Àwọn Oyomesi wà níbi tí mo ti dífá tó mú Aláàfin Oyo tuntun - Ọ̀jọ̀gbọ́n Wande Abimbola

Oríṣun àwòrán, Others
Láti ìgbà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti kéde Aláàfin tuntun fún ìlú Oyo ni awuyewuye ti ń wá lórí ìyànsípò Akeem Abimbola Owoade.
Lára àwọn nǹkan tó ń fa awuyewuye náà ni pé gómìnà Seyi Makinde kò tẹ̀lé ìlànà oyè Aláàfin jíjẹ.
Ṣáájú ni ìjọba Oyo ní àwọn kàn sí àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí ifá dídá, ìyẹn Ọ̀jọ̀gbọ́n Wande Abimbola tó ń gbé ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti dá ifá yan ẹni tí yóò di Aláàfin.
Ìjọba ní èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí Oyomesi, tó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi orúkọ ọmọ oyè ránṣẹ́ sí gómìnà fún ìbuwọ́lù, hùwà àjẹbánu àti pé wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ọmọ oyè tí wọ́n forúkọ rẹ̀ sọ́wọ́ fún ìyànsípò Aláàfin.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kọminú lórí ìgbésẹ̀ gómìnà pé ṣé ó yẹ láti máa dífá ẹni tí yóò jẹ Aláàfin láti ilẹ̀ òkèrè bí?
Ẹ̀wẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wande Abimbola nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Nigerian Tribune ṣàlàyé bí ifá dídá lórí ìyànsípò Owoade gẹ́gẹ́ bí Aláàfin tuntun ṣe wáyé.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Wande Abimbola ní ìgbà àkọ́kọ́ rèé, láti ìgbà tí ọ̀làjú ti wọ ilẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n yóò máa yan ọba lọ́nà tó yẹ.
Ó ní àṣà Yorùbá ni láti dá ifá, láti bèèrè lọ́wọ́ ifá, ẹni tó yẹ láti yàn sípò ọba nígbà tí ìdílé tí ọba bá kàn bá ti fa àwọn ọmọ oyè kalẹ̀.
O ṣàlàyé pé nǹkan bíi ọdún kan sí ọdún méjì sẹ́yìn ni gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde kàn sí òun láti dífá kí wọ́n le mọ ẹni tí Aláàfin tọ́ sí.
Ó ní èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tí wọ́n fi kan àwọn kan nínú ìgbìmọ̀ Oyomesi pé wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ Ọmọọba tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí gómìnà.
"Ìwádìí fi hàn pé ẹni tí Ifá mú kò ní àbáwọ́n kankan tàbí ní ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn lọ́rùn."
Ọ̀jọ̀gbọ́n Abimbola tẹ̀síwájú pé láìpẹ́ yìí ni gómìnà Makinde tún kàn sí òun nígbà tó gbọ́ pé òun wà ní Eko láti tún ifá dá tí ifá sì sọ pé ẹni àkọ́kọ́ náà ni ó yẹ lóyè Aláàfin.
"Ìwádìí tún fi hàn pé ẹni tí ifá mú náà kò ní àbáwọ́n kankan tàbí ní ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kankan lọ́rùn."
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn pé wọ́n kò jẹ́ kí àwọn Oyomesi mọ̀ nípa ohùn ifá, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wande Abimbola ní àwọn aṣojú Oyomesi mẹ́rin ló wà ní ìkàlẹ̀ lásìkò tí àwọn da ifá náà.
Ó ṣàlàyé pé owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ táwọn Oyomesi gbà lọ́wọ́ ọmọ oyè kan ti ń fa ìyapa ẹnu láàárín wọn.
Ó ní àwọn méjì tí jáde láyé nínú ìgbìmọ̀ Oyomesi tó ku àwọn márùn-ún. Nínú àwọn márùn-ún yìí, àwọn méjì ń bínú sí àwọn yòókù pé owó tí wọ́n fún àwọn nínú àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí wọ́n gbà kéré.
Ó fi kun pé àwọn méjì tó kú náà ni wọ́n lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó ìjọba létí tí ìjọba fi bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ fúnra wọn.
"Wọ́n jẹ́wọ́ fún EFCC, tí wọ́n sì dá owó tí wọ́n fún wọn padà àmọ́ káká kí àwọn yòókù náà ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbé ìjọba lọ sílé ẹjọ́, tí ọ̀rọ̀ náà ṣì wà ní ilé ẹjọ́ di àsìkò yìí.
"Àwọn méjì tó ti jẹ́wọ́ wà níbi tí a ti dífá ọmọ oyè, bẹ́ẹ̀ náà ni ìjọba tún yàn àwọn olóyè méjì tó ń délé fún àwọn tó ti papòdà gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe là á kalẹ̀."
Ọ̀jọ̀gbọ́n Abimbola gbogbo ìgbésẹ̀ tí àwọn gbé lórí ìyànsípò Abimbola Owoade gẹ́gẹ́ bí Aláàfin tuntun fún ìlú Oyo ló wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òfin.















