Ọlọ́pàá tú àṣírí bí ajínigbé ṣe jí obìnrin 16 gbé l‘Eko

Oríṣun àwòrán, Benjamin Hundeyin/X
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ṣalaye ọna tuntun tawọn ajinigbe n lo lati ji awọn eeyan gbe lọ lasiko yii.
Ileeṣẹ ọlọpaa Eko ṣalaye pe niṣe lawọn ajinigbe ọhun maa n dibọn gẹgẹ bi ọrẹ awọn obinrin lori ayelujara lati le ji wọn gbe.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn olubi ẹda yii ti lo ọna tuntun yii lati fi gbe obinrin mẹrindinlogun laipẹ yii eyi tawọn agbofinro doola wọn.
Awọn ọlọpaa tun doola ọdọbinrin kan ẹni ọdun mẹẹdogun ẹni ti wọn lo gbimọ pọ pẹlu ọrẹkunrin rẹ lati gba owo itusilẹ lọwọ awọn obi rẹ.
Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Olawale Ishola, ni ọgbọn alumọkọrọyi ni ọna tuntun tawọn ajinigbe n lo lati ji awọn eeyan gbe lọ.
O ṣalaye pe awọn ajinigbe maa n kọkọ taagi awọn ti wọn ba fẹ jigbe lori itakun ayelujara lati le fa oju wọn mọra.
Ọga ọlọpaa ni kete ti obinrin ti wọn n ba sọrọ ba ti bẹrẹ si ni gba ti wọn ni wọn yoo sọ pe ko wa bawọn niluu Eko kawọn le jọ bẹrẹ irinajo ifẹ.
Koda, awọn ajinigbe yii le fi owo to to N500,000 ranṣẹ sawọn ti wọn ba fẹ jigbe lati wọ baalu wa si ilu Eko.
Gbajugbaja ile itura lawọn ajinigbe yii kọkọ maa n gbe awọn to ba ti bọ sọwọ wọn lọ kete ti wọn ba ti de si ilu Eko.
Nibẹ ni wọn ti maa gba foonu wọn ti wọn yoo si tun gba gbogbo owo to wa ninu akaunti wọn pata.
Lẹyin naa lawọn ajinigbe yoo kan si ẹbi awọn eeyan ti to bọ sọwọ wọn lati fowo itusilẹ ranṣẹ.
Bakan naa lawọn ajinigbe yii yoo maa dunkoko lati ṣekupa awọn eeyan ti wọn jigbe tawọn ẹbi wọn ko ba sanwo ti wọn n beere fun.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko wa rọ awọn araalu lati maa sọra papaa julọ awọn obinrin.
O tun rọ awọn obinrin lati kiyesara pẹlu irufẹ awọn eeyan ti wọn ba fẹ mu lọrẹẹ lori itakun ayelujara.















