Àwọn awuyewuye tó wáyé lórí ìyànsípò Aláàfin Lamidi Adeyemi tó mú ìtẹ́ wà lófo fọ́dún mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi/Facebook
Láti ìgbà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti kéde Ọba Akeem Abimbola Owoade bíi Aláàfin tuntun fún ìlú Oyo ni àwọn awuyewuye kan ti ń wáyé lórí ìyànsípò rẹ̀.
Níṣe ni àwọn ọmọ oyè kan ń fi àké kọ́rí pé àwọn kò gba ìyànsípò Aláàfin tuntun náà àti pé ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo kò tẹ̀lé àwọn ìlànà tó yẹ.
Kódà, Basorun ìlú Oyo, Olóyè Yusuf Akinade Ayoola nígbà tó ń bá BBC News Yoruba sọ̀rọ̀ ní ohun tó wu gómìnà Seyi Makinde ló ṣe lórí ọ̀rọ̀ oyè náà nítorí Oyomesi kò fọwọ́ sí ìyànsípò Owoade.
Basorun ní orúkọ tí gómìnà kéde yàtọ̀ sí orúkọ tí Oyomesi fi ránṣẹ́ síi àti pé ọ̀rọ̀ náà ti wà nílé ẹjọ́ nítorí àwọn ti pe ìjọba Oyo lẹ́jọ́ lórí ìgbésẹ̀ náà.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tọ́rọ̀ jíjẹ Aláàfin ìlú Oyo yóò máa mú awuyewuye dání nítorí irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí wáyé ní bí àádọ́ta ọdún sẹ́yìn kí wọ́n tó yan Aláàfin àná, Ọba Lamidi Atanda Adeyemi sípò.
Báwo ni Ọba Adeyemi ṣe di Aláàfin lọ́dún 1971
Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, ọdún 1968 ni erin wó, tí àjànàkú sùn bí òkè, tí Aláàfin Bello Gbadegesin Ladigbolu kejì darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti bí ìwe òfin oyè jíjẹ ìlú Oyo ọdún 1961 ṣe là á kalẹ̀, ìdílé méjì ló ń jẹ oyè Aláàfin – ìdílé Agunloye tí ọba Gbadegesin ti wá àti ìdílé Alowolodu.
Láì fọ̀pá pọ̀ọ̀lọ̀pọlọ pejò, ó hàn gbangba pé ìdílé Alowolodu ni ipò ọba kàn táwọn ọmọ oyè sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ara wọn jọ láti fa ọmọ oyè tí yóò jọba kalẹ̀.
Ìtàn sọ pé ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kìíní kan náà ni àwọn ọmọ oyè láti ìdílé Alowolodu panupọ̀ láti fi orúkọ mẹ́rin ránṣẹ́ sí Oyomesi tó jẹ́ afọbajẹ ìlú Oyo láti yan èèyàn kan nínú wọn sípò Aláàfin.
Wọ́n fi orúkọ àwọn ọmọ oyè náà ránṣẹ́ àmọ́ àwọn Oyomesi kò gba orúkọ náà lọ́wọ́ nítorí wọn kò tẹ̀lé àṣà àti ìṣe.
Gẹ́gẹ́ bí àṣà, Oyomesi nílò láti kọ̀wé ránṣẹ́ sí ìdílé tí ọba bá kàn pé kí wọ́n fi orúkọ àwọn ọmọ oyè, tí wọn bá fẹnukò lé lórí ránṣẹ́ sáwọn, fún ìgbésẹ̀ tó bá tọ́ àti yíyan ẹnìkan ní pàtó.
Àkọ́ọ́lẹ̀ Onigegewura ṣàlàyé pé ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kejì, ọdún 1968 ni akọ̀wé ìgbìmọ̀ afọbajẹ Oyo kéde pé ìdílé Alowolodu ni oyè Aláàfin kàn , tí wọ́n sì ní kí wọ́n fi orúkọ àwọn ọmọ oyè tó tọ́ sí oyè ránṣẹ́ kọ tó di ogúnjọ̀ oṣù Kejì, ọdún kan náà.
