Ohun tó wáyé rèé nílé ẹjọ́ májísíréètì lórí ẹjọ́ Oriyomi, Naomi àti ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́

Aworan Olori Naomi ati Oriyomi Hamzat

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Igbẹjọ to yẹ ko waye l'owurọ ọjọ Aje ni ile ẹjọ Majistreeti Iyaganku tọ n bẹ nilu Ibadan lori awọn ẹsun ti wọn fi kan gbajugbaja agbohunafẹfẹ, Oriyọmi Hamzat, Olori tẹlẹri, Naomi Ṣilẹkunọla ati alakoso ile ẹkọ ti iṣẹlẹ naa ti waye, Abdullahi Fasasi ti di sisun siwaju bayii nitori awọn ẹni afẹsunkan naa ti ko fi ara han nile ẹjọ.

Lẹyin igbẹjọ to waye saaju asiko yii, ile ẹjọ naa beere amọran lọwọ ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si eto idajọ lori awọn ẹsun ti fi kan awọn eeyan mẹtẹẹta naa, ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si eto idajọ si fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn mẹtẹẹta ni wọn ni ẹjọ late jẹ, ti wọn si da ọjọ kẹtala oṣu kini ọdun yii fun igbẹjọ mii.

Ṣugbọn aifi ara han awọn mẹtẹẹta lo mu ki adajọ Olubisi Ogunkanmi sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu yii

Alaye Abdulfatai Oyedeji to jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro fun alakoso ile ẹkọ 'Islamic Secondary School' ṣe fun awọn akọroyin ni pe ile ẹjọ Majistreeti Iyaganku ko ni agbara lati da ẹjọ naa, ṣugbọn ile ẹjọ naa gbọdọ kọkọ gbọ tẹnu awọn eeyan ti ẹka eto idajọ pe lejọ ki wọn to fi ọrọ wọn ṣọwọ si ile ẹjọ giga to n bẹ ni agbegbe Ring Road niluu Ibadan.

Oyedeji ṣe alaye siwaju sii wi pe ohun to ṣeeṣe ko ṣẹlẹ ti awọn ẹni ti wọn fi ẹsun kan ba fi ara han nile ẹjọ Majistreeti Iyaganku lọjọ kẹtadinlogun oṣu yii ni ki ile ẹjọ fun ni anfani lati wi tẹnu wọn boya wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn. Lẹyin eyii sini ile naa yoo fi ẹjọ ṣọwọ si ile ẹjọ giga to n bẹ niluu Ibadan.

Ilé ẹjọ́ gba béèlì Oriyomi ati Naomi, gbé ìkìlọ̀ ńlá kalẹ̀ fún Oriyomi

Oriyomi Hamzat ati Olori Naomi Silekunola

Ile ẹjọ giga to wa nilu Ibadan ti gba beeli gbajumọ agbohunsafẹfẹ nni, Oriyomi Hamzart to wa ni ahamọ ọgba ẹwọn.

Bakan naa ni ile ẹjọ naa tun gba beeli Olori Naomi Silekunola ati ọga agna ile ẹkọ girama Islamic nibi ti isẹlẹ ọhun ti waye.

Agbẹjọro fun Oriyomi, Adekunle Sobaloju lo kede bẹẹ fun BBC Yoruba ni ọsan ọjọ Aje nile ẹjọ giga to wa nilu Ibadan.

Ile ẹjọ pasẹ fun Oriyomi pe ko gbọdọ sọ ohun ti oju rẹ ri lori awọn eto rẹ lori afẹfẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹjọro naa ni adajọ fun Oriyomi ni awọn gbedeke kan lati tẹle, ko to di pe wọn yoo gba beeli rẹ.

"Lara awọn gbedeke ti adajọ fi lelẹ ni pe Oriyomi gbọdọ fi oniduro meji silẹ, ti awọn mejeeji si n gbe nilu Ibadan.

O ni awọn oniduro mejeeji gbọdọ fi iwe asẹ irinna wọn silẹ, ki wọn si tọwọ bọ iwe lati mu afurasi naa wa sile ẹjọ nigbakuugba to ba yẹ lasiko ti igbẹjọ naa ba n lọ lọwọ."

Amofin Sobaloju ni ile ẹjọ naa tun pasẹ fun Oriyomi pe ko gbọdọ sọ ohunkohun ti oju rẹ ri lori isẹlẹ yii lori awọn eto rẹ lori afẹfẹ.

Bakan naa nile ẹjọ tun fi ofin de Oriyomi lati mase sọrọ nipa igbẹjọ to n lọ lọwọ naa lori afẹfẹ titi ti ẹjọ yoo fi pari.

"Ile ẹjọ ni kawọn oniduro Oriyomi mejeeji tun tọwọ bọ iwe adehun pe awọn yoo san miliọnu mẹwa ẹnikọọkan bi afurasi ọhun ba salọ."

