimulẹ tun fi kun un pe, "Inu wa dun pe Aarẹ Trump ti gba lati ṣiṣẹ pẹlu wa lori ona abayọ lati da TikTok pada bi o ba de ori oye."