Èyí ló mú kí Mọ́gàjí ìdílẹ Alowolodu nígbà náà, Alabi Adeyemi pe ìpàdé àwọn ọmọ oyè. Ibi ìpàdé yìí ni wọ́n fẹ̀sùn kan pé àwọn kan pinnu láti fi orúkọ ọmọ oyè kan ṣoṣo péré, Alabi Oranlola Adeyemi tó jẹ́ ọmọ Mọ́gàjí ṣọwọ́ sí Oyomesi.
Ìgbésẹ̀ yìí kò tẹ́ àwọn ọmọ oyè míì lọ́rùn rárá, tí àwọn ọmọ oyè mẹ́sàn-án mìíràn sì dìde èyí tí ọmọọba Lamidi Olayiwola Atanda Adeyemi wà lára wọn.
Babaiyaji, olóyè Sanda Moradesa tó jẹ́ olórí àwọn ọmọ oyè ilé Alowolodu ṣàfihàn àwọn ọmọ oyè mẹ́wàá yìí sí Basorun tó jẹ́ olórí Oyomesi.
Yíyan Aláàfin tó kàwé

Oríṣun àwòrán, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi/Facebook
Láti nǹkan bíi ọdún 1930 táwọn kan ti ń jà fún òmìnira Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn ni ìpè fún yíyan àwọn ọba tó bá kàwé ti ń gbilẹ̀ káàkiri Nàìjíríà èyí kò sì yọ ìlú Oyo náà sílẹ̀.
Níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe nílé Bashorun náà ni wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọọba tí kò bá ti kàwé kò nílè dépò Aláàfin. Báyìí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní já àwọn ọmọ oyè títí tó fi ku àwọn márùn-ún tí - Ọmọọba Sanda Ladepo Adeyemi tó jẹ́ ọmọ Mọ́gàjí àti Ọmọọba Lamidi Olayiwola Adeyemi wà lára wọn.
Àwọn méjéèjì ló kàwé, Ladepo Adeyemi jẹ́ òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá ìjọba ìbílẹ̀ nígbà tí Lamidi Adeyemi jẹ́ òṣìṣẹ́ ètò adójútòfò ní ìpínlẹ̀ Eko.
Ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹta ni Oyomesi ṣèpàdé láti yan ẹnìkan nínú àwọn ọmọ oyè márùn-ún tó kù, wọ́n panupọ̀ láti yan Lamidi Adeyemi gẹ́gẹ́ bí Aláàfin tí òkìkí sì kàn káàkiri gbogbo ìlú pé Lamidi ni àwọn afọbajẹ fẹnukò lé lórí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Oyomesi ti yan Lamidi, ó ku àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ìjọba láti fi ọ̀ǹtẹ̀ lu ìfẹ́ Oyomesi. Wọ́n fi orúkọ Lamidi ránṣẹ́ sí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oyè ní Ibadan fún ìbuwọ́l]u àti ìkéde.
Ìlú Ibadan ni orin ti yípadà, tí orúkọ ọmọọba táwọn Oyomesi fi ránṣẹ́ ti yípadà sí orúkọ mìíràn. Kàkà kí Kọmíṣánnà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oyè fi orúkọ Lamidi ránṣẹ́ sáwọn aláṣẹ, orúkọ Ladepo Oranlola Adeyemi ni wọ́n fi ránṣẹ́.
Oyomesi pín sí méjì lórí ta ni yóò jẹ Aláàfin ni 1968
Èyí mú káwọn Oyomesi fárígá pé Lamidi ni àwọn ń fẹ́ àmọ́ kò pẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà fi fa ìyapa ẹnu láàárín àwọn Oyomesi.
Bí Basorun, Yagba, Samu, Alapinni àti Akinniku ṣe ní ti Lamidi ni àwọn ń ṣe, Ashipa àti Laguna ní ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, Ladepo ni àwọn ń tẹ̀lé, òun láwọn ń fẹ́ pé kó dépò Aláàfin.