Nigba to n sọrọ lori ẹsun onikoko mejidinlogun tuntun ti ijọba ipinlẹ Oyo fi kan awọn afurasi mejeeji, amofin Sobaloju ni awọn ẹsun tuntun naa lagbara to ẹsun mẹrin akọkọ tijọba fi kan wọn.

Bí ọ̀rọ̀ ṣe lọ rèé lórí ẹjọ́ Oriyomi àti Naomi nílé ẹjọ́ Májísírétì

Igbẹjọ n tẹsiwaju lonii lori awọn ẹsun ti ijọba ijinlẹ Oyo fi kan awọn eeyan to se akoso eto to waye nilu Ibadan nibi ti awọn eeyan ti tẹ ara wọn pa.

Bẹẹ ba gbagbe, Ọjọ Isẹgun to kọja ni ile ẹjọ Majisireti to wa nilu Ibadan sun igbẹjọ naa siwaju di oni.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo n reti pe wọn yoo gba oniduro awọn eeyan ti wọn fẹsun kan naa, eyiun Oriyomi Hamzat, Olori Naomi Silekunola ati ọga agba ile ẹkọ girama Islamic ti isẹlẹ ọhun ti waye.

Amọ adajọ to n gbọ ẹjọ naa sun igbẹjọ siwaju di oni ọjọ Aje.

Nile ẹjọ Majisireti lonii, awọn afurasi mẹtẹẹta na ko yọju sile ẹjọ bi o tilẹ jẹ pe awọn ololufẹ wọn ti peju sibẹ lati se koriya fun wọn.

Ìdí rèé tílé ẹjọ́ méjì yóò fi gbẹ́jọ́ Oriyomi Hamzat àti Naomi lónìí

Oriyomi Hamzat ati Silekunola Naomi

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/Silekunola Naomi

Lonii, ọjọ kẹtala, oṣu Kini, ọdun 2025 ni gbajumọ sọrọsọrọ, Oriyomi Hamzat, ati Olori Ooni atijọ, Naomi Silekunola yoo tun foju bale ẹjọ niluu Ibadan.

Eyii ko ṣẹyin ẹjọ ti ijọba ipinlẹ Oyo n ba wọn ṣe lẹyin iku ọmọde marundinlogoji ti wọn tẹ pa niluu Ibadan lọdun to kọja.

Ile ẹjọ meji ọtọtọ lo ṣeeṣe ki igbẹjọ awọn afurasi naa ti waye; iyẹn nile ẹjọ majisreeti ati ile ẹjọ giga.

Igbagbọ awọn onwoye ohun to n ṣẹlẹ ni pe ile ẹjọ majisreeti ni yoo kọkọ gbọ ẹjọ naa ko to tare rẹ si ile ẹjọ giga nibi ti igbẹjọ ọhun yoo ti tẹsiwaju.

Ti ẹ ko ba gbagbe, gomina Seyi Makinde ti ṣeleri pe awọn afurasi naa ko ni ṣai jẹjọ lẹyin iku awọn ọmọ to jade laye.

Ijọba Oyo ka ẹsun mejidinlogun si awọn afurasi lẹsẹ

Wayi o, ẹsun mejidinlogun ọtọtọ ni ijọba ipinlẹ Oyo ka si awọn afurasi naa lọrun, eyii ti wọ yoo maa jẹjọ rẹ lati oni ọjọ Aje lọ.

Lara ẹsun naa ni ẹsun ipaniyan ti wọn ko mọọmọ ṣe.

Ijọba sọ pe awọn mejeji gbe eto kalẹ, ninu eyii ti wọn pe ọpọ ero si lai ṣe awọn alakalẹ to tọ lati daabo awọn ti wọn pe sibi eto ọhun.

Ṣaaju ni agbẹjọro awọn ti ijọba fẹsun kan naa ti sọ pe ko ba ofin mu bi wọn ṣe ti awọn afurasi naa mọle.

Lẹyin naa lo bẹbẹ pe ki ile ẹjọ tu wọn silẹ ni ahamọ lati maa gba ile lọ jẹjọ wọn.

O ni eeyan pataki ni wọn lawujọ, wọn ko si ni salọ ti ile ẹjọ ba tu wọn silẹ.

Agbẹjọro Hamzat, Adekunle Sobaloju, SAN, ni ko tọ labẹ ofin lati ṣadede ti awọn onibara oun mọle lai kọkọ gbe wọn lọ sile ẹjọ fun igbẹjọ ṣaaju igbesẹ naa.

O ni "A ti kọ iwe fun beeli, ile ẹjọ si ti sọ pe o di ọjọ kẹtala, oṣu Kini, ki oun to gbe idajọ kalẹ lori rẹ, amọ, ko tọ labẹ ofin lati ti wọn mọle."

Amọ ṣa, adajọ agba ipinlẹ naa, Abiodun Aikomo kọ beeli wọn latari bi ẹsun ti ijọba fi kan wọn ṣe wuwo to.

Aikomo da ẹbẹ agbẹjọro awọn afurasi nu lori pe agbẹjọro naa ko pese ẹri ati idi pataki lati gba beeli wọn.