Bí ìfaǹfà yìí ṣe ń lọ lọ́wọ́ ni àwọn kan láti ilé Alowolodu kan náà tún gbé ẹja dìde pé kò sí èyí tó tọ́ sóyè nínú Lamidi àti Ladepo, pé Ọmọọba Tella Kakansi Adeyemi ni ẹni tí oyè náà tọ́ sí.
Gómìnà ẹkùn ìwọ̀ oòrùn nígbà náà, Robert Adeyinka Adebayo nígbà tó ń ri pé ọ̀rọ̀ oyè Aláàfin kò ní ojútùú gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti rí sí ohun tó ń fa awuyewuye lórí oyè ọ̀hún.
Ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹfà, ọdún 1968 ni ìgbìmọ̀ Obileye bẹ̀rẹ̀ ìjókòó láti gbọ́ ẹ̀hónú nípa ohun tó ń fa awuyewuye lórí ipò Aláàfin.
Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ wọn, ìgbìmọ̀ náà ní Ọmọọba Sanda Oladepo Adeyemi ni ipò ọba tọ́ sí.
Bákan náà ni wọ́n fún Oyomesi ní ọ̀sẹ̀ méjì péré láti fi parí gbogbo ètò tó yẹ lórí ipò ọba náà ṣùgbọ́n síbẹ̀ àwọn Oyomesi fi àáké kọ́rí pé Lamidi Adeyemi ni àwọn yóò yàn bíi Aláàfin.
Ìjọba Oyo nígbà náà gbé ìgbésẹ̀ mìíràn nípa yíyan àwọn olóyè láti ṣiṣẹ́ Oyomesi.
Àwọn Oyomesi fẹnukò láti gbé ìjọba lọ sílé ẹjọ́ lórí ìgbésẹ̀ náà ṣùgbọ́n tí wọ́n fìdí rẹmi nílé ẹjọ́ bí ilé ẹjọ́ ṣe ní òun kò láṣẹ láti gbọ́ ẹjọ́.
Nígbà tí ọ̀rọ̀ oyè Aláàfin náà kọ̀ láti yanjú, gómìnà Adebayo ní àwọn máa gbé ọ̀rọ̀ tì sí ẹ̀gbẹ́ ná láti mójútó ìjà abẹ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní Nàìjíríà nígbà náà.
Báyìí ni ipò Aláàfin ṣe wà lófo fún ọdún mẹ́ta gbáko láì sí ọba kankan lórí ìtẹ́.
Lamidi gbọ́pà àṣẹ Aláàfin Oyo

Oríṣun àwòrán, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi/Facebook
Ọdún 1970 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò oyè jíjẹ Aláàfin lákọ̀tun padà nígbà tí wọ́n yan Dókítà Victor Omololu Olunloyo gba ipò Kọmíṣánnà fọ́rọ̀ oyè jíjẹ àti ìjọba ìbílẹ̀ Oyo.
Olunloyo lẹ́yìn tó ṣe àgbéyẹ̀wò awuyewuye àti àwọn ẹjọ́ tó ti wáyé lórí ọ̀rọ̀ oyè náà tó sì pàṣẹ pé kí wọ́n tún ọ̀rọ̀ oyè náà bẹ̀rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀.
Ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 1970 ni àwọn ará Oyo tú yàyà lọ sí ilé Bashorun Akano láti gbọ́ ẹni tí Oyomesi yóò kéde bíi Aláàfin tuntun.
Wọ́n tún orúkọ Lamidi Olayiwola Adeyemi fi ránṣẹ́ sí ìjọba fún ìbuwọ́lù tí gómìnà Adebayo sì kéde lọ́jọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kejìlá, ọdún 1970.
Ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kìíní, oṣù Kìíní, ọdún 1971 ni Lamidi Olayiwola Atanda Adeyemi gba ọ̀pá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí Aláàfin ìlú Oyo.















